Adájọ́ fi ààyè gba Elon Musk láti máa pín owó fawọn olùdìbò

Aworan Elon Musk, baba olowo rẹpẹtẹ

Oríṣun àwòrán, Getty

Àkọlé àwòrán, Aworan Elon Musk, baba olowo rẹpẹtẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Adajọ ipinlẹ Pennsylvania kan ti ni aaye ṣi wa fun baba olowo rẹpẹtẹ nni, Elon Musk, lati maa pin owo fawọn oludibo lasiko yii, ṣiwaju idibo America to ku ọjọ mẹrin ọhun.

Aarẹ Donald Trump ni Elon Musk n ṣatilẹyin fun ninu ibo naa bi gbogbo aye ṣe mọ.

Nipasẹ ẹgbẹ America PAC ti Musk da silẹ lo ti n pin owo fawọn oludibo to forukọ silẹ ni awọn ipinlẹ kan.

Iwa yii le tumọ si pe eeyan n ru ofin, gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ṣe wi, ṣugbọn Musk sọ pe ko sohun to jọ bẹẹ.

Igbesẹ yii naa lo mu olootu Philadelphia, Lawrence Krasner, pe Musk lẹjọ lorii miliọnu kan dọla $1m (£770,000) to n pin fawọn eeyan ki wọn le dibo sebẹ.

Lawrence Krasner loun fẹ ki kootu paṣẹ, pe Musk gbọdọ dawọ owo to n pin kiri naa duro, ki ibo to n bọ yii too waye.

Kí ni adájọ́ wí?

L’Ọjọbọ ti igbẹjọ waye, Adajọ Foglietta, sọ pe oun yoo ni lati taari ẹjọ naa si ile ẹjọ ijọba apapọ.

O ni bi ile ẹjọ apapọ ko ba gbọ ẹjọ yii, yoo pada si tipinlẹ ti wọn gbe e wa.

Ọrọ kan ti Musk kọ soju opo X rẹ lẹyin eyi ka pe "American Justice FTW (for the win)". To tumọ si pe aṣẹ ile ẹjọ duro fawọn ti yoo yege .

Ṣaaju ni Musk ti owo rẹ ti wọ biliọnu ti kede, pe oun yoo pin miliọnu kan dọla fawọn eeyan ipinlẹ ti nnkan ko ti rọgbọ.

Awọn bii Pennsylvania, Georgia, Nevada, Arizona, Wisconsin, Michigan ati North Carolina.

O loun yoo maa pin owo naa lojoojumọ titi di ọjọ karun-un, oṣu kọkanla ti idibo yoo waye gan-an.

Awon ilu ti Musk n sọ yii ni ifigagbaga to lagbara ti n waye laaarin Trump ati Kamala Harris ti wọn jọ n dije.

Ṣugbọn wọn kede ẹlomi-in to tun jẹ ẹbun miliọnu kan dọla naa l’Ọjọbọ, gẹgẹ bi America PAC ṣe wi.

Wọn ni Dacey lati Fremont, North Carolina lo jẹ ẹbun owo naa.

Kí ni èèyàn yóò ṣe láti jẹ ẹ́bùn owó Musk?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lati jẹ owo Musk, oludibo to ti forukọ silẹ yoo fi gbogbo alaye idanimọ rẹ ranṣẹ.

Ile to n gbe, nọmba ẹrọ ibanisọrọ rẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Wọn yoo tun kọwọ bọ iwe kan to n jẹjẹẹ pe wọn faramọ ofin ilẹ America.

Ṣaa, ẹsun ti awọn to pe Musk lẹjọ ka si i lẹsẹ ni pe tẹtẹ ti ko bofin mu lo ni kawọn eeyan maa waa ta.

“ America PAC ati Musk n tan awọn eeyan Philadelphia lati maa fi gbogbo aṣiri nipa wọn sita.

“ Ki wọn si tun maa jẹjẹẹ nitori miliọnu kan dọla. Tẹtẹ to lodi sofin lo n mu awọn eeyan ta.”

Ọgbẹni Krasner lo sọ eyi ninu ẹjọ to pe tako Musk.

Wọn tun fẹsun kan an pe o tẹ ẹtọ awọn eeyan loju mọlẹ nipa ẹtan to n tan wọn, ati awọn ọrọ ti ko ri bẹẹ to n sọ.

Ṣugbọn awọn lọọya Musk sọ pe onibaara awọn ko jẹbi kankan.

Ṣaaju ni BBC ti kan si America PAC lati gbọ ti ẹnu wọn.

Labẹ ofin ilẹ America, o lodi sofin lati fun awọn oludibo lowo lati dibo .

Awọn amofin sọ fun BBC pe eyi tako ofin.

Bi Musk ba jẹbi ẹsun yii, o le ni lati san owo itanran miliọnu mẹwaa dọla, ($10,000), tabi ko fi ẹwọn ọdun marun-un jura.

Musk funra ẹ to n fi gbogbo agbara polongo ibo fun Trump, ti sọ pe awọn to ba fẹẹ jẹ ẹbun owo oun ko nilo lati forukọ silẹ bii ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican, wọn si le ma dibo rara.