Doyin Okupe kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi adarí ikọ̀ ìpolongo Peter Obi lẹ́yìn ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún méjì rẹ̀

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC
Ọmọwe Doyin Okupe ti kọwe fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bii adari ikọ ipolongo ibo oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi.
Ninu lẹta kan to fi lede lọjọ Iṣẹgun, Okupe sọ pe ko ni bojumu ki oun ṣe akoba fun ipolongo oludije naa ati ẹgbẹ oṣelu Labour lapapọ, eredi ree ti oun sẹ gbọdọ fi ipo naa silẹ.
Lẹta naa ni “Perter mi ọwọn, ranti pe mo ti ṣalaye fun ọ nipa ohun ti mo n la kọja lati ri idajọ ododo gba ati lati fọ orukọ mi mọ lọna to ba ofin mu.”
“Ọpọ akitiyan ni mo ti ṣe lori ipolongo rẹ amọ mi o ni jẹ ki ohun ti mo n la kọja ṣakoba fun ipolongo rẹ.”
“Nibi ti ọrọ de duro bayii, mo ti pinnu lati yẹba, mo si rọ ọ pe ki o yan ẹlomiran gẹgẹ bii adari ikọ ipolongo rẹ ki ẹni naa le maa ba iṣẹ lọ.”
“ Ki Ọlọrun bukun iwọ ati awọn mọlẹbi rẹ.”
Okupe gba idajọ ẹwọn ọdun meji ṣaaju
Ikọwefiposilẹ Okupe yii lo n waye lẹyin idajọ ile ẹjọ giga kan l’Abuja, eyii to dajọ pe o jẹbi ẹsun gbigba owo ti iye rẹ ro igba miliọnu naira lọwọ Sambo Dasuki, to jẹ olubadamọran si Aarẹ ana lori eto abo.
Ninu idajọ naa ni adajọ Ijeoma Ojukwu ti ni ki Okupe lọ fi ẹwọn ọdun meji jura tabi ko san owo itanra.
Amọ ninu atẹjade kan loju opo Twitter rẹ, Okupe ni iṣẹ ọwọ awọn ọta oun ni ilakọja naa jẹ.
Ki lo ti sẹlẹ sẹyin?
Ilé ẹjọ́ rán Okupe lọ ẹ̀wọ̀n ọdún méjì lórí ẹ̀sùn owó N200 milìọ̀nù

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ile ẹjọ kan ni ilu Abuja ti sọ pe oludari agba ikọ ipolongo fun Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Ọmọwe Doyin Okupe jẹbi ẹsun gbigba iye owo igba miliọnu naira lọwọ olugbaninimọran agba ijọba lori eto abo, Col. Sambo Dasuki ti wọn si ti ran an lọ si ẹwọn ọdun meji.
Nigba ti adajọ Ijeoma Ojukwu n ṣe idajọ naa, o jẹ ko di mimọ pe iwa ti Okupe yii ti ajọ to n gbogunti iwa jẹgudujẹra fi wọ wa si ile ẹjọ, fihan pe Okupe ru ofin to lodi si jiji owo ilu ko.
Tori naa, o jẹbi ẹsun abala ofin ikẹrinlelọgbọn titi de ikọkandinlọgọta ẹsun ti wọn fi kan an.
Okupe to jẹ oludari agba ikọ ipolongo fun idibo yan Peter Obi ti gba idajọ pe ko lọ si ẹwọn ọdun meji lori ẹsun to ni ṣe pẹlu abala ikẹrinlelọgbọn tabi ki o san faani ẹgbẹ lọna ẹẹdẹgbẹta naira.
Bakan naa ni ile ẹjọ tun paṣẹ pe ko ṣe ẹwọn ọdun meji lori ẹsun to ni ṣe pẹlu abala ikarunlelọgbọn titi de ikọkandinlọgọrin tabi ko san faani ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta.
Anfani lati san faani mejeeji naa ni wọn fun un pe o lee san an tẹle ara wọn. Ẹwẹ, ni ti iye ọdun ti wọn ran an lọ ẹwọn, wọn fun un ni anfani pe o lee ṣe mejeeji papọ.
Bakan naa ẹwẹ ni wọn ni o gbudọ bẹrẹ gbigba gbogbo idajọ naa ni ọjọ ti ẹjọ jade ti wọn si ni Okupe ti di ẹtọ ijọba bayii. Wọn wa fun un di ago mẹrin abọ oni ti idajọ jade ki wọn to gbe e lọ si ọgba ẹwọn.















