Èrò OSIEC àti PDP l‘Osun tako ara wọn lórí ìbò ìjọba ìbílẹ̀
Osiec ní ìbò ìjọba ìbílẹ̀ Osun pegede àmọ́ PDP ní arúmọjẹ ní

Alága ètò ìdìbò ìjọba ní ìpínlè Òsun ti gboriyin fún àwọn ará ìlú bi won se tu jade daadaa ni awọn iledibo miran ati ward lati dibo ijọba ibilẹ to waye nipinlẹ naa.
Alaga ajọ eleto idibo ibilẹ ni ipinle osun (OSIEC) Otunba Olusegun Oladitan soro lori bi awon eniyan ti jade fun idibo ati bo ti lo ni irowo rose lakoko idibo ijoba ibile to sese kasenle loni.
Nigba to n ba akoroyin BBC Yoruba soro ni ofiisi re, Oladitan sọ pe inu oun dun gidigidi bi awon eniyan se jade lawon apa ibi kan wa dibo.
O ni won si dibo na ni irowo rose lati dibo yan eni to wu won ko dari wọn ni ijọba ibilẹ koowa wọn.
Ile ẹjọ lo da wa lare pe ka tẹsiwaju ninu idibo naa - Osiec Osun
Oladitan wi pe iroyin tawọn osise oun to jade lọ tọpinpin bi eto idibo naa se lọ, fi ransẹ si oun, o dun mọ oun ninu pe eto idibo naa waye ni alaafia.
Oladitan tun soro nipa bi awon ẹgbẹ oselu to ku ti gbe ajọ naa lọ sile ẹjọ pe awon ko fẹ ki eto idibo naa waye rara.
O ni sugbon adajọ ko ridi kankan ti eto idibo naa ko se ni waye, ti adajọ si kede fun ajọ naa lati tẹsiwaju ninu eto idibo ọhun.
O tun so wipe bi ile ejo ba ni awon ko gbodo dibo , ko si oun tawon le se rara.

Ijọba APC kan fi owo ilu sofo ni pẹlu ibo ijọba ibilẹ awuruju to se - PDP Osun
Wayi o, ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Osun ti koro oju si eto idibo ijọba ibilẹ to waye yika ipinlẹ naa lọjọ abamẹta ana.
PDP Osun ni se ni ijọba gomina Adegboyega Oyetola kan n fi owo apo ijọba ipinlẹ naa sofo pẹlu eto idibo to waye naa.
Ninu eto idibo to waye jake jado ipinlẹ Osun naa ni ẹgbẹ oselu kan soso, APC ti kopa ninu rẹ.
Ẹgbẹ Oselu PDP lo kede bẹẹ ninu atẹjade kan to fisita eyi ti alaga igbimọ alakoso ẹgbẹ, Ọmọwe Adekunle Akindele fọwọ si.
Ninu atẹjade ọhun si lo ti n kan saara si awọn eeyan ipinlẹ Osun pe wọn kare lori bi wọn se tẹle ipe to ni ki wọn ta kete seto idibo ijọba ibilẹ naa.
"Ẹtahoro ọmọ ẹgbẹ oselu APC nikan lo dibo, se lawọn agọ idibo da paro-paro"

“Ta ba wo ihuwasi awn eeyan ipinlẹ Osun to kẹyin seto idibo ijọba ibilẹ naa, o ti pẹ ju fun gomina Oyetola lati tọrọ aforijin pe oun yoo da owo ilu toun na seto idibo naa pada.
Lati ibẹrẹ ni ipalẹmọ fun to idibo naa ti wọ wa, gbogbo ọna ta si gba lati pe akiyesi gomina si igbesẹ rẹ naa, ni ko kọbi ara si.
Idi ree ti gbogbo awọn agọ idibo jakejado ipinlẹ Osun se da paro, to si jẹ ẹtahoro awọn ọmọ ẹgbẹ APC nikan lo wa nibẹ.”
Ẹgbẹ oselu PDP tẹsiwaju pe iwe idibo ti wọn lo gan ko safihan awọn ẹgbẹ oselu to n kopa ati ami idamọ wọn, ti ko si tun se afihan ijọba ibilẹ ti wn ti n dibo.
O ni eyi lo si mu ki awọn eeyan ipinlẹ Osun atawọn onwoye bi eto idibo naa se lọ si fi maa beere pe se idibo lo n waye ni abi eto rẹfirẹndọmu lati mọ ero araalu nipa igbesẹ naa.

"A gbe awọn to seto awuruju ibo naa rele ẹjọ, ta si gba gbogbo owo ti wọn na sori rẹ pada"
“Igbesẹ ijọba yii lo n se ẹlẹya ilana idibo ijọba alagbada nitori kikida awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC nikan lo wa ni awọn agọ idibo.
Lakotan, ohun to waye nipa idibo naa fihan pe awọn eeyan ipinlẹ Osun ko tẹwọgba idibo awuruju ti wọn pe ni idibo ijọba ibilẹ, ta si kan saara si ọkan akin tawn araalu se.”
Ẹgbẹ oselu PDP wa n sekilọ pe oun ko ni ni ohunkohun se pẹlu awọn osisẹ ti ko bojumu ti eto idibo awuruju naa ba fa kalẹ.
Bakan naa lo n fi ọwọ gbaya pe ijọba tuntun to n bọ nipinlẹ Osun yoo ri daju pe gbogbo awọn eeyan to ni nnkan se pẹlu idibo ọhun lo finmu kata ofin.
PDP ni gbogbo owo ti wọn ba si na lori eto idibo ijọba ibilẹ naa ni oun yoo gba pada perepere.
Àwọn olùdìbò dágunlá sí ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ l’Ọṣun

