A yọ ọta ìbọn lára Bolanle Raheem, a sì rí ilé ọta nínú ọkọ̀ rẹ̀ - Ẹlẹ́rìí

Oríṣun àwòrán, Bolanle Raheem/Instagram
Igbẹjọ lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan ọlọpaa kan, Vandi Drambi, tẹsiwaju ni Ileẹjọ giga ipinlẹ Eko lọjọbọ.
Ọlọpaa to wa nidi ẹjọ naa si jẹri lori iwadii ti wọn ṣe lẹyin iku agbẹjọro obinrin, Bolanle Raheem.
Ọlọpaa ọhun, Adeyemo Olubummi ni lati ibi ọdun mọkanlelogun ni oun ti darapọ mọ ileeṣẹ orilẹede Naijira.
O ni iwadii oun fihan pe Vandi Drambi lọwọ ninu iku agbẹjọro obinrin naa.
Agbẹjọro agba nipinlẹ Eko, Moyosore Onigbajo lo lewaju ninu fifi ọrọ wa Ọlọpaa naa lẹnu wo, bo ṣe n jẹri ni ileẹjọ.
"Iwadii wa fihan pe olujẹjọ Vandi lo ṣekupa Oloogbe Omobolanle Raheem"
Adeyemo tẹsiwaju ninu ẹri rẹ fun ileẹjọ pe awọn ri bi wọn ṣe yọ ọta ibọn lara oloogbe, ti awọn si ni fidio bi wọn ṣe yọ ọta ibọn naa jade.
Agbẹjọro ijọba, Moyosore Onigbajo, wa gbe fidio ẹri naa, ọta ibọn ati iwadi wọn, to si fi gbe fun ileẹjọ gẹgẹ bi ọkan lara ẹri niwaju ileẹjọ.
Ileẹjọ safihan fidio ọhun, ti ileẹjọ si ri ihoho oloogbe ati ibi ọta ibọn naa ṣe wọle si ni igbaya.
Fidio naa tun safihan bi ọta ṣe ba egungun oloogbe jẹ ati bi wọn ṣe yọ ọta ibọn naa jade.
Nigba ti agbẹjọro ijọba, Moyosore Onigbajo, beere lọwọ Adeyemo pe ki ni ero rẹ lori esi iwadii to ṣe?
Adeyemo to jẹ ẹlẹrii ni iwadii awọn fihan pe olujẹjọ Vandi lo ṣekupa Oloogbe Omobolanle Raheem.
"A ri ile ọta ibọn lẹyin ọkọ oloogbe”
Insipẹkitọ Adeyemo fikun pe awọn mu awọn ibọn naa lọ fun ayẹwo, ọkan lara ibọn ọhun lo jẹ ti olujẹjọ, ti ikeji si jẹ ti akẹgbẹ rẹ.
Bakan naa ni Adeyemo sọ fun ileẹjọ pe awọn ni awọn ri ile ọta to ṣekupa Bolanle lẹyin ọkọ ayọkẹlé to oloogbe wa lasiko ti isẹlẹ naa waye.
Elerii keji, Adeyeye Bamisope sọ fun ileẹjọ pe iwadii awọn fihan pe ọta ibọn to jade lati inu ibọn Vandi ni o fọ gilassi ọkọ ayọkẹlẹ naa.
“A ko ri iho kankan lara ọkọ ayọkẹlẹ naa.”
Adajọ Harrison Ibironke ti wa sun igbẹjọ si ọjọ Kẹdogun, oṣu keji.
"A gbe Vandi lọ si ilewosan fun ayẹwo arun ọpọlọ"
Insipẹkitọ Adeyemo sọ fun ileẹjọ pe, lẹyin ti awọn gba asẹ lati bẹrẹ iwadii lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2023, o ni awọn gbe olujẹjọ lọ si ile wosan lati lọ ṣe ayẹwo boya ko ni arun ọpọlọ.
Adeyemo ni awọn gba ibọn ti awọn ọlọpaa ko jade lọjọ Kedọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2022 lati ṣe ayẹwo ati iwadii.
O ni “ mo gba ohun silẹ lọwọ olujẹjọ ati olupẹjọ. Olujẹjọ sọ ninu ohun rẹ pe oun ko jẹbi ẹsun naa rara.
