N2.1m ni ọ̀gá mi ‘transfer’ sí wa lójú ìbọn, ká tó jó òun àti aya rẹ̀ mọ́lé - Awakọ̀

Oríṣun àwòrán, Ogun Police
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti kéde pé àwọn afurasí mẹ́ta ni àwọn ti nawọ́ gán báyìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣekúpani tó wáyé ní àìsùn ọdún tuntun ní ìlú Abeokuta.
Àwọn afurasi mẹtẹẹta ni Lekan Adekanbi ti inagijẹ rẹ n jẹ Koroba, Ahmed Odetola ti wọn n pe ni Akamo ati Waheed Adeniji ti wọn n pe ni Koffi.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Ogun, Abimbola Oyeyemi to fi ikede náà sita ni iwadii to gbopọn ni awọn ṣe lati nawọ gan awọn afurasi naa lẹyin ti wọn pa odidi idile run laisun ọdun tuntun, ọdun 2023.
Oyeyemi ni nigba ti awọn n ṣe iwadii awọn lọwọ ni awọn nawọ gan, Lekan Adekambi dẹrẹba awọn tọkọtaya naa pẹlu ẹri to daju pe o lọwọ ninu iṣẹlẹ buburu naa ti awọn si n ba iwadii awọn lọ.
Ó ṣalaye pe ni ọjọ Keji, oṣu ọdun 2023 ni Lekan ṣadede ṣubu lulẹ ni ọgba ẹwọn to wa ti awọn si sare gbe lọ si ile iwosan fun itọju.
Awakọ Fatinoye sa kuro nile iwosan, lọ si Iseyin, amọ Abeokuta lati pada nawọ he - Ọlọ́pàá
O ni ibi to ti n gba itọju naa lọwọ lo wa to fi fo odi (fence) ile iwosan ọhun to si gba ibẹ salọ ti eyi fidi rẹ mulẹ fun wa pe ọmọkunrin naa ni nnkan kan to mọ nipa iku awọn idile naa.
Oyeyemi tẹsiwaju pe idi niyi ti Kọmiṣọna ọlọpaa Ogun fi wa kan-an nipa lati waa ri àti awọn ti wọn ba jọ lọwọ ninu iṣẹlẹ naa ki wọn si foju wọn wina ofin.
O ni nigba to ya ni awọn gbọ pe o ti sa lọ si ọdọ ẹgbọn rẹ kan ni ilu Iseyin, ipinlẹ Oyo amọ nigba ti awọn fi maa de ibẹ, Lekan tun ti na papa bora.
Agbẹnusọ ọlọpaa naa ni awọn wa fi kun iwadii awọn lati ṣe awari ọmọkunrin naa ni awọn ri ni ibi to sapamọ si ni agbegbe kan Abeokuta lọjọ Kọkanlelogun oṣu Kiini ọdun 2023.
Nitori awọn tọkọtaya Fatinoye kọ̀ lati ya mi lowo lati fi ra ọkada àti lati fowo kun owo oṣu mi, ni mo fi pa wọn – Afurasi
Oyeyemi ni nigba ti awọn n fi ọrọ wa afurasi naa lẹnu wo, o ni lati ọdun 2018 ni oun ti n ba awọn tọkọtaya naa ṣiṣẹ gẹgẹ bi awakọ.
Ó ni oun ni oun wa nidii bi ikọlu naa ṣe waye ti oun pe àwọn eniyan meji mii kunra Waheed Adeniyi àti Ahmed Odetola lati wa jawọn lole ti wọn si ṣe iṣẹ laabi naa.
“O jẹwọ pe awọn tọkọtaya naa kọ lati fikun owo oṣu oun ati pe òun ni ki wọn wọn ya oun lowo lati ra ọkada amọ wọn kọ ni oun fi gbe ìgbésẹ̀ náà.”
O salaye siwaju pe lọjọ ti isẹlẹ naa ṣelẹ, oun ati awọn akẹgbẹ rẹ meji duro de awọn tọkọtaya lati pada de lati ile ijọsin fun ajọyọ adura ọdun tuntun nigba to ni anfani lati wọ ninu ile, ti wọn si kọlu wọn lẹsẹkẹsẹ.
Nigba ti wọn bi wọn pe ki lo de ti aja to wa ninu ile naa kofi kọlu wọn, o ni aja naa da oun mọ nitori oun ni oun ma fun ni ounjẹ.
Lẹyin ti wọn kọlu awọn tọkọtaya naa, wọn fi tipatipa mu ọkọ, Kehinde Fatinoye lati fi owo ransẹ si wọn lati ninu apo owo banki rẹ si apo owo mii.
Apo asunwọn owo to wa ni banki Kuda to jẹ ti Ahmed Odetola lo fi owo naa ransẹ si sugbọn ko lọ.
