Ṣé lóòtọ́ ni iléẹjọ́ jú Hushpuppi sẹ́wọ̀n ọdún mọ́kànlá?

Oríṣun àwòrán, Hushpuppi
Ni ọjọ Ẹti ọjọ Kẹrin Oṣu Kọkanla, iroyin bẹrẹ si ni tan kaakiri awọn ojuko iroyin Naijiria ati lori ayelujara pe gbajumọ ọmọ Naijiria to tun jẹ eekan afurasi ọdaran tayọ orilẹede Naijiria, Ramoni Igbalode ti ọpọlọpọ mọ si Hushpuppi, ti gba idajọ ẹwọn ọdun mọkanla.
Amọ ofege gba a ni iroyin yii, ko lẹsẹ nlẹ.
Agbẹnusọ fun ọfiisi adajọ agba ilẹ United States to wa ni aarin gbungbun California, Mrozek Thom, sọ fun BBC pe idajọ ọdaran naa ko tii waye.
Lara itọpinpin ti BBC ṣe boya lootọ ni abi irọ gẹgẹ bi awọn iroyin abẹle ṣe n sọ ọ, Mrozek salaye lẹkunrrẹ nipa rẹ.
“Kii ṣe ootọ, igbẹjọ idajọ rẹ ko tii waye amọ wọn ti gbe eto kalẹ pe yoo waye ni ọjọ Aje to n bọ yii iyẹ ọjọ Keje Oṣu Kọkanla, ọdun 2022.
Nibo ni iroyin ti bẹrẹ pe Hushpuppi ti fi ẹwọn ọdun mọkanla jura?
Iwadii ranpẹ lori ayelujara fihan pe oniroyin ọmọ Naijiria Kemi Olunloyo lo kọkọ sọrọ nipa rẹ loju opo Twitter rẹ ati Facebook ni ọjọ Kinni Oṣu Kọkanla.
Ọjọ mẹta lẹyin eyi ni awọn oniroyin bẹrẹ si ni gbe iroyin ka pe wọn dajọ ẹwọn fun un.
Ileeṣẹ BBC kan si ile ẹjọ US ni kiakia lori atẹjade Olunloye ile ẹjọ si ni irọ gbaa ni.
Ki ni ẹṣẹ Hushpuppi ti Amẹrika ṣe so o mọlẹ?
Awọn oṣiṣẹ alaabo United Arab Emirates fi panpẹ ofin mu Hushpuppi to n gbe ni ilu Dubai ninu Oṣu Kẹfa ọdun 2020.
Ẹsun ti wọn fi kan ni pe o n gbiyanju ati ji ọgọọrọ miliọnu Dollar nipasẹ yiyi oju opo atẹjiṣẹ email oniṣowo ti wọn n pe ni business email compromise (BEC), nipasẹ wiwọke.
Igbesẹ yii si wa lara ohun ti ofin mọ si yahoo-yahoo atawọn ọna mago mago miran lati lu eeyan ni jibiti.
Ninu Oṣu Keje ni ilẹ UAE wa gbe afurasi ọdaran naa lọ si Amẹrika labẹ akoso ọlọpaa ilẹ Amẹrika, FBI nibi ti wọn gba gbe e lọ sile ẹjọ fun igba akọkọ.
Hushpuppi ni oun ko jẹbi ẹsun meji ninu gbogbo eyi ti wọn ni o ṣe nile ẹjọ Amẹrika eyi to jẹ igbimọpọ lati ko owo jẹ gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe akọsilẹ ti BBC foju ri ti agbẹjọro Louis Shapiro si ni ootọ ni.

Oríṣun àwòrán, Hushpuppi
Ki lo de ti ọrọ Hushpuppi ṣe n fa ọpọlọpọ itakurọsọ?
Gbajugbaja ilumọọka ọdaran ti iṣe rẹ tayọ orilẹede kan ni Hushpuppi jẹ to si tun gbajumọ lori ayelujara paapaa julọ lori Instagram nibi to ti maa n ṣafihan igbe aye yala yolo rẹ.
Ọdaran yii jẹ ki awọn eeyan gbagbọ pe iṣẹ ọwọ oun ati iṣẹ aṣekarakara lo gbe oun de ipo ọrọ̀ ti oun wa ati pe o maa n sọ fun awọn to n tẹle e lori ayelujara pe ki wọn fi kun itiraka wọn eyi ti ọpọlọpọ ọdọ ni Naijiria n pe ni “hustle”.
Nibayii, ọpọlọpọ eeyan lo n jẹ ọrọ rẹ lẹnu tori wọn fẹ mọ iye ọdun ti ile ẹjọ ha fun un.
Ẹwẹ, awọn olupẹjọ ni Amẹrika gba ile ẹjọ nimọran pe ki wọn ran Hushpuppi lọ ẹwọn ọdun mọkanla pẹlu ayẹwo ọlọdun mẹta fun asiko itusilẹ rẹ.
Instagram sọ ìdí tó fi pa ojú òpó Hushpuppi rẹ́ lẹ́yìn tó wá lẹ́wọ̀n

Oríṣun àwòrán, Hushpuppi/Instagram
Àwọn alaṣẹ Instagram ti sọ idi ti wọn fi pa oju opo gbajumọ, ọmọ Naijiria to tun jẹ Ogbontarigi onijibiti, Ramon Igbalode, ti ọpọ eeyan mọ si Hushpuppi, rẹ.
Instagram sọ pe Hushpuppi tapa àwọn ilana ayelujara Ibaraẹni dọrẹ ọhun, eyi to tako jibiti.
Wọn ni àwọn ko fẹ ki ẹnikẹni lo ayélujára awọn, lati ja ẹnikẹ́ni lólè tabi lu wọn ni jibiti.
"A ni àwọn ilana to tako iwa jibiti, to fi mọ kiko owó pamọ lọna aitọ."
Agbẹnusọ kan fun ileeṣẹ Meta, to ni Instagram sọ ninu atẹjade pe awọn pa oju opo Hushpuppi rẹ nitori pe o ru awọn ofin náà.
Ṣáájú ki ọwọ ọlọpaa to tẹ ẹ n'ilu Dubai lọdun 2020, Hushpuppi ma n fi àwọn aworan to fihan pe o n jẹ aye ọlọba soju opo naa.
Sugbọn igbe aye ajẹrọrun naa dopin nigba ti wọn mu n'ilu Dubai to n gbe, ni oṣu Kẹfa, ọdun 2020.
Ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ilẹ̀ America, FBI, sọ pe Ramon Abass wa lara awọn onijibi to tobi julọ ni agbaye.
Hushpuppi sọ nile ẹjọ́ kan ni America pe oun jẹbi kiko owo pamọ lọ silẹ okeere lọ́nà aitọ.
Akọsilẹ ile ẹjọ fihan pe iṣẹ to fẹ ṣe ki ọwọ to o tẹ ni pe, o fẹ lati jí owo tó le ni miliọnu kan Dọla, lọwọ ẹnikan to fẹ kọ ile ẹ̀kọ́ ni orile-ede Qatar.
Ati pe gbogbo owo to ti ji to miliọnu mẹrinlelogun Dọla, to si le lọ si bi ẹ̀wọ̀n ogun ọdún.
Kaakiri agbaye ni Hushpuppi ni àwọn alajọ sisẹ pọ si.
Ọjọ keje, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, ni idajọ yoo waye lori Hushpuppi, nílé ẹjọ́ kan n'ilu Los Angeles lorile-ede America.
















