Ò hàn gbangba pé Ìyàwó Atiku ṣí ọ̀rọ̀ sọ ní nígbà tó ní kí àwọn aráàlú dìbò fún APC- Keyamo

Oríṣun àwòrán, others
Minisita abẹle fun ọrọ osiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Festus Keyamo ni ọrọ ti iyawo igbakeji aarẹ nigba kan ri ati oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Titi Atiku Abubakar sọ pe ki awọn eeyan dibo fun ẹgbẹ oṣelu APC lọdun to n bọ ni o jẹ asisọ ọrọ.
Keyamo to tun jẹ agbenuso APC, lori opo ayelujara rẹ ni iyawo igbakeji aarẹ si ọrọ naa sọ ni.
Laipẹ yii ni Titi Abubakat, nigba to ba awọn obinrin, o rọ wọn lati kaadi idibo wọn, ki wọn si dibo fun ẹgbẹ oṣelu APC.
O ni, “Ẹ lọ gba kaadi idibo yin, kẹ dibo fun APC lọjọ kẹdọgbọn oṣu keji ọdun to n bọ.”
Nigba to n sọrọ lori rẹ, Keyamo ni pe ko bojumu pe ki awọn bẹrẹ si ma gbe ọrọ naa kiri
“Pẹlu gbogbo otitọ ọkan, asisọ ọrọ ni sugbọn a ko ro pe o bujumu lati bẹrẹ si ni maa gbe ọrọ kiri paapa nigba ti ẹni ọhun ti ṣe atunṣe si ọrọ rẹ.
“Ẹgbẹ LP ni nkankan naa ẹgbẹ APC ati PDP lẹyin ti Atiku kuro lati APC lọ PDP
“Ẹgbẹ APC ni nkankan naa ni ẹgbẹ LP ati PDP lẹyin ti Peter Obi kuro lati PDP lọ LP.
“Orukọ Tinubu ko si ninu gbogbo ẹsun wọn.
Ẹgbẹ oṣelu PDP ko ni nkan lati sọ nitori aarun jẹjẹrẹ ni wọn, ti awọn eeyan si n sa fun wọn.”















