Ètò ìdìbò ọdún 2023, INEC ẹgbẹ́ awakọ̀ fọwọ́sí ìwé àdéhùn

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ajọ eleto idibo orilẹ-ede Naijiria (INEC) ti fọwọsi iwe adehun pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ oni moto irinna, (NURTW) ati ẹgbẹ (NARTO), ati Ẹgbẹ Oṣiṣẹ ori omi (MWUN) fun imunadoko irinajo awọn ohun elo idibo fun eto idibo 2023.

Nigba ti o nsoro ni ilu Abuja ni ọjọ iṣegun, Alaga INEC Mahmood Yakubu ṣe akiyesi pe INEC yoo nilo o kere ju awọn ọkọ ayọkẹlẹ ọkẹ marun ninu eto idibo ọdun 2023,

awọn ọkọ oju omi egberun mẹrin fun gbigbe awọn oṣiṣẹ ati awọn ohun elo ni awọn idibo gbogbogbo ti o n bọ.

Adehun naa ni o waye,oṣu kan leyin ti igbimọ naa ṣepade pẹlu awọn ọga to mojuto eto aabo ati awọn olori awọn ẹgbẹ irinna ni ilu Eko.

Alaga INEC, awọn olori awọn lẹgbẹlẹgbẹ ati awọn aṣaaju ẹgbẹ to risi irina lo wa ni ibi ipade naa ni Abuja.

Yakubu ro awọn ọmọ ẹgbẹ oni mato lati mase ṣegbe lẹyin oloṣelu kankan,lẹhinna ni ajọ INEC ati awọn ẹgbẹ to riri irinajo towobo iwe adehun.

Ètò ìdìbò ọdún 2023,INEC ẹgbẹ awako fọwọsi iwe adehun.