Florence Oyeyemi, obìnrin, ẹni ọdún 38 tó ń díje sílé aṣojúṣòfin
Ọkan lara awọn obinrin to n dije sile aṣojuṣofin lati ipinlẹ Kwara ni Olasumbo Florence Oyeyemi.
Ẹni ọdun mejidinlogoji ni Oyeyemi to n dije sipo aṣojuṣofin lati lọ ṣoju ẹkun idibo Ekiti/Irepodun/Isin/Oke-Ero lati ipinlẹ Kwara.
Ṣaaju ko to maa dije sipo aṣojuṣofin, Oyeyemi ti kọkọ ṣe Kọmiṣanna feto isuna ati aato ilu ni ipinlẹ Kwara, eyi to ṣe nigba to wa lẹni ọdun mọkanlelọgbọn.
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori ipa awọn obinrin ninu eto oṣelu, Oyeyemi sọ pe o pọn dandan lati maa fi awọn obinrin sipo agbara ki wọn ba a le maa ko ipa wọn si idagbasoke ilu.
O sọ pe awọn obinrin ni awọn nnkan to pọ lati mu ilọsiwaju ati idagbasoke ba awujọ amọ to ni awọn obinrin gbọdọ mọ pe ko si ẹni to maa fun wọn nipo naa ti wọn ko ba ji giri lati wa ipo naa funra wọn.
O ni gbogbo iṣẹ tawọn ọkunrin n ṣe lagbo oṣelu naa ni obinrin le ṣe to si yẹ kawọn obinrin maa lo iriri ati ikapa wọn lati fi ri pe awọn de awọn ipo yii.
Oyeyemi tun rọ awọn gomina lati maa fi awọn obinrin sipo oṣelu eyi to le mu kawọn eeyan ri ipa wọn lawujọ, to si ni eyi maa ṣeranwọ fun wọn nigba ti wọn ba gbegba ibo lati du ipo kan tabi omiran nitori awọn eeyan ti maa ri iṣẹ ti wọn ṣe nigba ti wọn b awa niru ipo bẹẹ.
"A o gbọdọ maa ri ara wa gẹgẹ bi ẹni to ti to tan nigba ti a ba wa nipo oṣelu tabi ipo agbara kan"
Nigba to n sọrọ irinajo rẹ gẹgẹ bi Kọmiṣanna feto isuna, Florence Oyeyemi sọ pe oun ṣe gbogbo ohun to wa ikapa oun lati ri pe oun ko doju ti awọn ọdọ atawọn obinrin nigba ti oun wa nipo naa.
O ni gbogbo eeyan, paapaa awọn ọdọ to ba wa nipo kan gbọdọ maa ri ara wọn gẹgẹ bi ẹni to maa fi ipo naa silẹ, ki wọn ma ma huwa gẹgẹ bi to jẹ pe awọn ni Ọlọrun gbọla fun lasiko naa.
"Igba ti wọn fi mi jẹ Kọmiṣanna, ọrọ ti mo maa n sọ fun awọn eeyan ni pe igun meji ni mo n ṣoju. Igun meji to tumọ si pe mo n ṣoju awọn obinrin, mo dẹ n ṣoju awọn ọdọ.
"Mo dẹ n ṣiṣẹ yẹn wi pe mi o fẹ ṣiṣẹ yẹn ni balabala nitori awọn obinrin to n bọ lẹyin mi ki n ma ba a di wọn lọna, atawọn ọdọ to wa lẹyin mi ki n ma ba a di wọn lọna, ki wọn ma ni i ṣebi a fun wọn, ẹ wa wo bi wọn ṣe ṣe, ṣebi a fun wọn, ẹ wo bi wọn ṣe ṣe, mo fẹ fi ara mi ṣina fun awọn to ku to n bọ lẹyin mi.
"Ka ma wo o pe a ti wa ni ipo yii bayii tori emi ni Ọlọrun fi ṣe ipo yii fun mi ẹ jẹ n ṣe fun emi ati emi ati emi nikan ni.
"Ka mọ pe ninu irinajo paapaa ti a ba kere, a ṣi n dagba bọ ni anfaani maa wa nigba mii ti eeyan maa lo gẹgẹ bi atẹgun fun awọn anfaani mii."
"Mo fẹ kawọn eeyan ti mo fẹ lọ ṣoju ri apẹẹrẹ ijọba awaarawa ti wọn ba gbemi depo"
Oyeyemi tun fi kun pe gbogbo iriri ti oun ti ni lẹnu iṣẹ ijọba ati alakooso ti oun ti ṣe fun oun ni amuyẹ lati jẹ oludije to kaju oṣuwọn lati de ipo ti oun n dije fun.
"Ti mo ba wo gbogbo iriri mi lati nimọ nipa bi eto ijọba ṣe n ṣiṣẹ labẹle atawọn iṣẹ ti mo ti ṣe ni eto ijọba apapọ, o fi mi sipo gẹgẹ bi oludije to nimọ to peye to ni iriri labẹle."
O sọ pe oun to ṣe pataki julọ si oun ni lati ri pe gbogbo awọn ti oun fẹ lọ ṣoju nile igbimọ aṣojuṣofin lẹkun ijọba ibilẹ Ekiti/Irepodun/Isin/Oke-Ero lati ipinlẹ Kwara ni wọn ri ipa iṣejọba awaarawa ti oun ba ni anfaani lati de ipo naa.
O fi kun pe oun maa fọwọsowọpọ pẹlu gomina, sẹnetọ to ba n ṣoju ẹkun guusu Kwara, awọn alaga ijọba ibilẹ ẹkun naa lati pese mukundun ijọba awaarawa fawọn ara agbegbe naa.




