"Ẹ fáwọn ajínigbé láǹfàní àti jí mi gbé, ẹ wá ń béèrè ìbò mi báyìí"

Ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria lo n gbe ninu ifoya awọn ẹgbẹ ajinigbe pawo gbogbo.
Ibẹru yii si pọ pupọ julọ lẹkun iwọ oorun ariwa Naijiria nibi ti ogunlọgọ ti sa fi ile ati ọna wọn sílẹ
Ipenija ọrọ abo yii lo wa tumọ si pe ẹkun naa, nibi ti awọn oludibo pọ si julọ lorilẹede Naijiria, lee maa le kopa ninu eto idibo apapọ ti yoo waye loṣu keji ati ikẹta ọdun 2023.
Ni ilu Bakiyawwa nipinlẹ Katsina, lẹkun ariwa orilẹede Naijiria, gba alejo awọn agbebọn ajinigbe, ti wọn gun alupupu wa ji eeyan mẹtadinlọgọta gbe nibẹ.
Ileto kekere ni ileto yii, iṣẹ agbẹ si ni ojulowo iṣẹ aṣejẹ nibẹ; nitori naa, ko si ẹni to le e lero pe awọn ọdaran yii le e wa ji ẹnikẹni gbe nibẹ fun owo.
“Ọjọ mejidinlogoji ni wọn fi ji iyawo mi gbe.”
Abduljabara Mohammed ni miliọnu kan naira loun san, ki wọn to tu iyawo oun silẹ.
"Agbebọn pa eeyan to le ni ọgọrun lọjọ kan soso nipinlẹ Katsina"
Zaradeen Musa, ẹni ọgbọn ọdun naa sọrọ lori iriri tirẹ.
Nnkan bii agogo kan oru ni wọn fipa ja ilẹkun ile rẹ, wakati mẹrin sì lawọn agbebọn naa fi sẹ ọṣẹ ni ileto rẹ laisi idiwoọ tabi ipaya awọn agbofinro.
“Gbogbo owo ti mo ni pẹlu alupupu kan ni mo fun wọn, nigba yẹn gan ṣe ni mo n bẹ wọn pe ki wọn maa ji emi naa gbe pẹlu.”
Ori lo ko Maria Sani ẹni ọdun marundinlaadọta yọni tirẹ. Nigba t’awọn agbebọn naa n ko awọn ti wọn ji gbe lọ si ibiba wọn lo sare bọ mọ wọn lọwọ.
O ṣi n mikan ni bayii lori ohun ti iba jẹ ipin rẹ, ka ni ko ri anfani lati sa ni.
O ni gẹgẹ bi ọpọlọpọ, oun ko ni lee ri owo itusilẹ ti wọn yoo beere san.
Gbogbo awọn ti wọn ji gbe, lẹyin idunadura ọpọlọpọ oṣu ti wọn san owo tabi dukia wọn bii alupupu ni wọn ṣẹṣẹ tu won sílẹ.
Eyi fihan bi ọwọja ijinigbe wọnyi ti ṣe gbilẹ si bayii ni nitori pe lọwọ yii, koda awọn talaka pẹlu ko bọ kuro lọwọ wọn.
Amoṣa, awọn olugbe ileto Bakiyawwa le ki ara wọn ku oriire nitori pe ọpọ igba ni ikọlu awọn ajinigbe-pawo wọnyi tun le ja si iku.
Gẹgẹ bi eyi to waye ni ọjọ Ẹti to kọja ni ipinlẹ Katsina nibi ti awọn agbebọn wọnyi ti pa eeyan to le ni ọgọrun ni ileto miran nibẹ.

