Chrisland school: Wón ti ṣe àyẹ̀wò ohun tó yí ikú Whitney Adeniran ká, Ọlọ́pàá ń dúró de èsì rẹ̀

Whitney Adeniran

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ileeṣẹ ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Eko ti alukoro wọn SP Benjamin Hundeyin gba ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ti fi aridaju han lori itesiwaju ohun ti wọn n ṣe lori iku ọmọ ile ẹ̀kọ́ wọn, Whitney Adeniran to papoda lasiko ti wọn n ṣe idije ère idaraya ojule si ojule (inter-house sport).

Hundeyin jẹ ko di mimọ fun awọn oniroyin pé idi ti esi ayẹwo oku ọmọ naa ko ṣe tii jade ni pe o ṣi ni esi kan ti wọn n pe ni "toxicology report" ti wọn n duro de.

Bakan naa, Ọgbẹni Adeniran to jẹ baba Whitney sọ fún BBC Yoruba pe òótọ́ ni nnkan ti Ọlọpaa sọ fun awọn oniroyin.

Ṣáájú ni a ti mu iroyin wa fun yin pe ijọba ti ile ẹ̀kọ́ naa pa ni kete ti wọn bẹ̀rẹ̀ iwadii lati mọ ohun to ṣokùnfà iku Whitney lasiko idije ojúlé si ojule eyi ti ile ẹ̀kọ́ naa ṣe agbekale rẹ ni papa ìṣeré nla to wa ni agbegbe Agege, Ìpínlẹ̀ Eko.

Nigba ti osojumikoro kan ati dokita ile ẹ̀kọ́ naa sọ pe ṣe ni Whitney ṣubú wọọ lulẹ ati pe ikọlu ọkan lo pa a, awọn obi ọmọ naa, paapaa baba rẹ, Michael Adeniran nigba to n pe fun idajọ òdodo sọ pe ina ẹlẹ́ktiriiki lo pa ọmọ oun.

Lara ohun ti o kọ soju opo Facebook rẹ ka bayii pé:

Odindi ọmọ ti ara rẹ pe to si n ṣe daadaa ni mo fun ilé ẹ̀kọ́ Chrisland, òkú ọmọ ni Chrisland da pada fun mi.

Inú ọpọ ibanujẹ ni gbogbo idile mi wa sugbọn ile ẹ̀kọ́ naa n sọ pe awọn ko mọ ń kankan nipa iku ọmọ mi pe gbogbo nkan ti awọn mọ nipe ọmọ mi ṣubú wọọ silẹ, o si ku.

Lati igba taa ti n beere ìbéèrè yii, ile ẹ̀kọ́ naa ti n sọ fún wa pe ka ma ṣe ayẹwo oku naa mọ si mọ pe wọn ni ẹsẹ gigun. Torinaa ni mo ṣe n ke si ẹ̀ka to n ṣe ayẹwo oku nileewosan ile ẹ̀kọ́ Fasiti LASU pe ki wọn jọ̀wọ́ ki wọn jẹ olóòótọ́.

"Ijọba Ìpínlẹ̀ Eko, ìjọba orileede Naijiria, ẹ jọ̀wọ́ ẹ da sii".

Ní ti iya ọmọ naa to ni oun wa níbi eto ti ile ẹ̀kọ́ naa n ṣe lọjọ naa, Arábìnrin Blessing Adeniran ṣàlàyé pe oun ṣáá n gbiyanju lati mọ ibi ti Whitney wa lasiko ti gbogbo eto ọhun n lọ lọwọ nígbà náà ni ọkàn lara àwọn ọmọ ile ẹ̀kọ́ naa sọ fun oun pe o ṣubú lulẹ wọn si ti gbe e dìgbà dìgbà lọ ileewosan fun itọju.

Ẹwẹ, Blessing rii pe ileewosan kọ ni wọn gbe ọmọ oun lọ bikoṣe ibudo ti wọn ti n gba abẹrẹ ajẹsara to si ni igba ti oun sáré de ibẹ, oku ọmọ rẹ lo ba ti ete ati ahọn rẹ ti dudu.

"Kìí ṣe ileewosan ni wọn gbe ọmọ mi lọ, ibudo abẹrẹ ajesara ni wọn gbe e lọ, ṣùgbọ́n ìyẹn ko tilẹ̀ dun mi bikoṣe aisi itọju àkọ́kọ́ to yẹ kí wọn ní, ko si ohunkohun ti wọn ṣe fun un. Oku rẹ ni wọn gbe lọ ileewosan ".

Ó ṣàlàyé siwaju sii pe nigba ti bàbà ọmọ naa de ileewosan lati wa gbé e lọ ileewosan míì, àbọ̀ itọju rẹ sọ pe, o ti baba ku ki wọn to gbe e de ọdọ awọn. O pariwo, Desola, Daddy ti dé, dide e. Ki lo n ṣe ọmọ mi. Ọkọ mi kunlẹ to n sọkún to n bẹ dókítà pe, ẹ ran mi lọwọ, àkọ́bí ọmọ mi niyii."