Èyí ni ìpinnu ìjọba lórí owó orí tuntun àti ìdí tí àwọn gómìnà ẹkùn Àríwá ṣe ń takò ó

Oríṣun àwòrán, @Gov Babajide Sanwo-Olu
Aigbọra ẹni ye ti bẹ silẹ bayii lori ipinnu ijọba Aarẹ Bola Tinubu nipa owo ori ọja, (VAT) eyi to fi ranṣẹ sile igbimọ aṣofin agba.
Ipinnu owo ori tuntun naa ni ko tẹ awọn gomina apa Ariwa lọrun, ti wọn si ti tako o ni gbangba.
Paapaa julọ, ọna ti ijọba fẹẹ gba lati pin owo ori ti wọn yoo maa san naa ko tẹ awọn gomina Ariwa lọrun rara.
Ni ibẹrẹ oṣu Kẹwaa ni Aarẹ Tinubu fi ipinnu mẹrin ranṣẹ sile igbimọ naa, nipa bi ijọba rẹ yoo ṣe maa ṣe iṣuna owo.
Kí ni owó orí tí a mọ́ sí ‘VAT’?
Ẹka owo ori tijọba maa n gba lori awọn ọja kan ni a mọ si Value Added Tax (VAT).
O jẹ owo kan to pọn dandan lati san lori ọja bi eeyan ba ra ọja ọhun lati ọdọ awọn ileeṣẹ.
Gẹgẹ bi Ọjọgbọn Muhammad Muntaqa Usman, ti Yunifasiti Ahmadu Bello, ni Zaria ṣe ṣalaye fun BBC.
O ni ida meje aabọ (7.5) ni owo ori ti wọn n yọ lori ọja ti eeyan ba ra ni Naijiria bayii.
" Ohun ti wọn n ṣe ni pe lori ohunkohun ti o ba ra, wọn yoo fi ele ida meje aabọ le owo to yẹ ki o san.
"Ọna ti wọn n gba gbowo ọhun ni pe awọn ileeṣẹ to n gbe ọja jade yoo ti fi owo naa le ori ọja.
Awọn ni yoo gba a, ti wọn yoo si san an si apo iṣuna ijọba."
Ọjọgbọn Muhammad Muntaqa Usman lo ṣalaye bẹẹ.
Àwọn ọjà wo ni èlé kò sí lóríí wọn?
Gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe afikun owo ori ti ọdun 2024 yii, ki i ṣe gbogbo ọja naa ni ele gbọdọ gun ori wọn.
Awọn ọja kan wa ti wọn yọ silẹ lati ma ni ele rara.
Lara awọn ọja naa ni a ti ri awọn ounjẹ onihooro, miliiki, burẹdi, omi mimu ati awọn nnkan ikẹkọọ, (educational items).
Kí wáá ni ìpinnu tuntun ìjọba dá lé lórí nipa èlé?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipinnu tuntun lori ele ori ọja yii fẹẹ yi ọna ti wọn n gba pin owo yii pada ni.
Tẹlẹ,ida mẹẹẹdogun (15%), ni ijọba n gba ninu owo naa, wọn waa fẹẹ din in ku si ida mẹwaa bayii.
Awọn ijọba ipinlẹ yoo gba ida marundinlọgọta (55%), nigba ti ijọba ibilẹ yoo gba ida marundinlogoji (35%).
"Ṣugbọn o, wọn fi ofin kan ti i.
Ofin naa ni pe ida ọgọta (60%) ninu gbogbo owo ori ọja ti wọn ba gba yii, wọn yoo yọ ọ kuro ninu apapọ owo to wọle, ibi ti wọn ba si ti pawo ọhun ni wọn yoo pin in si.
Iyẹn ni pe ilu ti ko ba ta ko gbọdọ rokan ati pinwo.
Ọjọgbọn Muntaqa lo ṣalaye bẹẹ.
Bakan naa ni ipinnu tuntun ijọba yii tun ṣeto bi wọn yoo ṣe pin owo naa laaarin ipinlẹ to ni ileeṣẹ ọhun ati agbegbe ti wọn gbe ileeṣẹ naa si.
Ipinnu yii tun duro lorii pe awọn ileeṣẹ to n gba owo ẹle ori ọja yoo sanwo ori sibi ti olu ileeṣẹ wọn wa, dipo awọn ipinlẹ ti wọn ni ẹka si.
Bi wọn yoo ṣe maa ṣafikun ele owo ori ọja naa ree titi di ọdun 2030, gẹgẹ bi ipinnu tuntun ijọba Tinubu.
