Lẹ́yìn ọdún kàn, ǹjẹ́ òtítọ́ ti faráhàn lórí ikú Timothy Adegoke?

awoaran Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, Timothy Adegoke

    • Author, Akinlabi Afolabi
    • Role, Broadcast Journalist

Báwo ni ọrọ ṣe ṣẹlẹ?

Lọjọ Keje, Oṣu Kọkanla ni wọn kede pe Timothy Adegoke ti di awati lẹyin ti iyawo ati awọn mọlẹbi rẹ ko si gburo rẹ mọ.

Adegoke ni iroyin ati iwadii awọn ọlọpaa fihan pe o de si ile itura Hilton lati Abuja lọjọ Karun un, oṣu Kọkanla ti o si fẹ sun sibẹ ki o ba a le ribi kopa ninu idanwo ẹka ileẹkọ fasiti Obafemi Awolowo Univeresity ni Ile Ife ni ipinle Osun ti yoo waye lọjọ keji.

Lẹyin tawọn mọlẹbi fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa Edun Abon Police Station ni wọn gbe ẹjọ naa lọ si ẹka to n ṣe iwadii iwa ọdaran iyẹn State Criminal Investigation Department lọjọ Kẹsan an, oṣu Kọkanla, ọdun 2021.

Abalọ ababọ, ọlọpaa lawọn ri oku Adegoke ninu saare kan ti wọn sin in si ti wọn si ti gbe oku naa lọ fun ayẹwo lati mọ ohun to ṣeku pa a.

Bakan naa wọn lawọn ti mu eeyan mẹfa kan tawọn fura si pe wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.

Awọn wo ni afurasi ti igbẹjọ iku Adegoke kan?

Aworan

Awọn afurasi olujẹjọ ti ẹsun naa kan ni ẹni to ni ile itura Hilton to wa nilu Ile Ife ti Timothy Adegoke ku si, iyẹn Ọmọọba Rahman Adedoyin, tii se ẹni ọdun mẹrinlelọgọta.

Awọn miran ni arabinrin Adedeji Adesola, ẹni ọdun mẹtalelogun, Magdalene Chiefuna, ẹni ọdun mẹrinlelogun ati Adeniyi Aderogba, ẹni ọdun mẹtadinlogoji.

Awọn yoku ni Oluwale Lawrence, ẹni ọdun mẹtadinlogoji ati Oyetunde Kazeem, ẹni ọdun mejidinlogoji.

Adebayo Adekunle tii se ẹni ọdun marundinlogoji naa wa lara awọn afurasi ọhun ati ọmọọba Raheem Adedoyin to ti na papa bora bayii.

Ọrọ naa si tun kan Esther Asigoh ti oun naa ti na papa bora ati Quadiri Moshood ti oun naa ti sa lọ pẹlu.

Kini Iwadi ileeṣẹ ọlọpaa sọ?

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun ṣalaye idi ti wọn ko fi ti pe arakunrin Raheem Adedoyin lẹjọ lori ẹsun pe o mọ si iku akẹkọọ fasiti OAU to ku nile itura baba rẹ.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun Yemisi Opalola lo salaye ọrọ naa.

Nigba ti Kayode Ajulọ tó jẹ agbẹjọro ẹbi Timothy Adegoke n beere idi ti ọrọ fi di bayii lọwọ ọlọpaa ni Agbẹjọro Oloye Ramon Adedoyin, Amofin agba Kunle Ọlagoke, SAN ṣalaye pé awọn ko tii ri ẹda iwe iwadii ọku 'Autopsy' naa gba.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti BBC Yoruba ṣe pẹlu rẹ lo tun ti sọ pe: "Awa o tii ri eyi ti ijọba fọwọsi to jẹ esi iwadii ohun to le e ṣekupa oloogbe. A ko tii ri eyi ti ijọba fọwọ si."

O ni eyi ti awọn eeyan n gbe kiri lori ayelujara ti wọn si n sọ oniruuru ọrọ nipa rẹ kii ṣe tootọ rara ṣugbọn o rọ awọn eeyan lati fi ara balẹ ki ijọba ṣe iwadii to tọ lati fi idi otitọ mulẹ.

Tani Rahmon Adedoyin?

Aworan
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹni to jẹ oludasile Hilton Hotel, Rahman Adedoyin to jẹ ilé ìtura ti ìròyìn sọ pé akẹ́kọ̀ọ́ Fáṣítì Obafemi Awolowo ti Ilé-Ifẹ̀, Timothy Adegoke kú si ti sọ̀rọ̀ pe oun ko mọ nkankan nipa iku rẹ rara.

Adedoyin to ti wa ni ahamo Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Osun bayii lori ẹ̀sùn ikú Adegoke to jẹ akẹ́kọ̀ọ́ imọ ipele Masters jẹ ko di mimọ pe oun ko padi àpò pọ mọ awọn oṣiṣẹ oun tabi ẹnikẹ́ni lati pá akẹ́kọ̀ọ́ naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, igba àkọ́kọ́ ti yoo gbọ́ nipa Adegoke ni igba ti awọn Ọlọpaa kede rẹ pe o di awati

O ni:

"Emi Rahmon Adedoyin ko ki n ṣe apaniyan tabi afini ṣogun owo. Ọlọrun ti baba bukun mi na to ti fun mi lowo latigba ti mo wa lọmọ ọdun mẹ́rindinlọgbọn titi di isinsiyii ti mo ti pe ẹni ọdun marundinlaadọrin bayii".

