Mo ní kí wọ́n sin ọmọ mi márààrún pẹ̀lú òkú ọkọ mi, mo ni ayé ti parẹ́ - Màmá Rainbow
"Ìyà jẹ mi, àrífín pọ̀, ayé le mọ́ mi, ìyá onílé mi ní kí ń lọ kú pẹ̀lú ọkọ́ mi"

Bi a ko ba jiya to to agbọn, a kii jẹ ila to kun ahá ni Yoruba n wi, bẹẹ si ni ẹni ti yoo ga, ẹsẹ rẹ yoo tiirin.
Bi ọrọ se ri ree pẹlu igbe aye gbajumọ osere tiata, Idowu Phillips, ti ọpọ eeyan mọ si Mama Rainbow, ẹni to n sami ọjọ ibi ọgọrin ọdun loke eepẹ lonii.
Jọ Kẹrindinlogun osu kẹwa ọdun 1942 ni wọn bi gbajumọ osere tiata naa.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn ipenija alagbara to la kọja, Mama Rainbow ni aye su oun lasiko naa.
Bakan naa lo salaye ọpọ iwa ẹgbin tawọn akẹẹgbẹ rẹ ni agbo tiata hu si lasiko to ni ipenija naa, ki igbadun to de.
"Ko rọrun fun mi lati tọju ọmọ marun, lai si ọkọ, iya jẹ mi pupọ”
Mama Rainbow salaye pe ọdun meji ati aabọ ni ọkọ oun fi se aisan, ko to dagbere faye.
O ni ọjọ nla ni ọjọ Kejilelogun osu Kinni ọdun 1984 ti ọkọ oun, Femi Phillips, ti oun naa jẹ osere tiata, jade laye.
O ni nigba to ku, ti wọn si fẹ sin, oun sọ fawọn eeyan to wa nibẹ pe ki wọn sin awọn ọmọ maraarun tawọn bi pẹlu ọkọ oun nitori iya to n bọ.
O ni ni kete ti ọkọ oun ku tan ni isoro ati iya nla nawọ gan oun atawọn ọmọ maraarun ti awọn bi.
“Oju mejeeji gan n tọ ọmọ, ko rọrun, ka to wa sọ pe oju kan soso, wahala naa pọ, iya j mi, mo si gba ọpọ arifin mọra.
Ko rọrun rara lati tọju ọmọ marun, mo si ro pe aye ti parẹ ni nigba ti ọkọ mi ku, ipenija nla si lo doju kọ mi.”
“Awọn onitiata ẹgbẹ mi, ti ọkọ mi maa n fun lowo ounjẹ tẹlẹ gan nawọ abuku si mi lẹyin iku ọkọ mi”
Bakan naa ni Mama Rainbow fikun pe iya ti oun jẹ, maa n tete mu ki eeyan gbo ni amọ aanu ni oun ri gba lati pe ẹni ọgọrin ọdun lonii.
O fikun pe lasiko ti wahala naa de, awọn osere tiata ti ọkọ oun maa n fun ni owo ounjẹ tẹlẹ, ti wọn si maa n pe oun ni Madam, gan ni wọn kọkọ na ọwọ arifin si oun.
O ni ọpọ wọn gan ni yoo pe oun si sinima sise, ti wọn yoo si ko owo tasọrẹ le oun lọwọ pe oun yoo gba owo yoku to ba ya, amọ ti wọn ko ni fun oun mọ.
“Ẹsẹ ni maa rin lati Iyẹsi de Ijọra, ma si sọ fun awọn eeyan ta jọ n lọ pe mo fẹ wo ẹgbọn mi kan lai si ẹgbọn kankan to n gbe adugbo naa.
Se ni maa ra ẹpa, ti maa ma wọn jẹ loju popo, titi ti maa fi de ile.
Idi ree ti iwe Atọka fi kede orukọ mi nigba naa gẹgẹ bii osere tiata to n gba ọ̀pọ̀, to n gba owo to kere julọ lagbo tiata.”
Mama Rainbow wa salaye pe idi ree ti oun se pinnu lati mase bawọn onitiata kan se isẹ mọ nitori iwa ẹgbin ati abuku ti wọn hu si oun lasiko ti oun n la awọn ipenija naa kọja.
“Mama Onile mi sọ fawọn ọmọ mi pe ki emi naa lọ ku pẹlu ọkọ mi, nigba ti a ko ri owo ile san”
Mama Rainbow tẹsiwaju pe ni akoko ti oun nla awọn isoro naa kọja, lọjọ kan ti oun ko si nile, ni mama onile wa sile.
O ni mama naa wa sọ fun awọn ọmọ oun pe ki wọn sọ fun oun pe nitori pe oun ko ri owo ile san, yoo dara ki oun kuku lọ ku gẹgẹ bi ọkọ oun se ku.
“ Ẹ wo, ko rọrun rara fun obinrin ti ọkọ rẹ ba ku lati tọju awọn ọmọ, ọpọ eeyan si lo maa n bu iru wọn pe wọn n se asẹwo.
Ọna to ba wu obinrin bẹẹ lo le gba lati tọju awọn ọmọ naa, o kan wu emi lati mase asẹwo ni.”
“Asiri Ọlọrun ni ẹwa mi loni, ti mo ba n ya itan maalu jẹ, o to bẹẹ”
Mama Rainbow wa n dupẹ lọwọ Ọlọrun to ran lọwọ lati tọ awọn ọmọ rẹ maraarun, ti gbogbo wọn si kawe.
O ni iru iya ti oun jẹ lẹyin iku ọkọ oun lati tọju awọn ọmọ maa n mu ki eeyan tete gbo ni amọ oun dupẹ pe Ọlọrun jẹ asiri ẹwa oun lẹni ọgọrin ọdun.
“Aanu ni mo ri gba, mo ro pe aye maa parẹ lasiko ti isoro de ba mi ni, iya jẹ mi, ẹgbin ta ba mi.
Amọ mo dupẹ lonii, ti mo ba si n ya itan maalu jẹ, o to bẹẹ, koda, o ju bẹẹ lọ.”






