Kunle Afolayan sọ̀rọ̀ sókè nípa nípa sinimá Anikulapo
Kunle Afolayan: Olè gbe, olè gbà á ni ọ̀rọ̀ Saro àti Arolake nínú sinimá Anikulapo, ó sì kọ́ wa nípa àtúnbọ̀tán
Olokiki ati gbajumọ ni Kunle Afolayan ta ba n sọrọ awọn odu, ti kii se aimọ fawọn oloko lagbo tiata, boya ni ede Gẹẹsi ni tabi ni ti Yoruba.
A si le ni ile ni Kunle ba ere sinima sise nitori inu ẹjẹ rẹ lo wa, to si jogun isẹ tiata lati ọwọ baba rẹ to ti di oloogbe, eyiun Adeyemi Afolayan, ti ọpọ eeyan mọ si Ade Love.
Laipẹ yii si ni Kunle Afolayan gbe sinima amilẹ-titi kan jade eyi to pe ni Anikulapo, to si kun fun ọgbọn, agbelarugẹ asa, ede ati ise iran Yoruba.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ nipa igbe aye rẹ ati bi agbo tiata se ri lasiko yii, Afolayan sọrọ ilẹ kun.
O ni oun kii ṣe sinima fun ọna ati jẹun nikan, amọ oun tun maa n ṣe ko le jẹ manigbagbe nitori o ni ti a ba tiẹ kuro laye, ki ni wọn maa sọ nipa wa.

“Isẹ tiata kii se ayaba fun mi, ajogunba ni, mo si maa n wo ohun ti maa se, ti yoo yatọ”
Nigba to n sọrọ lori ọna to n gba kopa ninu ere, Kunle Afolayan ni kikopa ninu ere jẹ abimọ amọ ki oun maa ṣe oludari ati agbatẹru jẹ ohun ti oun ti kọ lati ibẹrẹ wa.
“o dẹ jẹ ohun ti o ti wọ mi lẹwu, to jẹ ti a ba ni ki n mu kan ninu mẹtẹta mi o ni le mu ọkan, meji ni maa fẹ mu.
Maa mu ki n jẹ Oludari ati ki n maa ṣe Olootu ati Agbatẹru gbogbo nnkan ti mo ba fẹ ṣe, iru eeyan ti Ọlọrun da mi niyẹn.”
O tẹsiwaju pe bi oun se wọ inu agbo tiata kii n se ayaba, iṣẹ sinima ni oun n ṣe, ki oun si to bẹrẹ isẹ, ni oun yoo ti kọkọ wo pe ki ni oun le ṣe ti yoo yatọ si ohun ti awọn Baba oun ti ṣe.
Bakan naa lo ni oun maa n wo ohun ti oun le ṣe to maa yatọ si nnkan ti gbogbo eeyan n ṣe, ki oun to bẹrẹ si n ṣe fiimu.

“Ọdun mẹfa sẹyin ni mo ti kọ itan sinima Anikulapo, inu sinima yii si kọ ni wọn yoo ti kọkọ si ara silẹ”
Kunle Afolayan tun sọrọ lori agbekalẹ sinima Anikulapo to sẹsẹ se ati ero ọpọ eeyan lori abala ihoho obinrin ati ọkunrin to wa nibẹ.
Kunle ni sinima Anikulapo je ere ti oun bẹrẹ lati bi ọdun mẹfa sẹyin, ti oun si kọ itan naa lati igba naa.
O ni ọpọ awọn eeyan to n se ariwisi nipa abala ihooho naa ni ko mọ itan, ti wọn ko si tun mọ iṣe Yoruba.
O ni awọn ti wọn ba mọ itan, maa dakẹ ni.
“Ki wọn lọ wo fiimu Ogunde, 'Aye' wọn maa ri eeyan ti o ṣi ọmu silẹ, ti ko wọ aṣọ.
Ki wọn lọ wo 'Kadara' ti Ade Love ṣe, wọn maa ri awọn omidan marun-un ti wọn wọle, ti o jẹ pe isalẹ nikan ni wọn wo aṣọ si.
