2023 Election: Ta ni Atiku Abubakar, olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP

Atiku Abubakar

Igbákejì ààrẹ orílẹ̀ èdè yìí nígbà kan rí, Alhaji Atiku Abubakar ní ìrètí wà fún wí pé ó ṣeéṣe kí òun di ààrẹ Nàìjíríà báyìí bí ó ṣe ti ń díje fún ipò yìí fún ìgbà kẹfà lẹ́yìn tó pàdánù ní ẹ̀ẹmàrùn-ún bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1992.

Atiku Abubakar tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin fún ọ̀pọ̀ ìgbà ayé rẹ̀ jẹ́ òṣìṣẹ́ ọba, ìgbákejì ààrẹ Nàìjíríà àti oníṣòwò pọ́ńbélé, tó sì kó ọrọ̀ jọ lẹ́ka epo rọ̀bì.

Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹka tí Atiku ní yìí, ipò ààrẹ Nàìjíríà tó ti ń gbèrò láti ṣe fún ọjọ́ pípẹ́ kò bọ́ si fún-un tó sì tún ń gbèrò láti lọ lẹ́ẹ̀kan si lọ́dún 2023 pẹ̀lú ìgboyà pé òun ní ìrírí àti àwọn àmúyẹ láti mú àtúnṣe bá gbogbo àwọn ìpéníjà tó ń bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fínra.

Lára àwọn ìpèníjà tí Nàìjíríà ń kojú ni àìníṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́, àìsí ètò ààbò tó péye, ọ̀wọ́n gógó àti ètò ọrọ̀ ajé tí kò dúró ire èyí tó gbara lé owó tó ń wọlé lẹ́ka epo rọ̀bì.

Àwọn nǹkan tí Atiku Abubakar fi ń ṣe ìpolongo ìbò rẹ̀ ni àwọn àṣeyọrí tó ní nígbà tó ṣe igbákejì ààrẹ láàárín ọdún 1999 sí ọdún 2007 níbi tó ti jẹ́ olórí ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ètò ọrọ̀ ajé èyí tó mú àyípadà bá ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀, owó ìfẹ̀yìntí àti ẹ̀ka ètò ìfowópamọ́ tó mú àlékún bá ìpèsè iṣẹ́, tó sì tún pọkún owó tó ń wọlé fún Nàìjíríà.

Ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tó ń tako Atiku Abubakar ń tọ́ka sí gbogbo àwọn ẹ̀sùn ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ èyí tí wọ́n kà sí lọ́rùn, tí ọ̀pọ̀ sì gbà pé kò yẹ lẹ́ni tó le túkọ Nàìjíríà níbi tí ìwà àjẹbánu ti gbilẹ̀.

Bákan náà ni wọ́n tún fẹ̀sùn ṣíṣe ojú-ṣàájù kàn-án nígbà tó wà nídìí sísọ àwọn dúkìá ìjọba di ti àládàáni, wí pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí rẹ̀ ni ó ta àwọn nǹkan náà fún.

Àmọ́ Atiku Abubakar jiyàn gbogbo ẹ̀sùn náà, tó sì ní ọ̀rọ̀ ẹnu láti tako òun lágbo òṣèlú ni gbogbo ẹ̀sùn náà.

Ìrètí wà pé Atiku Abubakar yóò mú àtúnṣe bá ìyàpa ẹnu tó ń wáyé lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń díje lábẹ́ rẹ̀, lẹ́yìn awuyewuye tó ń wáyé lẹ́gbẹ́ náà lẹ́yìn tó jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò abẹ́nú wọn.

Àwọn gómìnà kan lẹ́kùn gúúsù Nàìjíríà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP náà kọminú lórí bí Atiku ṣe jáwé olúborí láti gbé àsíá ẹgbẹ́ wọn dání pẹ̀lú ìgbágbọ́ pé ẹkùn gúúsù ló kàn láti pèsè ààrẹ Nàìjíríà lẹ́yìn tí ààrẹ Muhammadu Buhari tó wá láti árìwá ti lo ọdún mẹ́jọ.

