"Mo rí ìjọba amúnisìn, mo rí ìgbòmìnira, mo rí ogun àti àlááfíà. Nínú gbogbo rẹ̀, ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni mo dì mú" - Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Reuben Fasoranti olórí ẹgbẹ́ Afẹnifẹre tó jáde láyé

Aworan Baba Rueben Fasoranti
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọdun 1926 ni wọn bi Baba Fashọranti ni ilu Uso ni ipinlẹ Ondo. Iṣẹ olukọ lo ti kọkọ bẹrẹ ki o to darapọ mọ oṣelu ati ijangbara fun iṣejọba tiwantiwa.

O kẹkọgboye ni fasiti Ibadan ki o to lọ kẹkọ sii lati gba iwe ẹri olukọni ni fasili Hull lorilẹede UK. Lẹyin eyi o tun kawe sii lati gboye imọ ijinlẹ Masters nipa akoso eto ẹkọ ati iṣakoso ie ẹkọ ni fasiti Macquarie lorilẹede Australia.

O ṣiṣẹ olukọ ni ileẹkọ girama Ondo Boys High school atawọn ile ẹkọ miran lagbegbe Ondo ati Akurẹ. Lẹyin igba diẹ loun pẹlu da ile ẹkọ ara rẹ silẹ ninu eyi ti a ti ri Ọmọlere Nursery and Primary School, Akurẹ High School ati St Frances' Academy ni Igoba nilu Akurẹ.

Irinajo oṣelu rẹ wa ni ipẹkinpẹki pẹlu irinajo Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ; ilana oṣelu Awo lo si mu dani to fi darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Action Group nigba naa ki o to di Unity Party of Nigeria.

Laarin ọdun 1979 and 1983, Ọgbẹni Fasoranti di ipo kọmiṣọna fun eto iṣuna labẹ ijọba gomina Adekunle Ajaṣin ni abẹ ipinlẹ Ondo laye ọjọun.

Lẹyin eyi loun pẹlu di ọkan lara awọn aṣiwaju lẹgbẹ Afẹnifẹre, to jẹ ẹgbẹ kan gboogi to duro lori ilana Awolọwọ.

Ipa to ko lasiko ijangbara fun ijọba alagbada

Baba Fasoranti jẹ ọkan gboogi lara awọn to koju ologun fun idapada ijọba alagbada loriede Naijiria.

Ipinnu rẹ lo sọ ọ di ẹni to n darapọ mọ ẹgbẹ NADECO to lewaju didoju kọ ijọba ologun lati da ijọba pada fun alagbada laaarin ọdun 1993 si 1999.

O pada wa di olori ẹgbẹ Afẹnifẹre lẹyin iku Baba oloye Abraham Adesanya, bi o tilẹ jẹ wi pe ija tani olori to waye laarin oun ati awọn adari ẹgbẹ naa kan pada di oun to mu ipinya wọ aarin ẹgbẹ naa.

"Majẹobajẹ agba lorilẹede ni Baba Fasoranti"

Eeyan kan n tọwọ bọwe ibanikẹdun ni ile Oloogbe Fasoranti.

Lasiko to fi n ṣe ayẹyẹ ajọdun ọjọ ibi ọgọrun ọdun rẹ, aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Tinubu tọka si Baba Fasoranti gẹgẹbi agbalagba to n to ilu, alakoso to dantọ, ajafẹtọ araalu ati ijọba tiwantiwa ti iwa ootọ, ọmọluabi ati ifọkansi ṣiṣe iṣẹ sin ilu.

Aarẹ Tinubu ṣe iranti bi awọn kan ṣe gbiyanju lati gba ẹmi rẹ lasiko iṣejọ ologun labẹ Ọgagun agba Sani Abacha nigba naa. O ni iṣẹlẹ naa tubọ mu ki o ṣe ọkan giri lati koju iwa ijẹgaba awọn ologun.

Awọn ọfọ to ṣẹ ẹ

Oniruuru adanu lo de ba Baba Fasoranti. O padanu iyawo rẹ lọdun 19991. O tun padanu ọmọ rẹ, Funkẹ Ọlakunrin ti awọn agbebọn kan ṣekupa ni oṣu keje ọdun 2019.

Lasiko ajọdun ọjọ ibi rẹ loṣu karun un ọdun 2026, Baba Fasoranti ṣalaye ninu ọrọ to sọ nibẹ pe "Mo ti ri ijọba amunisin, mo ti ri igbominira, oju mi ti ri ogun ati alaafia. Mo ti ri ijọba ologun ati ti alagbada. Ninu gbogbo rẹ ohun kan to mu mi duro ṣinṣin ni ibẹru Ọlọrun, itẹpamọṣẹ ati ṣiṣe iṣẹ sin ọmọlakeji."

O ni irinajo oun pẹlu Afẹnifẹre ti jẹ ki oun mọ laisiyemeji pe ifaraẹnijin nikan lohun ti wọn n pe ni ipo adari

Ààrẹ ẹgbẹ́ Afẹnifẹre, Reuben Fasoranti jade láyé lẹ́ni ọdún 100
Alagba Reuben Fasoranti nigba to wa laye

Olori ẹgbẹ Afenifere nilẹ Naijiria, Alagba Reuben Famuyide Fasoranti ti jade laye.

Ọjọ Iṣẹgun, ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 la gbọ pe Alagba Fasoranti ki aye pe o digboṣe, lẹyin aisan to nii ṣe pẹlu ọjọ ogbo.

Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa lo fidi iroyin naa mulẹ ninu atẹjade to fi sita.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aiyedetiwa sọ pe adanu nla ni iku baba naa jẹ fun gbogbo ọmọ Kaarọ-o-jiire bi, nitori pe asiko ti wọn nilo rẹ ju, lo jade laye.

"Pẹlu ọkan to wuwo ati jiọwọ fun ifẹ Ọlọrun, mo n kede iku agba alẹnulọrọ, Alagba Reuben Famuyide Fasoranti, ẹni to jade laye lẹni ọgọrun-un ọdun," Aiyedatiwa sọ bẹẹ.

Gomina naa sọ pe agbalagba to ko ipa ribiribi ninu idagbasoke ipinlẹ Ondo, ilẹ Yoruba ati orileede Naijiria lapapọ ni Oloogbe naa.

"Alagba Fasoranti jẹ agba, orison imọ, pẹlu iwa ọtitọ ati ifarajin ti igbe aye pipẹ rẹ tọka si oniruuru ifarajin si idagbasoke ipinlẹ wa, ilẹ Yoruba ati orileede Naijiria lapapọ," gomina fidi rẹ mulẹ.

O tẹsiwaju pe awọn ilana, itọni ati iduro lori otitọ rẹ ni awọn yoo ṣafẹri gidigidi.

Bẹẹ lo sọ pe ipa to fi lelẹ yoo si maa wa nilẹ fun awọn iran to tun n bọ lẹyin.

Bakan naa lo ba idile oloogbe naa kẹdun, to fi mọ gbogbo ilu Akure ati ipijnlẹ Ondo lapapọ kẹdun iku agba alẹnulọrọ ọhun.

"Lorukọ ijọba ipinlẹ yii ati awọn eeyan ipinlẹ Ondo, mo n ba idile, ilu Akurẹ ati gbogbo ipinlẹ yii kẹdun adanu nla yii," gomina kadi ọrọ rẹ nilẹ.

O wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ baba naa si afẹfẹ rere.