Adeyemo tẹsiwaju pe lẹyin naa ni awọn gba ohun olujẹjọ, ti awọn si ni ṣe iwadi lori ile ọta ibọn ti awọn ri lẹyin ọkọ ayọkẹlẹ ti oloogbe wa.
Bakan naa lo ni awọn se abẹwo si ibi ti isẹlẹ naa ti waye ati ibudo igbokusi ni Yaba, ti wọn gbe oku oloogbe naa lọ fun ayẹwo.
“Nigba ti a n yẹ ọkọ ayọkẹlẹ ti oloogbe ku si wo, a ri ọta ibọn kan lẹyin ọkọ naa.
"Ọta ìbọn 25 ni Vandi gba lọjọ Keresi amọ 23 lo da pada"
Insipẹkitọ Adamu Shuaibu, ẹni to jẹ ẹlẹrii kẹjọ to n farahan nile ẹjọ lori igbẹjọ iku Omobolanle Raheem ati Ọlọpaa ti wọn fẹsun kan pe o lọwọ ninu iku rẹ, Drambi Vandi, sọ fun ileẹjọ pe olujẹjọ naa gba ọta ibọn mẹẹdọgbọn jade lọjọ naa.
Shuaibu, ẹni to n mojuto awọn ohun ija ọlọpaa salaye pe, ninu ọta ibọn mẹẹdọgbọn ti Vandi gba jade, mẹtalelogun lo da pada lẹyin isẹlẹ to waye lọjọ Keresimesi ọdun to kọja.
O ni, ni dede ago mẹjọ kọja isẹju diẹ lowurọ Keresimesi ni Olujẹjọ wa si ọọfisi oun lati wa gba ibọn AK47 pẹlu ami idanimọ NO 24669 ati ọta ibọn mẹẹdọgbọn.
O fikun pe Insipẹkitọ Ibimini naa wa lati wa gba ibọn AK47 pẹlu ọta ibọn mẹjọ.
"Ninu Ọta ibọn Mẹẹdọgbọn ti Vandi gba jade, Mẹtalelogun lo da pada"
Adamu, nigba to n sọrọ ileẹjọ giga ipinlẹ Eko, to n joko ni Tafawa Balewa Square , sọ fun ileẹjọ pe oun gba ipe lati ọdọ Insipẹkitọ Ameh Mathew pe wahala ti sẹlẹ ni agbegbe afara Ajah.
Shuaibu ni kete ni oun fi to Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa Ajah leti pe nnkan ti sẹlẹ ni Afara bridge Ajah, ti Ọga agba naa si gbera lọ si bi isẹlẹ naa.
“Nigba ti a debẹ, a pade Insipẹkitọ Ibimini ati Mathew, ti a si beere ohun to sẹlẹ.
Insipẹkitọ Mathew tẹnu bọ ọrọ fun wa pe olujẹjọ yinbọn lu obinrin alaboyun kan.
“Mo pe ileeṣẹ ọlọpaa pe ki wọn maa ṣe akiyesi.
Ko pẹ si igba naa ni mo gbọ ariwo Ọga wa DPO, Vandi ati Supol Segun nigba ti mo wa ninu ọfisi mi.
“Bi mo ṣe jade kuro ninu ọọfisi mi, mo ri awọn mejeeji, ti Segun si fun mi ni ibọn AK47 ti olujẹjọ gba jade.
Mo pe Insipẹkitọ Ibimini, mo gba tọwọ rẹ pẹlu rẹ, ti mo si ṣe akiyesi pe ọta ibọn olujẹjọ din meji lara mẹdọgbọn to gba jade.
"Vandi ko ri nnkan pato sọ fun mi lori idi ti ọta ibọn meji ṣe din"
“Mo pe ileeṣẹ ọlọpaa pe ki wọn maa ṣe akiyesi, ko pẹ si igba naa ni mo gbọ ariwo Ọga wa DPO, Vandi ati Supol Segun nigba ti mo wa ninu ọfisi mi.
“Bi mo ṣe jade kuro ninu ọfisi mi, mo ri awọn mejeeji, ti Segun si fun mi ni ibọn AK47 ti olujẹjọ gba jade.
Mo pe Insipẹkitọ Ibimini, mo gba ibọn tọwọ rẹ pẹlu ti Vandi, ti mo si ṣe akiyesi pe ọta ibọn olujẹjọ din meji lara mẹẹdọgbọn to gba jade.
