Adedoyin ló ní kí ń sọ fún ọlọ́pàá pé Timothy Adegoke kò sun sílé ìtura Hilton - Ẹlẹ́rìí

Adegoke ati Adedoyin

Oríṣun àwòrán, Collage

Igbẹjọ tun tẹsiwaju lọjọ Ẹti nile ẹjọ giga ipinlẹ Osun, to wa nilu Osogbo lati tanna wadi iku to pa Timothy Adegoke.

Lasiko igbẹjọ naa si ni ikọ olujẹjọ ti ko awọn afurasi jade lati wa sọ tẹnu wọn lori ohun ti wọn mọ nipa isẹlẹ ọhun.

Nibi igbẹjọ naa si ni afurasi kan to jẹ oṣiṣẹ ile itura naa, arabinrin Adedeji Adesola ti tu kẹkẹ ọrọ silẹ nipa ohun to mọ lori iku Timothy Adegoke.

Adesola ni oludasilẹ ile itura naa, Ọmọọba Rahmon Adedoyin lo sọ fun oun nipa idahun ti oun yoo fun awọn ọlọpaa to wa se iwadii Timothy to di awati.

Obinrin naa, tii se osisẹ nile itura Hilton Hotels nilu Ile Ife, to jẹ ti Adedoyin fikun pe oludasilẹ ile itura naa lo sọ fun oun pe ki oun sọ fawọn ọlọpaa pe Timothy Adegoke ko wa si ile itura naa lọjọ to de si ibẹ.

Nigba to n dahun si ibeere lọwọ awọn agbẹjọro, Adesola sọ fun adajọ pe Rahmon Adedoyin ati ọmọ rẹ Roheem, lo kọ oun ni ọrọ ti oun yoo sọ naa.

O ni awọn mejeeji lo pe oun wa si ilegbe wọn, ti wọn si sọ pe ki oun sọ fun awọn ọlọpaa pe Timothy Adegoke ko de si ile itura naa rara ati rara.

Osisẹ-binrin naa ni Roheem Adedoyin tun fun oun ni iwe miran dipo eyi to wa nilẹ tẹlẹ, ti orukọ Timothy Adegoke wa.

O ni iwe akọsilẹ tuntun to fun oun naa lo ni ki oun fi orukọ ẹlomiran rọpo orukọ Timothy, ki oun si fun awọn ọlọpaa ti wọn ba ti beere iwe akọsilẹ orukọ awọn alejo to sun sile itura naa.

Igbẹjọ iku Timothy Adegoke n tẹsiwaju ni osu keji ọdun 2023

Wayi o, ile ẹjọ giga naa ti sun igbẹjọ iwadi iku to pa Timothy Adegoke siwaju di ọdun to n bọ.

Adajọ Adepele Ojo to n gbọ ẹjọ ọhun lo kede bẹẹ lẹyin ti awọn agbẹjọro Olupejọ ati Olujẹjọ bere ibeere lọwọ awọn ẹlẹrii to yọju si ileẹjọ lọjọ Ẹti

Adajọ Ojo ni igbẹjọ naa yoo tẹsiwaju lọjọ keji oṣu keji, ọdun 2023.

Ki lo waye nile ẹjọ ni Ọjọbọ?

Àwọn agbẹjọ́rò tahùn síra wọn níbi ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke:

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin nipa igbẹjọ iku Timothy Adegoke to waye ni Ọjọbọ.

Nibi igbẹjọ to waye naa ni ọkan lara awọn afurasi ti sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun.

Kazeem Oyetunde si lo jẹ ọkan lara oṣiṣẹ ile itura Hilton mẹta ti wọn fi ẹsun kan pe o gbe oku Adegoke lọ sinu igbo.

Afurasi naa ni oun ko mọ nipa bi foonu, laptop ati awọn ẹru Timothy Adegoke ṣe di awati, tabi mọ ibi ti wọn wa.

Awọn agbẹjọro tahun sira wọn lori asẹ ti Femi Falana ni lati soju ijọba ninu ẹjọ iku Adegoke

Bakan naa nibi igbẹjọ naa, ni awọn agbẹjọro tun ti tahun si ara wọn, lori boya agbẹjọro ẹbi oloogbe, Femi Falana (SAN) ni iwe aṣẹ lati ṣoju ijọba ninu ẹjọ naa.