Ẹni tí Atiku tún yàn láti ṣe igbákejì rẹ̀ náà tún fa awuyewuye láàárín ẹgbẹ́, tí ọ̀pọ̀ wọn sì ní bí wọn kò ṣe yan gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike le fa nǹkan ńlá fún ẹgbẹ́ náà.

Èèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Nyesom Wike ni àwọn kan ti ní ìgbàgbọ́ pé òun ló ká ojú òṣùwọ̀n láti jẹ́ igbákejì Atiku lẹ́yìn tó pàdánù ìbò abẹ́nú sọ́wọ́ rẹ̀ àmọ́ Atiku ní ó sàn fún òun láti yan gómìnà ìpínlẹ̀ Delta, Ifeanyi Okowa gẹ́gẹ́ bí igbákejì òun.

Lára àwọn tí Atiku Abubakar ń forí gbárí pẹ̀lú rẹ̀ ni Bola Tinubu tẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, àti Peter Obi, ẹni tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ń ṣe àtìlẹyìn fún lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party.

Lára àwọn ìpèníjà mìíràn tí Atiku ń kojú ni ọ̀nà láti lè yí àwọn ọ̀dọ́ lọ́kàn padà láti lè dìbò fún-un nírtorí ọjọ́ orí rẹ̀ àti pé ẹgbẹ́ òṣèlú tó ti wá jẹ́ èyí tí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn k]o ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.

Atiku Abubakar ti wà lágbo òṣèlú fún ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn tó sì ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti PDP láti fi wá ipò ààrẹ Nàìjíríà.

Ní ọdún 2006 ni Atiku Abubakar kọ́kọ́ fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ fẹ̀sùn kàn-án wí pé ó kó owó tó lé $125m (£95m) tó jẹ́ owó ìlú sí àpò ara rẹ̀.

Bákan náà ni àtẹ̀jáde kan tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà gbé síta ní ọdún 2010 fẹ̀sùn kan Atiku pé ó da owó $40m (£30.55m) tí ìrètí wà pé ó jẹ́ owó ìlú sákoto báǹkì ìyàwó rẹ̀ ní Amẹ́ríkà.

Títí di àsìkò yìí wọn ò ṣe ẹjọ́ kankan nílé ẹjọ́ lórí àwọn ẹ̀sùn yìí, tí Atiku Abubakar sì ní gbogbo ẹ̀sùn kíkó owó ìlú jẹ tí wọ́n fi kan òun ló jẹ́ àràbú lásán, àti pé ọ̀rọ̀ òṣèlú ni.

Ní oṣù Kìíní ọdún 2019 ni Atiku lọ sí Amẹ́ríkà láti fòpin sí gbogbo àhesọ ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn ń gbé kiri nígbà náà wí pé kò le yọjú sí orílẹ̀ èdè náà nítorí wọ́n máa fi òfin gbe ni.

Atiku Abubakar ń rawọ́ rasẹ̀ sí àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ń fẹ́ àyípadà sí ètò ọrọ̀ ajé láti dìbò fún òun lẹ́yìn ìṣèjọba ààrẹ Muhammadu Buhari kò mú àyípadà tó gbòòro kan bá ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà àti pé ẹlẹ́yàmẹ̀yà ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ iṣẹ́ pínpín ṣe.

Lára àwọn iṣẹ́ tó sọ Abubakar di olókìkí oníṣòwò ni ní iléeṣẹ́ Intels, tó ń rí sí gbégbe epo rọ̀bì, èyí tí Atiku wà lára àwọn tó da sílẹ̀ lọ́dún 1982 nínú ṣọ́ọ̀bù kọntena kan ṣe di iléeṣẹ́ ńlá tó gbà ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn síṣẹ́ lásìkò yìí.

