Àwọn nọ́ọ̀sì ní UK gùn lé ìyanṣẹ́lódì, pè fún ẹ̀kúnwó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn nọọsi ni orilẹede Gẹẹsi paapa julọ awọn ti ilu England, Wales àti Northern Ireland ni wọn ti bẹrẹ iyanṣẹlodi.
Iyanṣẹlodi yii ni yoo jẹ eyi ti o gbooro julọ ninu itan ẹka to n ri si eto ilera lorilẹede naa.
Pẹlu iyanṣẹlodi ti awọn oṣiṣẹ ilera gun le, ọpọlọpọ iṣe abẹ ati awọn itọju to rọ mọ ọ ni ko ni ṣeeṣe, ṣugbọn awọn itọju to ro mọ didoola ẹmi ni wọn yoo maa ṣe.
Awọn oṣiṣẹ Royal College ninu ọrọ wọn sọ wipe awọn ni lati gun le iyanṣẹlodi nitori wipe ijọba kuna lati ba awọn oṣiṣẹ ilera sọrọ.
Ijọba ilẹ Gẹẹsi lo ti sọ wi pe oun ko lagbara ekunwo ida Mọkandinlogun ti awọn oṣiṣẹ eto ilera beere fun.
Adari RCN Pat Cullen rọ ijọba lati ṣe ohun to tọ ki wọn si fi opin si iyanṣẹlodi yii ki ọdun 2022 to dopin.
Iyanṣẹlodi naa lo tan yika awọn ile iwosan ni ilẹ Gẹẹsi, awọn ile iwosan ni Northern Ireland, gbogbo ile iwosan ni Wales ayafi ile iwosan kan, ṣugbon awọn ile iwosan ni Scotland kii yanselodi.
Iyanṣẹlodi oni wakati mejila ti wọn gun le yii wa ni ninu ofin to rọmọ iṣẹ ni ile Gẹẹsi.
Awọn itọju to jọ mọ ọmọ bibi, aisan jẹdọjẹdọ, itọju ọmọde àti awọn itọju to rọmọ idoola ẹmi nikan ni wọn yoo maa mojuto ni awọn ilẹ iwosan naa.
Arabinrin lyndsay Thompson ẹniti o ti bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bii nọọsi lati ọdun mejila ṣẹyin ni ko wù awọn lati gun le iyanṣẹlodi ṣugbọn aibikita ijọba si ipenija awọn lo jẹ ki awọn gun le iyanṣẹlodi naa.
Iyanṣẹlodi ọhun lo ṣeeṣe ko tẹsiwaju ni ogunjọ oṣu yii ti ijọba ilẹ Gẹẹsi ba kọ lati dahun ibeere awọn nọọsi yii.