Ariyanjiyan yii lo kọkọ waye nibi igbẹjọ laarin Falana ati agbẹjọro fun awọn olujẹjọ.

Ninu alaye to ṣe fun ile ẹjọ, Amofin Femi Falana sọ pe oun ni aṣẹ lati se ẹjọ naa.

O fikun pe oun yoo mu iwe ti o fún ni aṣẹ wa ni ọjọ ti wọn ba tun sun igbẹjọ si.

Bẹẹ ba gbagbe, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, ni ijọba ipinlẹ Osun kede pe oun ti fun Femi Falana ni iwe aṣẹ lati ṣoju idile oloogbe ninu igbẹjọ.

Ẹlẹri miran ti o yẹ ki wọn pe, ni ọkan lára àwọn agbẹjọro, ṣugbọn ti ko de si ile ẹjọ titi igbẹjọ fi pari nitori pe oun n rinrinajo bọ lati ipinlẹ Eko.

Onidajọ Adepele Ojo si ti sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2022.

Femi Falana ati awọn agbẹjọro mii
Àkọlé àwòrán, Ariyanjiyan kọkọ waye nibi igbẹjọ laarin Falana ati agbẹjọro fun awọn olujẹjọ.

Ohun to ṣẹlẹ sẹyin nibi igbẹjọ to kọja

Awọn afurasi
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Yatọ si ọga ọlọpaa, nibi igbẹjọ naa, afurasi kan to jẹ oṣiṣẹ ile itura naa, arabinrin Adedeji Adesola tu kẹkẹ ọrọ lori bi oludasilẹ ile itura naa ṣe ni koun sọ fawọn ọlọpaa pe Timothy Adegoke ko wa si ile itura naa lọjọ to de si ibẹ.

Adesola sọ fun adajọ pe Dokita Rahmon Adedoyin ati ọmọ rẹ Roheem pe oun wa si ile igbe wọn ti wọn si sọ pe koun sọ fun awọn ọlọpaa pe Timothy Adegoke ko de si ile itura naa rara ati rara.

"Emi pẹlu Roheem Adedoyin ni a jọ wọle lati lọ ba Dokita Rahmon Adedoyin ninu ile wọn.

Nibẹ ni Dokita ti sọ pe ṣe mo le sọ fún àwọn ọlọ́pàá pe oloogbe Timothy Adegoke ko sun Ile itura Hilton Hotel Honour ni ọjọ taa n wi yi.''

"Wọn bere boya mo gba owo sinu akanti banki UBA mi, mọ dẹ ni bẹẹni.

Wọn ni ṣe mo le sọ fún àwọn ọlọ́pàá pe oloogbe Timothy Adegoke kò sun ilé ìtura naa ati pe mi o gbọdọ darukọ awọn alakoso ile ìtura Hilton Hotel Honour fun awọn ọlọpaa."

O tẹsiwaju pe "Dokita Rahmon Adedoyin ni awọn o ba fi owo sinu banki mi sugbọn awọn ọlọ́pàá yoo mọ.

Wọn ni ki emi àti agbẹjọ́rò wọn lọ ba awọn ọlọpaa nile itura wọn iyẹn Hilton Hotel Honour."

Awọn wo ni afurasi ti igbẹjọ iku Adegoke kan?

Awọn afurasi olujẹjọ ti ẹsun naa kan ni ẹni to ni ile itura Hilton to wa nilu Ile Ife ti Timothy Adegoke ku si, iyẹn Ọmọọba Rahman Adedoyin, tii se ẹni ọdun mẹrinlelọgọta.

Awọn miran ni arabinrin Adedeji Adesola, ẹni ọdun mẹtalelogun, Magdalene Chiefuna, ẹni ọdun mẹrinlelogun ati Adeniyi Aderogba, ẹni ọdun mẹtadinlogoji.

Awọn yoku ni Oluwale Lawrence, ẹni ọdun mẹtadinlogoji ati Oyetunde Kazeem, ẹni ọdun mejidinlogoji.

Adebayo Adekunle tii se ẹni ọdun marundinlogoji naa wa lara awọn afurasi ọhun ati ọmọọba Raheem Adedoyin to ti na papa bora bayii.

Ọrọ naa si tun kan Esther Asigoh ti oun naa ti na papa bora ati Quadiri Moshood ti oun naa ti sa lọ pẹlu.