Ọ̀pọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ló dà sí ètò ìbojú àánú wo ni, tí ọ̀kan lára rẹ̀ sì jẹ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásìtì American University èyí tó wà ní ìpínlẹ̀ Adamawa. Ilé ẹ̀kọ́ gíga yìí ti pèsè ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Chibok tí àwọn Boko Haram jí gbé nígbà kan.

Atiku Abubakar máa ń ka ara rẹ̀ kún ọ̀kan nínú àwọn tó jẹ àǹfàní ètò ẹ̀kọ́ mọ̀-ọ́n-kọ mọ̀-ọ́n-kà èyí tí ilé ẹ̀kọ́ náà ń pèsè, èyí tí àwọn Boko Haram sì lòdì sí gidi.

Ta ni Atiku Abubakar?

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, AFP

Ní ìpínlẹ̀ Adamawa ni wọ́n bí Atiku Abubakar sí sínú ìdílé mùsùlùmí, tí bàbá rẹ̀ tó jẹ́ adaranjẹ̀ àti oníṣòwò sì lọ sí ẹ̀wọ̀n fún ìgbà díẹ̀ nígbà kan rí fẹ́sùn wí pé kò jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ lọ sí ilé ẹ̀kọ́.

Lẹ́yìn tó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, Atiku darapọ̀ mọ́ iléeṣẹ́ aṣọ́bodè, Nigeria Customs Service, tó sì ṣiṣẹ́ ní papakọ̀ omi àti ti òfurufú ní ìpínlẹ̀ Eko.

Atiku ní ìwà àjẹbánu kún iṣẹ́ náà fọ́fọ́ àmọ́ òun kò bá wọn lọ́wọ́ nínú rẹ̀, bó ṣe jẹ́ wí pé pípa owó fún ìjọba ló jẹ òun lógún fún gbogbo ìgbà tí òun wà lẹ́nu iṣẹ́.

Nígbà tó ń ṣiṣẹ́ náà ló bẹ̀rẹ̀ sí ní ra àwọn dúkìá àti ilẹ̀ láti fi ṣòwò kó tó di wí pé ó wá bá ara rẹ̀ lẹ́ka epo rọ̀bì àti afẹ́fẹ́ gáàsì, tó sì ní láti kékeré òun ni òun ti nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣòwò.

Iṣẹ́ aṣọ́bodè rẹ̀ fun ní àǹfàní láti mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ológun àtàwọn olóṣèlú. Ibẹ̀ ní Atiku ti ní ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán pẹ̀lú Shehu Musa Yar'Adua, ẹni tí Atiku máa ń pè ní bàbá ìsàlẹ̀ rẹ̀ lágbo òṣèlú.

Nígbà tí Nàìjíríà ṣì wà lábẹ́ ìjọba ológun, àwọn méjéèjì yìí bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹkùn mìíràn láti ṣàgbékalẹ̀ ìjọba alágbádá.

Ní ọdún 1989, Atiku Abubakar fi iṣẹ́ aṣọ́bodè sílẹ̀ láti gbájúmọ́ òṣèlú gangan. Ọdún 1992 ló kọ́kọ́ díje láti dupò ààrẹ Nàìjíríà nínú ẹgbẹ́ èyí tí Shehu Yar'Adua ṣe agbátẹrù rẹ̀ àmọ́ tó padà júwọ́ sílẹ̀ nígbà tó ṣe ipò kẹta níbi ìpele àkọ́kọ́ àmọ́ ìjọba ológun ìgbà náà da ìbò náà nù.

Atiku Abubakar sá lọ sí ìlú London lẹ́yìn tí ìṣèjọba ọ̀gágun Sani Abacha ń gbóná mọ́ wọn, wọ́n sọ Shehu Yar'Adua sẹ́wọ̀n níbi tó kú sí.

