Àwọn ọlọ́pàá 612 gba ẹ̀kọ́ síi láti gbóguntí ìjínigbé, rògbòdìyàn lásìkò ìdìbò tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, NPF
Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ni awọn ti fun awọn ọlọpaa to le ni ẹgbẹta ni eto ẹkọ saaju isibo gbogboogbo ti yoo waye ni ọdun 2023.
Awọn ọlọpaa naa ni yoo koju igbesunmọmi, ijinigbe ati iwa ipa lasiko idibo ti yoo waye naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Muyiwa Adejọbi ni gbogbo ẹkun mẹfẹẹfa to wa ni Naijiria ni wọn ti mu awọn ti wọn gba eto ẹkọ naa.
Adejobi ni eto ẹkọ naa waye laarin Ọjọ Keje, Osu Kini ọdun 2023 si Ọjọ kejidinlogun, Osu Kini, ọdun 2023.
Adejọbi ni awọn iwa ipa to ti ma n waye kaakiri orilẹede Naijiria bi ijinigbe, igbesunmọmi ati awọn ẹlẹgbẹ okunkun to fi mọ rogbodiyan lasiko eto idibo lo mu ijọba gbe eto naa kalẹ.
O ni Ọga agba ọlọpaa, Usman Alkali Baba sọ pe idibo to n bọ yii ko ni ni idiwọ ati idena ninu nitori eto aabo yoo wa ni pese
O rọ awọn ti wọn gba eto ẹkọ naa lati lo o bi o ti to ati bi o ti yẹ ki opin de ba eto aabo to dẹnukọlẹ ni Naijiria.
Bakan naa ni ọga ọlọpaa naa sọ fun awọn ti wọn gba eto ẹkọ naa lati ri pe wọn lo ni ẹka agọ ọlọpaa wọn fun idagbasoke ẹkun wọn.
Awọn ikọlu to ti waye nipaṣẹ eto idibo ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, NPF
Ikọlu lasiko eto idibo wọpọ lorilẹede Naijiria, eleyii to ma n fa ifoya lasiko idibo fun awọn araalu.
Ohun to ma n fa wahala lasiko idibo ni bi awọn olosẹlu ṣe ma n lo awọn onijagidijagan lati ba eto idibo jẹ.
Nitori naa ni wọn ṣe ma n fun awọn ọlọpaa ni eto ẹkọ lasiko ti idibo ba ti fẹ sun mọ eti ile.
Ni Oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 ni awọn onijagidijagan sẹkọlu si oludije sipo gomina lẹgbẹ osẹlu PDP, Abdul-Azeez Adediran ni agbegbe Ikoja ni Badagry.
Awọn ẹgbẹ oṣelu PDP da ẹbi iṣẹlẹ naa ru APC , ti wọn si ni awọn to ṣekọlu si wọn n pariwo APC.
Amọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ko si ohun to jọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, NPF
Bakan naa ni awọn onijagijagan kan ṣekọlu si ọkọ oludije sipo aarẹ lẹgbẹ osélu APC ni ilu Eko.
Ni ipinlẹ Oṣu, oludije sipo gomina ni ẹgbẹ oṣelu Labour, Rabiu Ismaila fẹsun kan awọn ẹgbẹ alatako pe wọn ṣekọlu so ohun ni Osu Kọkanla, ọdun 2022.
Ni Ọjọ Kẹta, OṢU Keje, ọdun 2022 ni awọn kan sọ ina si ileeṣẹ ajọ eleto idibo INEC ni agbegbe Igboeze, ni ipinlẹ Enugu.
Bakan naa ni wọn ti fi iroyin lede nipa ikọlu ni agbegbe Zamfara, Rivers, Kaduna, Ebonyi, Kastina ati awọn ibomiran.
Gẹgẹ bi atẹjade ti kọmiṣọnna ajọ INEC fi lede, Festus Okoye ni agbara awọn awọn agbebọn naa ju ti ẹṣọ alaabo awọn lọ ni wọn ṣe jo gbogbo ileeṣẹ naa palẹ.