Asiko naa ni Lekan Adekanbi fun oloogbe ni apo owo miiran to jẹ ti Access, ti wọn si gba owo toto miliọnu meji naira ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan le ni meji loju ibọn.
Hammer nla ni awakọ fi ṣekupa Iyawo, ti Waheed Adeniyi si fi ọbẹ gun ọkọ pa
Bi Lekan ṣe mọ pe orukọ oun ti han sita lẹyin ti wọn fi apo owo rẹ gba owo lọwọ awọn tọkọtaya naa lo ba pinnu lati gba ẹmi wọn, ti Waheed Adeniyi, ti wọn mọ si Koffi si mu ọbẹ lati ile idana lati fi gun ọkọ, Kehinde Fatinoye, ti Lekan Adekanbi si lọ Hammar nla to mu wa lati ile fi ṣe isẹ ibi naa fi gba iyawo, Bukola Fatinoye lori, to si ku lẹsẹkẹsẹ.
Wọn wọ ọmọ kan soso ati ọmọ ti wọn gba tọ sinu odo
Nigba ti wọn ṣe isẹ ibi naa lọwọ, ọmọ kankan soso tọkọtaya naa, Oreoluwa Fatinoye ati ọmọ ti wọn gba tọ, Felix Olorunyomi wọle, ti awọn afurasi apaniyan naa ṣi kọlu, so wọn pẹlu okun, ti wọn ru wọn lọ si odo afara Ogun ni agbegbe Adigbe, ti wọn si ju awọn mejeeji sinu odo naa.
Ori lo ko Felix Olorunyomi yọ nigba ti okun ara tiẹ tu, to si ni anfani lati rapala jade kuro ninu odo naa sugbọn Oreoluwa ko ni anfani naa, ti wọn si oku rẹ lọjọ keji.
Waheed Adeniyi, ti ọpọ mọ si Koffi ati Ahmed Odetola, ti ọpọ mọ si Akamo ni ọwọ tẹ ni agbegbe Ogere, lọjọbọ, ọjọ kẹsan, oṣu keji, ọdun 2023.
Kọmisọna ọlọpaa ni ki wọn lọ ile ẹjọ lẹsẹkẹsẹ
Awọn afurasi mẹta to jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye ni wọn ti jẹwọ ipa ti wọn ko ninu bi wọn ṣe ṣekupa mọlẹbi naa.
Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Frank Mba ti wa palasẹ pe ki wọn gbe awọn afurasi lọ si ileẹjọ lẹsẹkẹsẹ.
Ọwọ́ wa ti tẹ gbogbo afurasí apànìyàn tó run ìdílé Fatinoye l‘Ogun - Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Farinloye
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kede pe ọwọ ti tẹ awọn afurasi apaniyan to ṣekupa osisẹ banki apapọ tẹlẹ, Kehinde Fatinoye, iyawo ati ọmọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Oyeyemi Bola, lo kede ọrọ naa lori ayelujara lọjọ lọjọbọ, ọjọ kẹsan, ọsu keji, ọdun 2023.
Oyeyemi ni, “Gbogbo awọn to lọwọ ninu iku tọkọtaya Fatinoye ati ọmọ wọn niluu Abeokuta ni ọwọ ọlọpaa ti tẹ.
Tọkọtaya naa, Ọgbẹni Kẹhinde Fatinoye to jẹ ọga agba lẹka eto ipawowọle (Marketing Manager) ati Arabinrin Olubukola Fatinoye toun naa jẹ oṣiṣẹ fasiti eto ọgbin l'Abẹokuta, FUNAAB l'awọn kan ṣe ikọlu si ile wọn, ti wọn si tun ju ọmọ wọn ati alabagbe wọn sodo.
Saaju ni Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti rọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun lati ri pe awọn ri awọn apaniyan naa, ki ofin si fiya jẹ wọn fun ẹsun naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ta ni tọkọ-tiyawo Fatinoye naa?
Iwadii fihan pe oṣiṣẹ banki apapọ orileede Naijiria, CBN ni Ọgbẹni Kẹhinde Fatinloye, nigba ti iyawo rẹ, Arabinrin Bukọla jẹ oṣiṣẹ fasiti ọgbin to wa niluu Abẹokuta, iyẹn Federal University of Agriculture, Abẹokuta, FUNAAB.
Lara awọn ti wọn n gbe lagbegbe naa la gbọ pe wọn ranṣẹ si awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana nigba ti wọn ri ile wọn to n jona lọwọ, ti wọn si ni k’awọn panapana to debẹ, aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ.
Igba ti wọn lawọn panapana wọnu ile naa, ni wọn too mọ pe n ṣe ni wọn wa dana sun t’ọkọ ti’iyawo naa mọle.
















