Ìgbẹ́jọ́ ti parí, ìdájọ́ ló kù báyìí lórí ẹjọ́ ikú Adegoke tí wọ́n fi kan Rahamon Adedoyin l'Osun

Aworan Adegoke pẹlu Adedoyin

Oríṣun àwòrán, other

Onidajọ Agba Adepele Ojo to n ṣe ẹjọ ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan Dokita Rahmon Adedoyin atawọn oṣiṣẹ ile-itura rẹ mẹfa, ti kede pe igbẹjọ ti pari lori ọrọ naa.

Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ ni wọn n jẹjọ lori iku to pa akẹkọọ fasiti Ifẹ kan, Timothy Adegoke, sinu otẹẹli Hilton to wa niluu Ile-ifẹ ninu oṣu kọkanla ọdun 2021.

Ki lo ṣẹlẹ nibi igbẹjọ tẹlẹ?

Nigba naa ni Falana fi ẹsun ipaniyan kun ẹsun ti wọn fi kan Dokita Adedoyin, ti agbẹjọro rẹ, Barisita Kehinde Ẹlẹja, SAN, sọ fun ile ẹjọ pe yoo pe awọn ẹlẹri meji.

Lẹyin ti wọn kọkọ pari igbẹjọ lọdun to kọja ni agbẹjọro ti awọn mọlẹbi Adegoke gba, Fẹmi Falana, SAN rọ ile ẹjọ pe awọn fẹẹ fi kun awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn olujẹjọ.

Adedoyin kuna lati mu ẹlẹri meji wa siwaju ile ẹjọ

Amofin Falana SAN atawọn agbejoro miran nile ẹjọ lasiko ọkan lara awọn igbẹjọ ẹjọ naa

Latari pe wọn ko ri ẹlẹri ti Adedoyin fẹẹ pe mu wa si kootu nijoko igbẹjọ to kọja ni wọn sun igbẹjọ naa siwaju di oni ọjọ keji oṣu keji ọdun 2023.

Ṣugbọn ni kootu ni agbẹjọro Adedoyin tun ti sọ pe gbogbo igbiyanju awọn lati gbe awọn ẹlẹri mejeeji to ni wa si kootu lo ja si pabo.

Ẹlẹja ṣalaye pe awọn gbiyanju lati gbe Dokita Benedict Agpo ti Nigeria Police Forensic Science Laboratory lati Force CID Annex, Alagbon, nipinlẹ Eko ati Inspẹkitọ Victor Ekpenyong wa, ṣugbọn wọn ko ṣe e ṣe.

Awọn agbofinro ko awọn afurasi lori ẹjọ naa wa sile ẹjọ

O ni wakati mẹrinlelogun sẹyin ni Ekpenyong ṣẹṣẹ sọ pe oun ni iṣẹ nita. Nitori naa, o ni pẹlu bi awọn ko ṣe lanfaani lati gbr awọn ẹlẹri naa wa, ki kootu pari igbẹjọ olujẹjọ akọkọ to jẹ Adedoyin.

Bakan naa ni awọn agbẹjọro ti awọn olujẹjọ yooku sọ pe awọn naa faramọ ọn ki igbẹjọ pari.

Nitori naa, Onidajọ Agba Adepele Ojo kede ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹta ọdun yii gẹgẹ bii ọjọ ti awọn agbẹjọro fun gbogbo awọn olujẹjọ yoo mu akọsilẹ awijare wọn wa.