Àjọ NDLEA ṣàwárí egbògi olóró nínú 'Indomie' ní pápákọ̀ òfurufú Eko

Aworan ogun oloro ninu Indomie

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Okere tan miliọnu kan le ni ẹgbẹrun meji egbogi oloro ni ajọ to n gbogun ti ogun oloro sawari ninu pali ‘Indomie’ ati awọn ẹru miiran ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed niluu Eko ati ipinlẹ Gombe.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ajọ naa, Femi Babafemi fi lede, o ni pe ẹgbẹrun mẹfa egbogi oloro Tramadol ati awọn miiran ni wọn ko wa lati Karachi lorilẹede Pakistan ni awọn ọmọ ologun sawari ẹ lọjọ Aje, ọjọ kejila, oṣu kejila ọdun 2022.

Bakan naa ni egbogi oloro Ropypnol ti wọn tun sawari ninu pali ninu apo ‘Indomie’, eyi ti wọn fẹ fi ransẹ lọ si Johannesburg lorilẹede South Africa.

Ajọ naa tun kede aṣeyori mii ni awọn ipinlẹ wọnyi

Babafemi ni ọwọ ti tẹ osisẹ ileeṣẹ Freight kan, Olaleye Adeola fun ẹsun wi pe o mọ mi pa bi pali ‘Indomie’ ṣe n lọ si orilẹede South Africa.

Bakan naa ni ajọ NDLEA kede ọwọ tẹ afurasi kan ni ọja Balogun niluu Eko nigba to gbinyanju lati gbe ogun oloro lorilẹede UAE. 

Akunne Chibuzor ni ọwọ tẹ lọjọ isẹgun pẹlu ajọsepọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa.

Tí ọwọ si tẹ awọn afurasi yooku ni Ipinlẹ Oyo, Kano, ati Delta.