Ara ẹwa ẹda ati ni ihoho ni gbogbo wa ti wa, ọpọlọpọ awọn eeyan to n kọ kini yii lori ayelujara, awọn ti wọn ran pe ki wọn wa bu ẹnu atẹ lu ohun ti eeyan n ṣe ni.
Wọn ko si le ṣe idaaji ohun ti eeyan n ṣe, lara awọn eeyan ti a jọ wa ninu iṣẹ maa wa n bẹ, ẹlomi naa wa ti o fẹ gbe ẹsin wọ asa, awọn naa a wa n bẹ.”
“Sinima Anikulapo kọ wa nipa atunbọtan ẹda eyi to yẹ ka maa ronu nipa rẹ”
Nigba to n sọrọ lori awọn ohun ti sinima Anikulapo da le lori, Kunle Afolayan ni ijamba ta fun ijamba ra ni ọrọ Saro ati Arolake.
“Fun ẹni ti o ba mọ itumọ rẹ, ole gbe e, ole gba a naa ni, ọpọlọpọ ohun ti a ba n ṣe laye awọn eeyan o ki n mọ itumọ atunbọ tan, won o ki n wo.
O ko si le ta ọja iyẹpẹ, ko ma gba owo okuta, ohun ti eeyan ba ta naa ni yoo ma ra.
Ti eeyan ba ti ṣi ẹsẹ gbe ni awon ibi kan, ti o ti fi ojukokoro gba nnkan mọra pe ohun ọwọ mi o to maa fi gọngọn fa.
Wọn ni ole ni eeyan, pe o lu eeyan ni jibiti, wọn wa mu, ẹ wa ni pe bi o tiẹ jẹ pe o lu jibiti, ṣebi jibiti diẹ lo lu, ẹ ṣe jẹ ki a dariji.
Bẹẹ ni ọrọ Arolake ati Saro jẹ amọ ti eeyan ba ri anfani tabi aye lati le gba oore orisirisi mọra, emi naa yoo gba.
Emi wa le maa fi ibi su oloore amọ ti wọn ba ni wa gba nibi, e mi a lọ.”
“Mo n fi asa, ise ati ede Yoruba kọ awọn ọmọ mi lati kekere ni mo se fi ọmọ mi sinu sinima Anikulapo”
Ọpọ eeyan lo woye pe ọmọ Kunle Afolayan wa ninu ere Anikulapo, to si se ọmọọba Alaafin Oyo to tu asiri Arolake ninu ere sinima Anikulapo.
Ninu alaye rẹ, to se fi ọmọ bibi rẹ sinu sinima to gbe jade, Kunle ni oun fi ọmọ oun 'Eyiyemi' sinu ere naa nitori pe awọn ewe iwoyii ko fi bẹẹ gbọ ede abinibi mọ.
Awọn ọmọ wa nisin wọn ko gbọ Yoruba, wọn ko tiẹ bikita, to ba dẹ bi wọn, wọn yoo da obi wọn lẹbi, idi ree ti emi se gbiyanju latilẹ lati kọ awọn ọmọ mi lati mọ aṣa ati iṣe abininbi wọn.
Ti emi ati awọn ọmọ mi ba n sọrọ nisinsinyi, ọpọlọpọ igba Yoruba ni a maa n fi sọrọ, wọn le kọ, wọn si le kaa, wọn si le sọ.
Ọmọ mi dara, o rẹwa lọmọ, o jọ ọmọọba, ọmọọba tiẹ ni, o gbọ Yoruba, o kan maa wa ku pe Yoruba ti o maa sọ, kiie Yoruba ti ẹ n fi ahọn sọ ni Eko.
Mo si ri pe ọmọ mi le se ipa ti mo fun ninu ere naa, ni mo se ni ko wa ko ipa naa, abi ki ni maa tun wa wa eeyan to le se kiri fun?”






