Kí ló ń fa ìjà láàrin ọba Iragbiji àti Ẹ̀rọ̀ Àríkẹ́, gbajúmọ̀ Oníṣègùn ìbílẹ̀ l’Osun?

Oríṣun àwòrán, others
Kabiyesi Aragbiji ti ilu Iragbiji, Ọba Abdulrasheed Ayọtunde Ọlabomi ti fi ẹsun kan Gbajumọ onisegun ibilẹ, Alhaja Falilat Oyetunji, ti ọpọ mọ si “ẹrọ Arikẹ” pe O n gbiyanju ati gba ẹmi oun.
Aragbiji ti ilu Iragbiji ni Alaaja Oyetunji ti pinnu ati ran awọn agbenipa si oun ati awọn ọmọ ilu Iragbiji mẹta.
Ninu fọnran fidio kan ti Ọba AbdulRasheed Ọlabomi fi sita loju opo Facebook rẹ lo ti fi awọn ẹsun yii kan Ẹrọ̀ Arike.
Bakan naa, o ke si gomina ipinlẹ Ọsun, Adegboyega Oyetola ati ọga agba yan-an-yan -an fun awọn ọlọpaa ni Naijiria, lati se iwadi ọrọ naa.
Aragbiji tun ke sawon eekan ọmọ bibi ilu Iragbiji lati gba oun lọwọ Alhaja Ẹrọ Arikẹ to n fi ẹsun kan pe o n gbero ati gbẹmi oun.
"Àwọn ẹrú ikú tí Ero Arike rán sí mí tí ń ṣe òfintótó"

Oríṣun àwòrán, others
Ọba Ọlabomi tẹsiwaju lati jẹ ko di mimọ pe, oun ni ẹri to to fidi mulẹ pe awọn ẹru iku ti Alaaja Falilat ran si oun ti bẹrẹ si ṣe ofintoto irin oun ati ti Baalẹ Ọlọrunda ni ilu Iragbiji kan naa.
Bakan naa lo ni iwadii awọn agbanipa ọhun tun kan alagba kan ni ilu naa, Jimoh Adeleke pẹlu Abdulrasheed Adeleke alias Jimade ati Wasiu Babalola Oluaye.
Asiko ọrọ ko tii to, O digba ti mo ba de kaaba ni Medina – Alhaja Falilat Oyetunji, Ẹrọ Arikẹ fesi

Oríṣun àwòrán, others
Ṣe wọn kuku ni isoro ni igbesi, Alhaja Falilat Oyetunji naa ti fesi si ẹsun ipaniyan ti oride ilu Iragbiji fi kan-an.
Oyeunji ni ilara lo n ba Ọbalaye naa ja ati pe oun ko mọ ohun ti oun le e ṣe fun un, ti o le mu iru wahala bẹẹ wa lati ọdọ ọbalaye naa.
Alaja Ẹrọ Arikẹ wa seleri pe Mecca loun wa lọwọlọwọ lati wa oju rere Ọlọrun.
O ni nigba ti oun ba de Kaaba, loun yoo to tu pẹrẹpẹrẹ alaye kalẹ lori ohun to n waye gan an laarin oun ati Aragbiji ti ilu Iragbiji.