Paroparo lọpọlọpọ awọn ibudo idibo nibi eto idibo kansu nipinlẹ Ọṣun to waye lọjọ Abamẹta da pẹlu bi ọpọ awọn eeyan ipinlẹ naa to ti to ibo o di ko ṣe kopa ninu eto idibo naa.
Ẹgbẹ oṣelu APC nikan lo fi ifẹ han si kikopa ninu eto idibo naa lẹyin ti awọn ẹgbẹ alatako bii PDP, APP atawọn ẹgbẹ oṣelu miran ṣe faakekọri pe awọn ko ni kopa ninu eto idibo naa nitori pe ọrọ nipa rẹ wa niwaju ile ẹjọ.
Akọroyin BBC to lọ kakiri awọn ibudo ibo rii pe awọn oludibo diẹ lo jade lati dibo.
Bakan naa lawọn eeyan ko fi bẹẹ pa aṣẹ ti ijọba ipinlẹ naa fi sita pe ko ni si lilọ bibọ ọkọ laarin agogo meje owurọ si mẹta ọsan nitori idibo naa mọ. Ọpọlọpọ awọn ibudokọ eroni ilu Oṣogbo tii ṣe olu ilu ipinlẹ naa atawọn ilu miran nibẹ ni wọn n ko ero, ti awọn alupupu ọkada si n lọ kaakiri lati ṣe ọrọ aje wọn.
Lára àwọn ibi ibudo idibo ti akọroyin BBC de ni ijọba ibilọ Osogbo Unit 5 ati 7 Ward 3 Ataọja 'c' Asubiaro, Unit 10 ati 11 ward 3 Olutimehin Grammar school, ìjọba ìbílẹ̀ Ọlọrunda Unit 33 ward 8,mosafejo; Ijoba ibile Boripe Unit 2 ati 3 ward 11 ni ilu iree, Unit 2ward 1 L.A pry school popo,Iragbiji.

Gomina Oyetọla dibo ni Iragbiji
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla dibo tirẹ lowurọ ọjọ Abamẹta pẹlu Iyawo rẹ Kafayat ni ibudo idibo Unit 2, ward 1 L.A Pry school popo, nilu Iragbiji ni ijoba ibile Boripe.
Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ lẹyin to dibo, gomina ipinlẹ Ọṣun Gboyega Oyetọla fi idunnu rẹ si bi eto idibo naa ṣe lọ.
Bakan naa lo kan sara si ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọṣun atawọn ajọ agbofinro fun iṣẹ takuntakun to ni wọn ṣe fun abo ati alaafia lasiko idibo naa.

Bakan naa ni a tun ri ẹgbẹ oṣelu APC All Progressive Congress APC nikan laarin awọn ẹgbẹ oṣelu mẹrinla miiran lo n kopa ninu idibo ti n lọ lọwọ pẹlu iwe idibo ti Bẹẹni tabi Bẹẹkọ.
Lára àwọn aṣoju ẹgbẹ òṣèlú APC ti o wa ni ile ètò ìdìbò Adeniyi Latifat so fun akoroyin BBC News Yoruba pé àwọn oludibo n jade leeyoosoka ti wọn sì n dìbò pada Si Ile ni ko je ki a ri àwọn oludibo pipọ pẹlu wọn.

Ijọba ipinlẹ Ọṣun kede pe ko ni si lilọ bibọ ọkọ kaakiri ipinlẹ naa loni ọjọ Satide ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹwaa ọdun 2022 nitori eto idibo sijọba ibilẹ to n waye nibẹ.
Atẹjade kan ti kọmiṣọna feto iroyin nipinlẹ naa, Funkẹ Ẹgbẹmode fi sita sọ pe eyi yoo fun awọn oluddibo lanfani lati dibo wọn laisi idiwọ rara.
“Ijọba n rọ gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ yii lati jade lọ dibo wọn lọjọ Satide, nitori anfani nla leyi jẹ lati yan awọn aṣoju ati adari wọn nijọba ibilẹ.”
Ninu atẹjade naa, ijọba ipinlẹ Ọṣun ṣeleri pe abo to peye yoo wa fun ẹmi ati dukia lasiko idibo naa.
Ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo lo n dije ni ibo ijọba ibilẹ l’Ọṣun
Ninu ọrọ to sọ l’Ọjọbọ, alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọṣun, OSIEC, Ṣẹgun Ọladitan ṣalaye pe ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo lo tii fi ifẹ han si kikopa ninu eto idibo naa.
Alaga ajọ OSIEC naa ko darukọ ẹgbẹ oṣelu naa ṣugbọn o fi da awọn eeyan ipinlẹ naa loju pe eto idibo to ṣee fọwọ rẹ sọya lajọ naa yoo gbe kalẹ.

Lati igba ti ajọ eleto idibo nipinlẹ Ọṣun ti kede pe oun fẹ ṣeto idibo sijọba ibilẹ nipinlẹ naa ni awọn ẹgbẹ oṣelu alatako nipinlẹ naa ti kebosi sita pe awọn ko lee lọwọ si.
Idi ti wọn n la kalẹ paapaa, ẹgbẹ oṣelu PDP ti yoo gba iṣakoso ijọ nipinlẹ naa, ni pe o ṣe jẹ asiko atiwọ iṣejọba APC nipinlẹ naa ni wọn ṣẹṣẹ n rii pe eto idibo sijọba ibilẹ yẹ ko waye.
Ẹgbẹ oṣelu PDP ati APP nipinlẹ Ọṣun ti gbe ajọ eleto idibo ipinlẹ naa lọ sile ẹjọ ninu ipẹjọ ọtọtọ lati tako idibo naa