Oríṣun àwòrán, nduka orjinmo/bbc
"INEC kede pe ewu nla ni lati ṣeto idibo lawọn agbegbe kan nipinlẹ Katsina"
Ni oṣu kejila ọdun 2022, ajọ eleto idibo Naijiria kede pe ewu nla ni yoo jẹ lati ṣeto idibo lawọn agbegbe kan ni ipinlẹ Katsina.
Amoṣa ko ti si ẹni lee sọ lori ohun ti yoo ṣẹlẹ lọjọ idibo.
Ọjọgbọn imọ ofin kan, Chidi Odinkalu ni afaimọ kí ọrọ ibo yii ma di ti wahala ti wọn yoo maa pari nile ẹjọ iyen bi ipenija abo ko ba jẹ ki idibo waye, ti ọkan ninu awon oludije ba si fariga pe iru awọn agbegbe bẹẹ ni oun ti ni ireti awọn oludibo to po.
Tẹlẹ awọn eeyan wulẹ maa n yago fun ibo didi nitori ifoya wahala lawọn ipinlẹ bii Imo, Anambra, Eko ati Rivers.
“Ẹ faaye gba awọn ajinigbe lati ji mi gbe, ẹ wa n wa ibo mi bayii.”

Oríṣun àwòrán, nduka orjinmo/bbc
Eyi lọrọ ti Arabinrin Sani gba ẹnu ogbufọ sọ.
Aarẹ Muhammadu Buhari loun ati ọpọ awọn olugbe ileto naa dibo fun. Amọ bayii o ni oun ko tilẹ ni dibo lọtẹ yii.
Aarẹ Buhari n fi ipo silẹ lẹtin saa meji lori oye, Bola Tinubu lo n dije bayii fun ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣe ijọba lọwọ ni Naijiria.
Lawal Suleiman, to tifi igba kan ri jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu APC , sọ pe “ Bawo ni eeyan yoo se tun dibo fun APC pẹlu gbogbo iya wọnyi.”
Oun nikan lo n ṣe ẹgbẹ oselu Labour Party ni ileto naa, ọpọ ninu awọn tiku ni ileto naa ni wọn n so pe bi awọn yoo ba tilẹ dibo o ṣeeṣe ko maa jẹ APC.
“Bi Buhari ko ba ti le yanju isoro orilẹede yii ko si ẹni ro le ṣe e ,” ni ọrọ ti Nana Samaila ti ipenija ọrọ abo le kuro ni ilu rẹ, Batsari nigba ti awọn agbebọn kọlu ibẹ ni ọdun mẹta sẹyin sọ fun BBC news.
Ọmọ rẹ , Aisha Mama, pẹlu ṣẹṣẹ sa kuro ni ilu Dangyya, roun tọkọrẹ ni nitori gbonmọgbọnmọ ikọlu loruloru awọn agbebọn si ileto wọn ti sọ wọn di ẹni to n gbe ninu oko wọn fun ọpọlọpọ ọsẹ .

Oríṣun àwòrán, nduka orjinmo/bbc
Arabinrin Samaila ti ni ireti tẹlẹ pe Aarẹ Aarẹ Buhari gẹgẹ bi ajagunfẹyinti to tun jẹ ọmọ ipinlẹ Katsina yoo lee yanju iṣoro Naijiria nigba 5o kọkọ sibo fun un lọdun 2003, amọ ijakulẹ nla lọrọ naa ti n jẹ bayii fun oun at’awọn miran bẹẹ. ijakulẹ ìjọba ti bu omi tutu aii lọkan.
Ọpọlọpọ awọn akẹkọọ lawọn ajinigbe wonyi ti ji gbe ti wọn si ti da pada, debi wipe ijoba ipinlẹ naa ni lati sọ fun awọn eeyan ibẹ pe ki wọn dira o lati le maa koju awọn agbebọn naa.
Awọn oludije to n lewaju ninu idije fun ipo aarẹ lorilẹede Naijiria naa ti mọ bi wahala ọrọ a o ṣe wuwo to, ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu ọwọngogo ounjẹ eyi to ti mu ki igbe aye nira lorilẹede Naijiria bayii.
Ahmed Bọla Tinubu ti APC, Atiku Abubakar ti PDP, Tinubu ti APC ati Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party ti n fonrere atunto ileeṣẹ ọlọpaa, idagbasoke ileeṣẹ ọmọogun pẹlu igbayeg adun wọn ati bẹẹbẹ lọ.
Ohun ti wọn n sọ yii ko yatọ si ohun ti aarẹ Naijiria Muhammadu Buhari naa sọ lori didoju ija kọ ẹgbẹ alakatakiti esin gbogbo lẹkun ila oorun ariwa Naijiria ti ko seso aṣeyọri kankan.

