Wó ìdí tí àwọn obìnrin tó ṣí ní ìbálé ṣé ń sọ ará wọn di ọkùnrin ní ìlú yìí

Fun ọpọlọpọ awọn obinrin ni aye igba naa, piparọ awọn ẹya ara ibalopọ wọn nikan lo le fun wọn ni anfani lati ni ọla ati iyi ti awọn ọkunrin ni.
Ni bayi, awọn mejila nikan lo ku lara awọn obinrin ti wọn gbe igbe aye obinrin amọ ti wọn pada sọ ara wọn di gende ọkunrin.
Gẹgẹ bi Giystina Grishai ṣe sọ, “Orilẹede Albana jẹ orilẹede ọkunrin, ọna kan lati wa laye si ni koo di ọkunrin.”
Gẹgẹ bii ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹtalelogun to n gbe ori oke apata ni ariwa Albania nigba naa, o ni oun pinnu lati mu iyipada ba igbesi aye oun.
Tani Gjystina Grishaj to ṣo ara rẹ di ọkunrin?
Awọn mọlẹbi Gjystina Grishaj ti n gbe ni Malësi e Madhe ni ẹkun ijọba Lëpushë fun aimọye ọdun.
Agbegbe yii jẹ ọkan lara awọn agbegbe ti aṣa ‘Burrnesha’ ti jẹ wọn logun, eyi ni o fun awọn obinrin ni anfani lati di ọkunrin lẹyin ti wọn ba ti bura fun awọn agbagba ilu naa.
Awọn obinrin naa ni wọn n pe ni ‘Sworn Virgins’, eyi to tumọ si awọn obinrin to bura pe awọn ko ni mọ ọkunrin, ti wọn si ama gbe igbeaye ọkunrin.
“Ọpọlọpọ awọn ọbinrin lo kuna lati ṣe igbeyawo ṣugbọn wọn ko ki n ṣe ara wa gẹgẹ bii ẹni ti ko tii mọ ọkunrin rara.
“Burrnesha ni Obinrin to ti pinnu gbe igbeaye rẹ fun awọn mọlẹbi lati ṣe isẹ , ti yoo si pa ara rẹ fun ibalopọ pẹlu ọkunrin.
Gjystina, ẹni ọdun mẹtadinlọgọta yii ba ileeṣe BBC News sọrọ.
Mo gba lati di ọkunrin nitori mo fẹ tọju mọlẹbi lẹyin iku Baba mi
O ni ti obinrin ba ti gba lati di ọkunrin, o ni anfani lati mura bii ọkunrin, jẹ olori ile bi ọkunrin, ma gbafẹ bi ọkunrin, ti yoo si ni anfani lati ṣe isẹ ti ọkunrin n ṣe.
Gjystina tẹsiwaju pe pupọ awọn to sumọ mọ wipe oun fẹ dawa, ti oun o si fẹ jẹ iyawo fun ọkunrin kankan.
“Kete ti baba mi jade laye ni mo pinuu pe mo fẹ di ọkunrin lati di olori mọlẹbi, ti ma si ni anfani pese fun awọn mọlẹbi mi.
“Ko si owo kankan. Baba mi ku, iya mi bimọ mẹfa, mo nilo lati gbe igbesẹ naa lati mu nnkan rọnu fun iya mi.”
Ati pe mo ri ara mi gẹgẹ bii Ọkunrin
Gjystina ni ẹnikẹni ko fi tipa mu oun lati di ọkunrin, o ni fun ara oun ni oun nifẹ lati di Okunrin, ti oun si yan igbesi aye naa layo.
O ni igbesi aye ọkunrin ni ọpọlọpọ omira, ti oun si le ṣe ohunkohun to ba wu oun lati ṣe.
“Asiko kan wa ti wọn ko le gbe obinrin si ẹgbẹ ọkunrin, awọn obinrin o ni anfani yẹn lẹyin ki wọn da wa ni ibi kan, ti wọn yoo ti ma ṣe isẹ ile, ti wọn ko si ni anfani lati sọ ni awujọ awọn ọkunrin.”
O ni iya oun koro oju si igbesẹ oun nitori o ti sọ anfani lati ni mọlẹbi tiẹ nu, ati pe ko le di iya ọmọ mọ.
Sugbọn Giystina ni oun figba kan sọ pe oun jẹbi lori igbesẹ oun nitori nnkan ti oun fẹ ni.
“Nigba ti mo di Burrnesha, mo bẹrẹ si ni maa ri aponle.”
“N ko kii ba awọn obinrin rin papọ. Emi ati awọn ọkunrin ni a jọ maa muti, fa siga nile ọti.”
Inu mi dun pe Asa yii ti n tẹnu bọ omi - Valeriana Grishai

“Loni, gbogbo awọn eeyan ko fẹ di okunrin mọ.”, eyi ni ọrọ Valeriana Grishai
“Gbogbo ọdọ ọmọbinrin asiko yii ko nifẹ lati tọju ibale wọn nitori wọn fẹ di ọkunrin. Emi fun apẹẹrẹ.”
Valerianan Grishai ni o dara pupọ bii asa ọhun ṣe ti n tẹnu bọ omi bayi nitori o n ṣe akoba pupọ.
“Nigba kan, mo ranti ti mo kere, ọrẹ mi lọ si ile ọkọ, o sọ fun mi pe ọkọ oun ko ni jẹ ki oun lọ si ile ẹkọ ati pe o gbọdọ gbọ ọrọ si ọkọ rẹ lẹnu ko duro."
