Ní ọdún 1997 ni Atiku Abubakar padà sí Nàìjíríà lẹ́yìn tí Abacha mú àdíkù bá ọwọ́ líle tó fi mú gbogbo nǹkan, tó sì di igbákejì ààrẹ lọ́dún 1999 lábẹ́ ìṣèjọba Olusegun Obasanjo.

Atiku Abubakar ní òun yóò dá ògo orílẹ̀ èdè yìí padà tí àwọn ọmọ Nàìjíríà bá fi àyè gba òun láti di ààrẹ lọ́dún 2023.

Ìyàwó mẹ́rin àti ọmọ méjìdínlọ́gbọ̀n ni Atiku Abubakar bí.

Àwọn ta ló ń díje láti tukọ̀ Naìjíríà?

Mọ̀ síi nípa àwọn tó ń du ipò ààrẹ Nàìjíríà

Ya olùdíje kan nítorí kí o lè kà nípa wọn

Bola Tinubu

All Progressives Congress (APC)

  • Ọjọ́ orí: 70
  • Ó gba oyè nípa ìmọ̀ ìṣirò ní fásitì ìpínlẹ̀ Chicago (Chicago State University)
  • Ó ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Eko fún sáà méjì láti 1999 sí 2007
  • Ó ṣojú [wọ̀ Oòrùn ìpínlẹ̀ Eko ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà láti 1992 sí 1993.
  • Ó jẹ́ èèyàn kan tó ti pẹ́ nhí ìdí òṣèlú Nàìjíríà, ìgbà àkọ́kọ́ tí yóò du ipò ààré nìyí.
  • ìgbógun ti ìṣèjọba sójà
  • Mú ìdàgbàsókè bá owó tó wọlé fún ìpínlẹ̀ Eko ní ọ̀nà tó ju ìlọ́po mẹ́rin lọ láti N22.2 blilion ní 1999 sí N220.9 bíllion ní 2007.
  • Ó ṣiṣẹ́ bíi ọ̀gá tó ń ṣe àyẹ̀wò ìwé owó, lẹ́yìn náà ló ṣe iṣẹ́ akápò ní iléeṣẹ́ Mobile Producing Nigeria, ọ̀kan lára iléeṣẹ́ epo tó tóbi jù ní Nàìjíríà.
  • Láti ṣé àlékún ọjà tí Nàìjíríà ń tà síta àti láti dín ìgbẹ́kẹ̀lé Nàìjíríà kù lóríiohun òkèrè.
  • Láti sọ àìníṣẹ́ ṣe láàrin àwọn ọ̀dọ́ di ìlàjì láàrin ọdún mẹ́rin àti láti pèsè iṣẹ́ mílíọ́nù kan nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ kọ̀pútà láàrin ọdún méjì.
  • Mú àyípadà bá ètò ìdájọ́ kó lè mójútó ìdènà ìrúfin àti ṣe àlékún ìfọkàntán lórío àwọn agbófinró.

Atiku Abubakar

Peoples Democratic Party (PDP)

  • Ọjọ́ orí: 76
  • Igbákejì ààrẹ Naìjíríà láti ọdún 1999 sí 2007.
  • Ó kàwé gboyè eléèkejì (masters) lórí àjọṣepò àwọn orílẹ̀èdè (International Relations) láti fásitì Anglia Ruskin University , UK.
  • Ó jẹ́ ẹni tó ṣe iṣẹ́ aṣọ́bodé rí kó tó di olóṣèlú láti nǹkan bíi ọdún 1980.
  • Ó du ipò ààrẹ náà ní ẹmaàrú ùn ní ọdún 1993, 2007,2011, 2015 àti 2019, ṣùgbọ́n kò wọlé.
  • Òun ló dá fásitì Amẹ́ríkà ti Nàìjíríà (American University of Nigeria) silẹ̀, fasitì náà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Chibok ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́.
  • Oníṣòwò tó ṣe àṣeyọrí tó ní okòwò níbi ọ̀rọ̀ epo, ọ̀gbìn, bánkì àti ògùn.
  • Ètò títa iléeṣẹ́ ìjọba tó ní àríyànjiyàn nínú.
  • Fún àwọn aládáni ní ipa tó pọ̀ nínú ètòi ọrọ̀ ajé.
  • Fún ìṣọ̀kan orílẹ̀èdè ní agbára síi nípa ìṣe déédéé àti ìdájọ́ òdodo láàrin àwọn ẹ̀yà tó ń gbé ní Nàìjíríà.
  • Ṣe àtúntò ètò ìṣèjọba Nàìjíríà.

