Ọlọ́pàá ń wá 'Ọba Ogboni' l'Eko!

Aworan Oba ogboni ati ibon ti wọn ka mọ ile rẹ

Oríṣun àwòrán, Lagos Police

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko n wa ọba Tajudeen Ọlanrewaju Bakare ti awọn kan n pe ni Ọba Ogboni Abalaiye lori ẹsun dida omi alaafia ilu ru.

Ileeṣẹ ọlọpaa kede pe awọn n wa arakunrin naa lẹyin iwadi ti wọn ṣe lori fidio kan to gba ayelujara kan lọsẹ to kọja ninu eyi ti wọn ti ri arakunrin naa to n gbe ibọn atamatase ‘pump action’ kiri eyi to fa ibẹrubojo laarin araalu.

“Ikọ RRS labẹ akoso CSP Ẹgbẹyẹmi ya bo ile arakunrin naa ti wọn si tu ile rẹ naa lagbegbe Surulere nibi ti wọn ti ri ibọn ‘pump action’ mẹta ati apo ọta ibọn ilewọ Beretta, atawọn ọta ibọn ati aworan afurasi naa kan.”

Atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko fi sita loju opo Twitter rẹ ṣalaye pe afurasi naa, Tajudeen Ọlanrewaju Bakare yọ bọrọ mọ awọn agbofinro lọwọ nigba ti wọn lọ fi ṣinkun ofin mu u.

Awọn ọlọpaa wa rọ awọn araalu lati mu iroyin ti yoo mu kọwọ tẹ afurasi naa tọ ọlọpaa wa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ṣe igba akọkọ niyi ti Ọba Ogboni yoo maa wọ inu iwe ati awọn ọlọpaa l’Eko?

Igba akọkọ kọ niyi ti ‘Ọba Ogboni’ Tajudeen Bakare yoo maa wọ inu ṣokoto kan naa pẹlu awọn ọlọpaa nipinlẹ Eko.

Tajudeen Bakare wa lara awọn afurasi ti ileeṣẹ ọlọpaa ko nibi iwọde Yoruba Nation to waye lagbegbe Ọjọta nilu Eko lọjọ kẹta oṣu keje ọdun 2021 ti wọn si ko wọn lọ si ile ẹjọ Majisireeti kan ni Yaba.

Ẹsun dida igboro ru ni wọn fi kan awọn yooku, ṣugbọn ẹsun ipaniyan ni wọn fi kan Ọba Ogboni Tajudeen Bakare lori iku ọmọdebinrin kan Jumọkẹ Oyekele ti ọta ibọn ba lasiko iwọde naa.