“Lẹsẹkẹsẹ ni mo pe olujẹjọ pe bawo ni ọta ibọn meji ṣe din sugbọn ko ri nnkan pato lati sọ fun mi,
Mo sọ DPO, ti o si ni ki n lọ gbe iwe akọsilẹ mi jade lati fi idi rẹ mulẹ pe otitọ nipe ọta ibọn mẹdọgbọn ni olujẹjọ naa gba jade .
Lẹyin gbogbo atotonu awọn agbẹjọro ijọba ati ti olujẹjọ, Adajọ sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ Kẹsan Oṣu Keji.
"Vandi bèèrè ọ̀tá ìbọn mìíràn lọ́wọ́ mi torí ọta ìbọn rẹ̀ kó pé mọ́ lẹ́yìn ikú Bolanle Raheem"
Ọkan lara awọn Ọlọpa to n jẹri nibi igbẹjọ to n sawari iku to pa agbẹjọro kan nilu Eko, Bolanle Raheem, ti jẹri nile ẹjọ, nipa awọn iṣẹlẹ to waye pẹlu rẹ ati afurasi ọlọpa ti wọn fẹsun iku obinrin naa kan, Vandi Drambi.
Ti ẹ ko ba gbagbe, lọjọ ọdun keresimesi to kọja ni wọn yinbọn mọ Raheem Bolanle to loyun sinu, ti wn si fi ẹsun ipaniyan naa kan ọlọpa Drambi Vandi, to ṣiṣẹ ni agọ ọlọpa to wa ni Ajiwe lagbegbe Ajah nipinlẹ Eko.
Insipẹkitọ Sunday Akagu, nigba to n jẹri nile ẹjọ lori igbejọ Vandi salaye pe lẹyin iṣẹlẹ naa, Drambi Vandi beere ọta ibọn lọwọ oun.
O ni Vandi sọ pe oun fẹ fi ọta ibọn to n beere naa sinu ibọn oun nitori awọn ọta ibọn to ṣẹku lọwọ rẹ ti din.
"Vandi kọ lati salaye ohun to sẹlẹ fun mi lẹyin iku Bolanle Raheem"
Sunday, ẹni to ti n ṣe iṣẹ ọlọpa fun ogun ọdun, ni oun kọ jalẹ lati fun Vandi ni ọta to beere naa.
Nigba ti adajọ agba fun ipinlẹ Eko, Moyosore Onigbanjo beere boya o fun Vandi ni ọta ìbọn to beere fun, Sunday ni rara oo, laelae, oun ko fun.
Ninu ijẹri rẹ, Sunday ni oun ati awọn akẹgbẹ oun mẹta lawọn n jọ ṣiṣẹ, ki DPO agọ ọlọpa Ajiwe to pe awọn nipe ojiji.
Lọgan ti awọn de ile iṣẹ ọlọpa Ajiwe, ile iwosan Budo, nibi ti wọn gbe oku Bolanle Raheem si, ni awọn lọ, nibẹ si ni oun ti pade Vandi.
Sunday ni oun beere ohun to ṣẹlẹ ṣugbọn Vandi kọ lati ṣalaye ayafi ti awọn baa de ọfiisi.
O ni DPO Ajiwe lo paṣẹ ki awọn gbe Vandi wa si agọ ọlọpa amọ Sunday ko sọ boya ibọn ṣi wa lọwọ Vandi nigbati wọn mú lo si ilé iṣẹ ọlọpa Ajiwe.
Nigba ti ile ẹjọ beere nọmba ara ibọn ti Vandi gbe lọwọ, Sunday ni oun ko ranti ayafi ti wọn ba yẹ iwe akọsilẹ ile iṣẹ ọlọpa wo.
Insipẹkitọ Olagunju Olatunji ni ẹlẹrii keji nile ẹjọ to tun fara han nile ẹjọ, to si sọ pe oun ni ọlọpaa to n tọpinpin ẹsun naa, ki wọn tilẹ to gbe e lọ siwaju ẹka to n ṣewadii ọtẹlẹmuyẹ, SCID.
O kẹnu bọ ọrọ lẹkunrẹrẹ lori ohun to ṣẹlẹ lẹyin ti wọn gba iroyin pe wọn fẹsun kan ọfisa kan pe o yinbọn pa eeyan ni Ajah.
