Àwọn ònwòye orílẹ̀èdè àgbáyé pè fún àlàáfíà lásìkò ìdìbò Nàìjíríà

Awọn onwoye orileede agbaye bii ilẹ̀ Amẹrika, Australia, Japan, Norway,
Canada ati UK to ti gunlẹ si orileede Naijiria.
Won ti fi idunu han si iwe adehun alafia ti gbogbo awọn oludije ẹgbẹ́ òṣèlú to n dije fun ipo Ààrẹ ti ọwọ bọ.
W#on ni pe:
"A n gba gbogbo awọn olukopa niyanju lati ko ipa daadaa lati le mu adinku ba ohunkohun to le gbe ọkan awọn eniyan soke ki wọn si lodi si wahala to ba fẹ yọjú, ṣáájú, lasiko naa ati lẹyin idibo ".
Wọn sọ eyi ninu atẹjade kan.
Bakan naa, wọn fun pe si gbogbo awọn ti yoo ṣíṣe to fi mọ àwọn agbofinro pe ki wọn rii pe wọn pese ayika to ni alafia ti abo si daju lakoko idibo.











