Awuyewuye súyọ lórí ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn Oluwo lórí ikú ọmọ̀ Davido tí Dele Momodu gbé síta

Davido ati Ifeanyi

Oríṣun àwòrán, Davido

Awuyewuye waye lori ọrọ ibanikẹdun Dele Momodu ati Oluwo nipa iku Ifeanyi ọmọ Davido.

Lẹyin ọjọ kan ti wọn tu ọfọ Ifeanyi ọmọ gbajumọ akọrin nni, Davido sori ayelujara, se ni ara ọpọ eeyan n gbona janjan lori iku ọmọ ọdun mẹta naa ati ọna to gba ku.

Idi si ree ti ọpọ eeyan to wa lori ayelujara se n fi oju ọtọọtọ wo awọn ikinni ati ọrọ ibanikẹkun tawọn agba awujọ kan n se nipa iku ọmọ akọrin takansufe naa, paapaa ọna to gba lọ si alakeji.

Eyi naa si lo mu kawọn eeyan kan maa fi oju abuku wo awọn ọrọ ibanikẹdun ti Dele Momodu gbe soju opo ayelujara Instagram rẹ, eyi ti Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, Telu Kinni kọ.

Davido, Ifeanyi ati Dele Momodu

Oríṣun àwòrán, Davido

Ki lo wa ninu ọrọ ibanikẹdun ti Oluwo kọ eyi ti Dele Momodu gbe sita?

Ọba Akanbi lo fi ikede sita lọjọ Isẹgun ti iroyin jade lori iku Ifeanyi lati ba Davido kẹdun lori iku ọmọ naa.

Atẹjade nipa ibanikẹdun naa ti Oluwo fi ransẹ si BBC Yoruba amọ ti Dele Momodu gbe soju opo tiẹ, ni oriade naa ti gbarata lori iku ọmọ naa, eyi to ni o ba oun lojiji.

Ọba Akanbi ni irora nla ni bi ẹda ba padanu ọmọ jẹ amọ a gbọdọ gba fun Ọlrun ni.

Oluwo wa ba Davido ati Ọmọwe Adedeji Adeleke, tii se baba Davido kẹdun pẹlu gomina ipinlẹ Osun ti wọn sẹsẹ dibo yan, Ademola Adeleke, tii se aburo baba Davido.

Bakan naa ni Oluwo tun rannsẹ ibanikẹdun naa si gbogbo awọn eeyan ilu Ede ati ipinlẹ Osun lapapọ lori isẹlẹ ibanujẹ naa.

Ba alaye naa wa rọ wọn lati mu ọkan le, nitori iru awọn isẹlẹ bii iru eyi jẹ ara amuwa Ọlọrun, to si gbadura pe ki Ọlọrun tubọ maa daabo rẹ bo gbogbo ẹbi Adeleke lapapọ.

Ohun ti Dele Momodu gbe soju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, delemomoduovation/Instagram

Ki lo de tawọn eeyan fi fọnmu lori ọrọ ibanikẹdun Oluwo ti Dele Momodu gbe sita?

Bi Dele Momodu se gbe ọrọ naa soju opo Instagram rẹ ni ọpọ eeyan ti tutọ soke, fi oju gbaa lori ikede naa.

Ọrọ ibanikẹdun naa ni Dele Momodu fi aworan Ifeanyi sabẹ rẹ, nibi ti ọmọde naa ti wọ asọ ibiblẹ wa, asọ oke tii se agbada ati sokoto pẹlu fila.

Amọ ọpọ awọn eeyan to sọrọ loju opo Dele Momodu naa lo n naka aleebu si agba akọroyin naa pe ki lo de to gbe aworan ọmọ naa nigba to ti di oku.

Wọn ni Dele ko seese gbe aworan ọmọ naa soju opo ayelujara rẹ ri nigba ti ọmọ naa wa nile aye.

Wọn wa n fi ewe ọmọ mọ Dele Momodu leti pe ko sọra se nitori pe agba awujọ nii se, agbalagba kii si se ki lo ba eyi wa.

Koda, awọn eeyan miran tun wa n beere pe ki lo de ti wọn ko darukọ mama ọmọ naa, eyiun Chioma avril Roland sinu isẹ ibanikẹdun naa?

Ọpọ awọn eeyan to woye ọrọ yii ni orukọ wọn jẹ ti ẹya Igbo ti Chioma ti wa, ti wọn si pọnju koko si bi wọn ko se mẹnuba orukọ Chioma ninu isẹ ibanikẹdun Oluwo naa.

Bi araalu se faraya lori ohun ti Dele Momodu kọ soju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, delemomoduovation/Instagram

Ki lo ti sẹlẹ saaju nipa iku Ifeanyi, ọmọ Davido

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alẹ ọjọ Aje ni iroyin gbalẹ kan pe Ifeanyichukwu tii se ọmọkunrin kan soso ti gbajumọ akọrin takansufe, Davido bi ti jade laye.

Ọpọ eeyan naa ni iroyin ọhun n se ni kami kami kami, ti wọn ko si fẹ gba ikede iku ọmọ naa gbọ.

Amọ nigba to di aarọ ọjọ keji ni agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin fidi isẹlẹ naa mulẹ fun awọn akọroyin pe lootọ ni Ifeanyi ti jade laye.

O ni ọmọ naa lo ko sinu omi ti wọn fi n luwẹ to wa ni ile Davido lasiko ti baba ati iya rẹ ko fi si ninu ile.

O ni o si pẹ ki wọn to sakiyesi pe ọmọ naa ti ku sinu omi, ti ọlọpaa si ti ko awọn osisẹ mẹjọ to n sisẹ ninu ile Davido fun ifọrọwanilẹnuwo.

Amọ nigba to di aarọ ọjọru, ileesẹ ọlọpaa Eko ni oun ti fimẹfa ninu awọn osisẹ naa silẹ, ti meji to ku si ni ẹjọ lati jẹ lori iku ọmọ ọdun mẹta naa.

Bakan naa lo ni o seese ki wọn se ayẹwo oku ọmọ naa lati tubọ mọ ọna to ba l si ọrun aibaamọ ejo le lọwọ ninu.

Isẹlẹ iku ọmọde yii lo dun awọn eeyan de ọkan, paapaa na to ba ku, ti ọpọ awn osere tiata, akọrin, awọn oloselu atawọn agbaagba lawujọ si ti n ransẹ ibanikẹdun si ẹbi Adeleke.