Akọsilẹ ijọba sọ pe wọn yoo fi kun un ti yoo di ida mẹwaa, ida mejila, titi ti yoo fi pada si ida mẹẹẹdogun ni 2030.
Ìdí tí àwọn Àríwá fi ń bínú
Nibi ipade kan ti awọn gomina ipinlẹ apa Ariwa ṣe ni Kaduna lọsẹ to kọja, wọn sọ pe ipinnu ijọba yii tako Oke-Ọya.
Awọn gomina yii rọ awọn aṣofin lati ma ṣe gba a wọle rara.
"Idi ti a ko ṣe gba ni pe olu ileeṣẹ awọn ileeṣẹ ni wọn ti fẹẹ maa gba ele yii, dipo ibi ti awọn ẹka ileeṣẹ naa wa.
’’Bẹẹ, ẹka ileeṣẹ ni wọn ti n ta ọja ti wọn si ti n ṣe awọn nnkan mi-in"
Olori ẹgbẹ awọn gomina Ariwa,Muhammad Inuwa Yahaya, lo ṣalaye bẹẹ.
"Idi niyẹn ti ẹgbẹ wa fi tako igbesẹ naa, ipalara lo jẹ fun awọn eeyan wa, ko ṣe anfaani kankan fun wa rara," Gomina ipinlẹ Gombe lo sọ eyi.
Nigba to n kin ọrọ awọn gomina yii lẹyin, Ọjọgbọn Muntaqa sọ pe o yẹ ki ẹru ba awọn ẹya Oke Oya.
’’Bi ẹ ba wo ibi ti wọn ti n gba owo ori, ẹ maa ri i pe olu ileeṣẹ awọn bii banki ati awọn ileeṣẹ nla nla mi-in ni, Eko si ni ọpọ awọn olu ileeṣẹ naa wa."
Ọjọgbọn Muntaqa lo ṣe afikun bẹẹ.
Alaga to n ri si atunto owo ori fun ijọba apapọ ni tiẹ,Taiwo Oyedele, ṣalaye pe ki idagbasoke le wa ni ijọba ṣe gbe ipinnu tuntun yii kalẹ.
O ni ki eto pinpin ire le wa, kawọn to tọ si le gba ẹtọ wọn, ni ijọba ṣe ṣeto ilana tuntun yii.
Taiwo Oyedele sọ pe, "Fun apẹẹrẹ, ipinlẹ to ba n pese ounjẹ ko gbọdọ padanu, nitori ko sohun to kan wọn pẹlu ele ori ọja. Ṣugbọn awọn ipinlẹ mi-in n ra ọja wọn.
"O daa ka wo ohun ti ipinlẹ kọọkan n pa wọle fun orilẹede. Bakan naa ni yoo kan awọn ileeṣẹ ẹlẹrọ ibaraẹni sọrọ, ibi ti awọn eeyan to n lo oju opo wọn ba wa la o fi pin i.
"A maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn alẹnulọrọ ti ọrọ yii kan, ka le baa ri ọna abayọ ti yoo ṣe anfaani fun gbogbo awọn t’ọrọ kan."
Ìpa wo ni yóò ní lára Àríwá Naijiria?
Gẹgẹ bi Ọjọgbọn Muntaqa ṣe wi, bi wọn ba sọ aba yii di ofin, awọn ipinlẹ Oke ọya ko ni i ri owo ti wọn n gba tẹlẹ gba mọ.
" Kẹ ẹ si maa wo o, awọn ipinlẹ Oke-ọya ni awọn eeyan pọ si ju, awon ni yoo waa ni ipin to kere ju." Muntaqa lo sọ bẹẹ.
‘’Owo ori ọja ti wọn n pa l’Ekoo ju ti awọn ipinlẹ yooku ni Naijiria lọ.
Ti ẹ ba waa sọ pe wọn yoo jẹ anfaani ida ọgọta (60%), ki ni awọn ipinlẹ bii Zamfara, Jigawa ati Katsina ti wọn ko ni ileeṣẹ yoo gba, yoo kere gan-an.
Bi wọn ba sọ aba yii di ofin, Eko ni gbogbo owo yoo maa lọ, pẹlu Port Harcourt ati ipinle Ogun, nitori ibẹ ni awọn ileeṣẹ nla nla pọ si i lorilẹede yii.’’
Ọjọgbọn Muntaqa sọ pe ebi, ìyà, òsì, ifasẹyin ati ìṣẹ́ ni ipinnu yii yoo mu ba Ariwa, bi wọn ba fi le sọ ọ di òhun.