“Ọta ibọn dawati ninu ibọn rẹ lẹyin iṣẹlẹ naa”
Ọfisa Olatunji sọ fun ile ẹjọ pe “mo wa ninu agọ ọlọpaa ni ọjọ Kẹẹdọgbọn Oṣu Kejila to kọja yẹn ni nnkan bii ago kan ọsan ti arabinrin kan Enema Titilayo sare wọ agọ wa lati fi ẹjọ iṣẹlẹ naa sun.
A ke si igbakeji ọga wa DPO. Ati emi ati DPO atawọn mii lọ si ileewosan ti wọn gbe arabinrin naa lọ.”
Ile iwosan naa dari wọn lọ awọn ileewosan mii kaakiri, ibi ti wọn lọ kẹyin si ni wọn ti kede fun wọn pe Bolanle Raheem ti jẹ Ọlọrun nipe.
O fi kun un pe oun ri afurasi to n jẹjọ lọwọ ni ileewosan naa to n pa gulọ gulọ sapamọ labẹ atẹgun ibẹ.
“A ṣe iwadii iṣẹlẹ naa, afurasi sọ tẹnu rẹ, olupẹjọ naa ṣalaye ọrọ tirẹ a si lọ sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye”, eyi ni alaye rẹ.
Nigbati agbẹjọro ijọba to jẹ agbẹjọro agba ipinlẹ Eko beere pe ki ni iwadii wọn fihan ki wọn to gbe ẹjọ naa kuro ni agọ wọn...
Ohun ti iwadii awọn Ọlọpaa fihan

Olatunji ṣalaye pe “iwadii wa fihan pe olujẹjọ lo yinbọn lootọ eyi to pa arabinrin ọhun”.
Nigba ti wọn bii lere boya o mọ olujẹjọ ṣaaju iṣẹlẹ naa, o dahun pe “mo mọ olujẹjọ gẹgẹ bi ọkan lara ikọ wa, mi o fibẹẹ mọ pupọ nipa rẹ toripe wọn ṣẹṣẹ gbe mi wa si agọ wa ninu Oṣu Kọkanla ni.”
Lasiko ti wọn tun ṣe awọn ayẹwo mii, agbẹjọro olujẹjọ, Adetokunbo Odutola bii leere boya o wa nibẹ lasiko ti iṣẹlẹ yii waye, o dahun pe rara.
Nipa iye ibọn to wa fun iṣẹ lọjọ naa, Olatunji ni ọfisa meji pere lo fi orukọ silẹ lati lo ibọn lọjọ naa, Insipẹkitọ Vandi ati ọfisa mii, “nigba ti iṣẹlẹ naa waye taa si wo ibọn wọn, ọta ibọn meji lo ti din ninu ibọn ọfisa Vandi nigba ti ti ọfisa keji ṣi pe sibẹ”.
O fi kun un pe nigba ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ ti awọn de ileewosa, oun ri Insipẹkitọ Vandi to n sapamọ sabẹ àtẹ̀gùn to si wọ aṣọ ara tẹ pẹlu ibọn lọwọ.
Nigba ti wọn bii pe kilode to ṣe sọ pe ọfisa naa lo pa arabinrin ọhun, o ni nigba to yinbọn ba obinrin naa, ọkọ rẹ sọkalẹ o si lọ di ọlọpaa naa mu titi to fi wọ ọ tẹle wọn lọ si ile iwosan.
Idi mii to sọ ni pe, ọfisa mẹta lo gba ibọn, ọta awọn meji to ku pe amọ ti Vandi nikan lo din meji.
Idi kẹta to sọ ni pe oun rii to n sa pamọ si abẹ àtẹ̀gùn ileewosan ti awọn ti lọ wo arabinrin naa.
Agbẹjọro olujẹjọ wa bii pe, ṣe yoo yaa lẹnu ti ọkọ ati aburo oloogbe naa ba ko ba sọ pe awọn rii ti olujẹjọ yinbọn, o ni bẹẹ ni yoo ya oun lẹnu.
Bakan naa ni Ọlọpaa mii jẹri nipa bi olujẹjọ ṣe n gbọn jinijini ti o n fi ibẹru ba awọn sọrọ lọjọ naa.
Adajọ ti sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ Kẹjọ Oṣu Keji.
















