Obìnrin kan rí ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà fẹ́sùn wí pé ó fẹnukonu pẹ̀lú ọkùnrin

Oríṣun àwòrán, Others
Bí a ṣe ń ṣe nílé wa èèwọ̀ ibòmíràn ni.
Arábìnrin kan ní orílẹ̀ èdè Sudan yóò fi ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà gbára fẹ́sùn wí pé ó fẹnukonu pẹ̀lú ọkùnrin kan.
Obìnrin náà, ẹni ogún ọdún nígbà tó jẹ́wọ́ fún ilé ẹjọ́ wí pé òun fẹnukonu pẹ̀lú ọkùnrin ọ̀hún ni ilé ẹjọ́ náà kọ́kọ́ dájọ́ pé kí wọ́n lọ sọ ọ́ ní òkò pa.
Ṣùgbọ́n nígbà tí ìdájọ́ náà hànde, gbogbo ayé ló bu ẹnu àtẹ́ lu ìdájọ́ náà èyí ló sì fà ìyípadà tí ilé ẹjọ́ mú bá ìdájọ́ náà.
Àjọ tó ń rí sí ìdájọ́ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ àláfíà (ACJPS) júwe ìdájọ́ ikú náà bí èyí tó lòdì sí òfin àgbáyé.
ACJPS ní ilé ẹjọ́ kò gbà obìnrin ọ̀hún láyè láti gba agbẹjọ́rò tí yóò bá ro ẹjọ́ kí wọn tó gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé kí wọ́n lọ pá.
Ilé ẹjọ́ ní Kosti ní ìpínlẹ̀ White Nile, orílẹ̀èdè Sudan ní obìnrin ọ̀hún jẹ̀bi ìwà àgbèrè tí adájọ́ sì ní kí wọ́n lọ sọ ọ́ ní òkò títí ẹ̀mí fi maa bọ́ lára rẹ̀.
Àmọ́ nígbà tí gbogbo àgbáyé bẹ̀rẹ̀ sí ní bu ẹnu àtẹ́ lu ìdájọ́ ọ̀hún ni ilé ẹjọ́ náà tún ẹjọ́ náà gbé yẹ̀wò tí wọ́n sì ní obìnrin náà kò jẹ̀bi àgbèrè.
Nítorí náà ni wọ́n ṣe yí ìdájọ́ padà pé kí wọ́n lọ paá sí pé kó lọ lo oṣù mẹ́fà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Agbẹjọ́rò obìnrin náà, Intisar Abdullahi tó bá BBC sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé fúnra obìnrin ọhún ló fi ẹnu rẹ̀ jẹ́wọ́ nílé ẹjọ́ wí pé òun àti ọkùnrin náà fẹnu ko ara àwọn lẹ́nu.
Abdullahi ní obìnrin ọ̀hún tó ti wà nílé tẹ́lẹ̀ ti lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n láti bẹ̀rẹ̀ ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà tí ilé ẹjọ́ fún-un.
Orílẹ̀ èdè Sudan títí di àsìkò yìí ṣì ń lo ìdájọ́ ikú fún àwọn ẹ̀sùn olè jíjà àti àgbèrè.
Lábẹ́ òfin Sudan àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bíi olè jíjà àti àgbèrè ló ní ìdájọ́ gígé ọwọ́, nína ẹni náà lẹ́gba, sísọ ènìyàn lókò pa àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àmọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìdájọ́ yìí ni ilé ẹjọ́ gíga máa ń yí padà.
Ìjọba ológun ló ti ń ṣe ìjọba Sudan láti ọdún 2021 lẹ́yìn tí ìdìtẹ̀gbàjọba wáyé níbẹ̀.















