Tani Auxilliary tí Teslim pé ní 'Ex convict' tó ń bí Makinde nínú?
Alhaji Lamidi Mukaila, ẹni ti ọpọ mọ si Auxiliary, ni o jẹ olori ọmọ ẹgbẹ awakọ nipinlẹ Oyo.
Lẹyin ti ijọba Makinde kede pe oun ko fi aye silẹ fun ajọ NURTW lati sisẹ nipinlẹ Oyo lo yan Auxiliary gẹgẹ bi olori awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ PMS.
Ọpọ igba ni Auxiliary ti bọ sori ayelujara lati dun koko pe oun yoo ṣekupa oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Teslim Folarin.
Laye Gomina Abiola Ajimobi, Ileeṣẹ ọlọpaa fi ofin mu Auxiliary pe o da ilu ru, to si fi oju ba ileẹjọ lori ẹsun naa , eyi to gbe lọ si ọgba ẹwọn.
Auxiliary tun jẹ ẹni ti awọn eeyan mọ si igbakeji gomina nitori ibaṣepọ pẹlu Gomina Seyi Makinde

Makinde àti Folarin tahùn síra wọn lórí tá ló ṣekúpa Eleweomo
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ẹni to jẹ oludije si ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ati Oludije si ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Teslim Folarin ni wọn gbena woju ara wọn nibi ipade itagbangba kan to waye niluu ibadan.
Teslim Folarin, nibi ipade na bu ẹnu atẹ lu bi Gomina Ṣeyi Makinde se yan ẹni to ti sẹwọn ri, iyẹn Alhaji Mukaila Lamidi, ti ọpọ eeyan mọ si 'Auxiliary', gẹgẹ bii oludari ẹgbẹ awọn awakọ nipinlẹ Oyo.
Ẹni to ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bii oni jagidijagan to n da ilu ru.
Bi a ko ba gbagbe, lọdun to kọja ni Fọlarin ke si Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria ati Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Oyo pe olori ẹgbẹ awọn awakọ ipinlẹ Oyo, Mukaila Lamidi, ti ọpọ mọ si Auxillary n dunkoko lati gba ẹmi oun lẹyin to gbe fọran kan jade lori ayelujara.
O tẹsiwaju pe ẹni ti Makinde yan gẹgẹ bi olori ẹgbẹ awakọ PMS nipinlẹ Oyo jẹ ẹlẹwọn ati pe iru apẹrẹ wo ni ijọba Makinde n fi lelẹ fun awọn araalu.
Ta lo pa Eleweọmọ?
Eyii ni esi ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde fọ si Fọlarin.
Makinde ni iyalẹnu lo jẹ wi pe ẹni ti wọn fi ẹsun kan pe o ṣekupa olori ọmọ ẹgbẹ awakọ tẹlẹri, Oloogbe Alhaji Lateef Salako, ti ọpọ mọ si 'Eleweọmọ' n pe ẹni kan ni ẹlẹwọn.
Makinde ni o pọn dandan ki oun sọrọ lori ẹsun naa, nitori ọpọlọpọ awọn ipinlẹ lorilẹede Naijiria lo ti n wo awọkọse ipinlẹ Ọyọ, ti wọn si ti da iṣakoso ibudokọ, PMS ti wọn naa silẹ n'ipinlẹ wọn.
Makinde ni, "Taa lo ṣekupa Eleweọmọ? Nibo ni iwe ẹsun naa wa?
O wa lori tabili mi, ẹsun ọdaran ni sigbọn n ko fẹ mu ẹnu lọ bẹ.”
To ba da Makinde loju pe oun mo ẹni to ṣekupa Eleweomo, ko gbe lọ si ileẹjọ
Teslim Folarin ni oju gba oun ti pe irufẹ ọrọ pe oun ṣekupa eeyan le jade lẹnu Gomina.
O ni to ba da Makinde loju pe oun mọ si iku to pa olori ẹgbẹ awakọ naa, Alhaji Lateef Salako, ko jẹ ki awọn morile ileẹjọ.
“Gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Oyo, to ba da Makinde loju pe oun mọ ẹni to pa Eleweọmọ, ko gbe lọ si ileẹjẹ ni kiakia.
Oju gba mi ti nitori ko yẹ ki Gomina ipinlẹ Oyo ma kopa ninu oṣelu ile ọti rara.”
Tani Alhaji Lateef Salako, Eleweọmọ?

Oríṣun àwòrán, others
Alhaji Lateef Salako, ti ọpọ mọ si Eleweọmọ jẹ olori ọmọ ẹgbẹ awakọ NURTW, ti awọn agbebọn kan ṣekupa nigba to mojuto eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu PDP ni Olunlọyọ ni agbegbe Akanran niluu ibadan ni Ọgbọnjọ oṣu kejila, ọdun 2010.
Eleweomo to jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP ati alatilẹyin gomina Oyo nigba naa, Adebayo Akala ni wọn yinbọn fun lori, to si sun sinu agbara ẹjẹ.
Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP fi ẹsun kan pe Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Teslim Folarin lo ṣekupa Eleweọmọ, ti ọrọ si di ti ileẹjọ giga niluu Ibadan.
Lọjọ karun un, oṣu kini, ọdun 2011, ileẹjẹ giga nipinlẹ ni ki Teslim Folarin lọ rọ kun si ọgba ẹwọn Agodi niluu Ibadan.
