Peter Obi

Labour Party

  • Ọjọ́ orí: 60
  • Gómìnà tó ṣe sáà méjì ní ìpínlẹ̀ Anambara láti ọdún 2007 sí ọdún 2014.
  • Ó du ipò igbákejì ààrẹ ní ọdún 2019.
  • Oníṣòwò tó kàwé gboyè nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ọgbọ́n (Philosophy) ni University of Nigeria Nsukka.
  • "o bá ìpínẹ̀ rẹ̀ dá okòwo ''sub soveriegn wealth fund '' tó tó $156 million ní ìgbà tó fẹ́ fi orí oyè sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi gómìnà.
  • Ó gbé ìpínlẹ̀ Anambara lọ sí ipò kínní láti ipò kẹrìndínlọ́gbọ̀n nínú àwọn ìpínlẹ̀ Nàìjíríà lórí ìdánwò NECO àti WAEC.
  • Ó ní àwọn ṣọ́ọ̀bù alágbàtà kan tó fún ẹgbẹgbẹ̀rún èèyàn ní iṣẹ́.
  • Ó ṣèlérí láti kó àkóyawọ́ la'ti ríi pé ìjọba gbógun ti ìwà àjẹbánu.
  • Ó ṣèlérí láti gbé Nàìjíríà dé ibi ṣíṣe nǹkan láti ibi lílo nǹkan.
  • Ó ṣèlérí láti gbé ọlá fún ìdàgbàsókè àwọn èèyàn nípasẹ̀ fífi owó sí ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ àti sáyẹ́sì, ètò ìlera àti àwọn nǹkan amáyédẹrùn.

Rabiu Kwankwaso

New Nigeria Peoploes Party (NNPP)

  • Ọjọ́ orí:66
  • Mínísítà fún ètò ààbò láti ọdún 2003 sí ọdún 2007
  • Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano láti ọdún 1999 sí ọdún 2003, àti láti ọdún 2011 sí ọdún 2015.
  • Ó ṣojú agbègbè Madobi ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin n;i ọdún 1992 àti ààrin Kano ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà láàrin ọdún 2015 sí ọdún 2019.
  • Ó kàwé gboyè PhD ní orí ìmọ̀ ẹ̀rọ ilé kíkọ́ láti fásitì Sharda ní India.
  • Ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ àti ìtọrẹ.
  • Ó ṣe àfikúnb iye àwọn tó wọ ilé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ láti mílíọ́nù kan lọ́dún 2011 sí mílíọ́nù mẹ́ta ní ọdún 2015 nígbà tó kúrò lórí oyè.
  • Ó pèsè oúnjẹ ọ̀fẹ́ àti aṣọ ilé ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀.
  • Ó dá fásitì Sáyẹ́nsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ ìpínlẹ̀ Kano sílẹ̀ ní Wudil sílẹ̀. Ó tún dá Northwestern University sílẹ̀. Àwọn fásitì ìpínlẹ̀ Kano méjéjì.
  • Ó ṣe ìlérí láti pèsè iṣẹ́ nípasẹ̀ ìdókòwò lórí ètò ọ̀gbìn.
  • Kojú ètò ààbò tó mẹ́hẹ.
  • Ó ṣe ìlérí láti tẹ̀lé òfin àti ìlànà tó tọ́.