Buhari já wa kulẹ̀, Ó gbàgbé àdéhùn lẹ́yìn ètò ìdìbò 2019- Miyetti Allah

Aworan adari ẹgbẹ Miyetti Allah

Oríṣun àwòrán, others

Aarẹ ati adari ẹgbẹ Miyetti Allah lorilẹede Naijiria, Baba Othman Ngelzatma ti fi fẹsun kan Aarẹ Muhammadu Buhari pe o ja awọn kulẹ lẹyin ti awọn ṣe atilẹyin ita gbangba fun un ni saa keji lọdun 2019.

Ngelzarma ni Aarẹ Buhari gbagbe awọn lẹyin to wọle saa keji, ti ko si mu gbogbo ileri to ṣe wa si imusẹ.

O sọ eleyi nigba to ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja, o ni aarẹ ko kọ ibi ara si idagbasoke nnkan ọsin, ti ijọba si kuna lati pese owo fun awọn agbẹ to sin nnkan ọsin.

O ni pe: “Eto idibo ọdun 2019, a buwọlu Buhari. a fi han gbogbo agbaye pe a wa lẹyin Buhari sugbọn lẹyin o rẹyin, a ko gbọ ohunkohun lati ọdọ aarẹ mọ́, ti wọn ko si ṣe nkankan fun idagbasoke ohun ọsin.

“ Buhari ja wa kulẹ, o ti han gbangba pe iṣejọba yii ko nifẹ si ohun ọsin rara, nitori bawo ni wọn yoo ṣe gbe owo to to ọgọrun marun un milọnu kalẹ, ti wọn ko si ri pe awọn agbẹ ohun ọsin ko ri nkankan gbe nibẹ fun idagbesoke.

“Ẹ lọ wo bii wọn ṣe pin owo ọhun, ẹ ri pe awọn ko fi nkankan silẹ fun ẹka ohun ọsin. O ya wa lẹnu.

Ngelzarma ni ọpọ igba ni awọn agbebọn ṣekọlu si awọn ohun ọsin wa nitori pe kaakiri orilẹede ni awọn ti gba iroyin lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn.

Yatọ si pe wọn ṣekọlu si awọn eranko wa, pupọ ninu awọn eeyan wa ni wọn koju ijinigbe lọwọ awọn ajinigbe, a nilo iranlọwọ aabo lọwọ ijọba apapọ.