Adedoyin fi kun un pe oun ko paayan ri laye oun. "Musulumi ododo ni mi. Adegoke gba yara nọmba 305 ni Hilton Hotel. Ile itura to fi orukọ rẹ sil ko kọkọ san owo ni orukọ rẹ sinu asunwọn owo ile itura".

Bakan naa lo ni ko si akọsilẹ pe o san owo si asunwo owo Banki WEMA. "Mi o mọ bi wọ́n ṣe fun un ni yara lai san owo sinu asunwọn owo to jẹ ti ileeṣẹ gangan.

Bi Igbẹjọ lori iku Timothy Adegoke ṣe lọ lati ìbẹrẹ...

aworan

Mọlẹbi Adegoke pariwo sita pe awọn n fẹ ki igbẹjọ gbogbo awọn afurasi ti wọn mu lori iku oloogbe naa waye ni ipinlẹ Osun nibi ti isẹlẹ naa ti waye.

Ibeere yii jẹyọ ninu lẹta kan ti agbẹjọro fun mọlẹbi Timothy, Naim Adekilekun kọ nilu Osogbo nipinlẹ Osun 

Bawo ni ti Femi Falana ṣe jẹ?

Kete ti wọn da ẹjọ naa pada si ipinlẹ Osun, Ogbontarigi Agbẹjoro agba, Femi Falana kede pe oun ti di agbẹjoro awọn olupẹjọ

Ẹgbọn oloogbe naa, Olugbade Adegoke salaye pe Femi Falana funra rẹ gan lo n pe oun lori ẹjọ Timothy ati bo se n lọ, paapaa nigba ti wọn gbọ igbe awọn ọmọ Naijiria.

"Baba funra wọn gan ni wọn pe mi nigba ti wọn gbọ ohun tawọn ọmọ Naijiria n se, o ni Olugbade awọn ko ni gba owo lọwọ wa, ẹ ma sare kiri.

Owo ti awọn eeyan ba da, ẹyin ẹbi oloogbe, ẹ gbaa, kẹ maa fi se nnkan miran tori ẹni to n tọju yin lo ti ku yii.

Ti Timothy ba jẹ ọmọ inu mi, maa sa gba idajọ ododo fun."

Arabinrin Adedeji Adesola tu kẹkẹ ọrọ lori Timothy Adegoke

Yatọ si ọga ọlọpaa, nibi igbẹjọ naa, afurasi kan to jẹ oṣiṣẹ ile itura naa, arabinrin Adedeji Adesola tu kẹkẹ ọrọ lori bi oludasilẹ ile itura naa ṣe ni koun sọ fawọn ọlọpaa pe Timothy Adegoke ko wa si ile itura naa lọjọ to de si ibẹ.

Adesola sọ fun adajọ pe Dokita Rahmon Adedoyin ati ọmọ rẹ Roheem pe oun wa si ile igbe wọn ti wọn si sọ pe koun sọ fun awọn ọlọpaa pe Timothy Adegoke ko de si ile itura naa rara ati rara.

"Emi pẹlu Roheem Adedoyin ni a jọ wọle lati lọ ba Dokita Rahmon Adedoyin ninu ile wọn. Nibẹ ni Dokita ti sọ pe ṣe mo le sọ fún àwọn ọlọ́pàá pe oloogbe Timothy Adegoke ko sun Ile itura Hilton Hotel Honour ni ọjọ taa n wi yi.''

"Wọn bere boya mo gba owo sinu akanti banki UBA mi, mọ dẹ ni bẹẹni. Wọn ni ṣe mo le sọ fún àwọn ọlọ́pàá pe oloogbe Timothy Adegoke kò sun ilé ìtura naa ati pe mi o gbọdọ darukọ awọn alakoso ile ìtura Hilton Hotel Honour fun awọn ọlọpaa."

O tẹsiwaju pe "Dokita Rahmon Adedoyin ni awọn o ba fi owo sinu banki mi sugbọn awọn ọlọ́pàá yoo mọ. Wọn ni ki emi àti agbẹjọ́rò wọn lọ ba awọn ọlọpaa nile itura wọn iyẹn Hilton Hotel Honour."

Ibo ni igbẹjọ de duro?

aworan

Ọla o de yii ni igbẹjọ lori iku Timothy yoo tẹsiwaju, Rahmon Adedoyin ni igbagbọ a pe yoo farahan ni ileẹjọ lẹyin ti kudiẹkidiẹ de ba ilera rẹ lọgba ẹwọn.

Adajọ ileẹjọ giga ipinle Osun, Adepele Ojo ti bu ẹnu atẹlu bi awọn Agbẹjọro ṣe n fi ìgbẹjọ lori iku akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo Timothy Adegoke lẹyin ti ọkan lara awọn afurasi, Dokita Rahmon Adedoyin ko lati yọju si ileẹjọ. Ojo ni o tapa sì ofin lẹyin ti oun ti ṣe ileri fun awọn araalu pe Igbẹjọ ko ni ju oṣu mẹfa sugbọn o ti ń ju bẹ lọ, tí ko si dun mọ oun nínu rara.

"Mo ṣetan lati gbe ẹjọ yii fun Adajọ torí o ṣe ọpọlọpọ idaduro fun mi.

"Nkan méjì ni fifalẹ yii le mu jade, boya kí n gbe fun Adajọ mìíran to ni ọpọlọpọ ọdun lẹnu isẹ tabi ki n kì awọn afurasi ma jẹjọ wa lati ile wọn.

"Mo ní láti wa lati ilẹ Amerika nitori ẹjọ yii."