Oríṣun àwòrán, twitter/Peter obi/Rabiu kwankwaso/asiwaju bola tinubu/atiku abubakar
Bi o ṣe n gbero ati koju awọn alakatakiti esin lẹkun ila oorun ariwa, labẹ akoso rẹ ni rogbodiyan gbogbo n waye lẹkun iwọ oorun ariwa ati ila oorun gusu.
Agbẹ ni Mohammed Yusuf lati Kastina tẹlẹ ki ipenija a o to sọọ di ẹni to n ta ohun mimu tii ati ohun jijẹ ipanu noodlesni oju popo nilu Kano.
O ni Aarẹ Buhari “ba ọrọ aje jẹ, bẹẹ wahala ọrọ abo tun peleke sii.”
Ipinlẹ Kano, Katsina ati Kaduna jẹ ipinlẹ mẹta ti o ṣe koko fun ẹnikẹni to bafẹ dije du ipi aarẹ lorilẹede Naijiria nitori omilẹngbẹ awọn oludibo to wa nibẹ.
Awọn oludibo to forukọsilẹ nibẹ pọ ju gbogbo awọn oludibo to wa ni gbogbo ipinlẹ maraarun un to wa lẹkun ila oorun gusu Naijiria.
Ipinlẹ mẹta yii naa ni ibo to gbe Muhammadu Buhari de ipo aarẹ ti pọ julọ nigba mejeejito fi ṣe saa lori oye,. Amọ bi awọn kan ṣi ṣe n tẹle APC nibẹ, ọpọ n woye pe agbara ẹgbẹ oṣelu naa ti walẹ nibẹ nitoei gulegule wahala abo.
Ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin, okuta ni wọn ju lu baluu aarẹ lasiko to ṣe abẹwo kan sibẹ.
Igi tẹẹrẹ ti a foju rena ti n yi ni ni ladugbo omi danu ni Rabiu Kwankwaso ro jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples Party (NNPP).
Awọn ololufẹ rẹ nikan lo n si n lero pe yoo bori ibo aarẹ ro n bọ yii, amoṣa ohun gan ni igi wọrọkọ to le da ina ibo aarẹ yii ru fun ẹnikẹni ro ba nlepa ati di aarẹ lọdun yii ni Naijiria.
O ti fi igba kan ri jẹ gomina ipinlẹ Kano, ati minisita fun ọrọ abo. Gbajumọ nla ni ni ipinlẹ Kano ari Jigawa to mu ile ti i.
Bi o ba lọ ko ibo to pọ julọ ninu ibo miliọnu mẹfa to wa ni Kano, wyi to jẹ ibo to pọ julọ ṣekeji si ipinlẹ Eko, yoo da wahala silẹ fun APC ati PDP.
Eyi lee jẹ anfani fun Labour ti ko ni gbongbo rara ni ẹkun naa.
Gẹgẹ bi iṣe ọpọ awọn oloṣelu ni Naijiria, ọpọ igba ni Kwankwaso ti fo kuro lẹgbẹ oṣelu kan lọ si omiran. Ẹgbẹ oṣelu PDP lo n gbe si lẹyin tẹlẹ, aheaọ ọrọ to si n kaakiri ni pe o ṣeeṣe ko ju ọwọ silẹ fun Atiku to jẹ oludije PDP to situn jẹ ọmọ ẹkun oke ọya kan naa.
“Oun ati Obi ko lee bori bi o tilẹ jẹ pe awon naa ni ọna miran to wa yatọ si Atiku to jẹ onifẹ si eto iṣejọba ọlọrọ kiko jọ (capitalist) .”
Eyi ni ọrọ ti Umar Yahaya, akẹkọọ fasitikan to n ṣe iṣẹ kanuka u nitosi Kaduna sọ.
O tẹsiwaju, o ni, “ Ẹnikẹni to ba dibo fun APC n kan sara si ijakulẹ wọn ni.”












