Messi fi ìtàn lélẹ̀, Ife ẹ̀yẹ àgbáyé di ti Argentina lẹ́yìn ọdún 36

Lionel Messi

Oríṣun àwòrán, Others

Orílẹ̀ èdè Argentina ti borí ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ọdún 2022 èyí tó wáyé ní orílẹ̀ èdè Qatar.

Orílẹ̀ èdè France ni Argentina lù láti fi gba ife ẹ̀yẹ náà.

Aago mẹ́rin ìrọ́lẹ́ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kejìlá ní àṣekágbá ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé tó bẹ̀rẹ̀ ní ogúnjọ́, oṣù Kọkànlá wáyé ní pápá ìṣéré Lusail ní orílẹ̀ èdè Qatar.

Góòlù mẹ́ta mẹ́ta ni France àti Argentina fi parí ìfẹsẹ̀wọ́nsẹ̀ náà kí wọ́n tó gbá pẹnáritì.

Messi ló jẹ góòlù méjì fún Argentina tí Angel Di Maria sì fi ẹyọ̀kan le.

Kylian Mbappe ló jẹ góòlù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fún orílẹ̀ èdè France.

Nígbà tí ìdíje náà parí sí ọ̀mì ni wọ́n gbá pẹnáritì àmọ́ France pàdánù sọ́wọ́ Argentina.

Góòlù mẹ́rin sí méjì ni Argentina fi fàgbà han France láti fi gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé.

Orílẹ̀ France ló gba ipò kejì nígbà tí Croatia gba ipò Kẹta lẹ́yìn tí wọ́n ná Morocco ní ọjọ́ Àbámẹ́ta.