Ìjọba Eko bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ẹ̀sùn pé àwọn nọ́ọ̀sì ya fídíò Rico Swavey dípò kí wọ́n dóòlà ẹ̀mí rẹ̀

Rico Swavey ati Gomina Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Rico Swavey/instagram

Ijọba ipinlẹ Eko sọ pe oun ti bẹrẹ iwadii lori ileewosan ti wọn kọkọ gbe oloogbe Rico Swavey lọ.

Ọjọbọ ni Patrick Fakoya, ti ọpọ mọ si Rico Swavey, to gbajumọ fun kikopa ninu eto agbelewo BBNaija Double Wahala lọdun 2018, jade laye lẹyin ijamba ọkọ kan lọjọ Iṣẹgun.

Kọmisanna fun eto iroyin nipinlẹ Eko, Gbenga Omotosho, sọ fun BBC pe awọn yoo wadii iwa aibikita ati fifi ẹmi alaisan wewu, ti awọn nọọsi ileewosan ti wọn kọkọ gbe Rico Swavey lọ lẹyin ijamba ọkọ naa.

Ṣaaju ni fidio kan jade si ori ayelujara, eyi to ṣafihan iha ti awọn nọọsi kọ si oloogbe naa nileewosan ọhun.

Ninu fidio naa ti ko ju iṣẹju aaya ọgbọn lọ, a ri riko to joko lori aga kan to si han pe agbedemeji aye ati ọrun lo wa.

Ninu fidio baa bakan naa ni a ti gbọ ti nọọsi kan n kesi awọn akẹẹgbẹ rẹ pe ki wọn o jẹ ki awọn gbe Rico si ori ibusun ti wọn o fi gbe e wọ yaara itọju.

Koda, ẹnikan lara wọn n rẹrin bo ṣe n ya fidio naa, eyi to mu ki nọọsi miran ba a wi pe ko bojumu bo ṣe n ya fidio alaisan naa.

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo ti n bu ẹnu ẹtẹ lu fidio naa.

Kọmisanna eto iroyin, Gbenga Omotosho sọ pe ileewosan aladani ni ọrọ naa ti waye, ati pe awọn ti n ṣe iwadii lori iwakiwa naa.

O ni nkan akọkọ ti awọn yoo sẹ ni lati ti ileewosan naa pa, ti iwa buruku awọn nọọsi naa ba fi jẹ otitọ lẹyin iwadii.

Gbajúmọ̀ olùkópa nínú 'BBNaija Double Wahala' Rico Swavey ti kú

Rico Swavey

Oríṣun àwòrán, Others

Ọkan lara awọn gbajumọ ni Naijiria, to tun jẹ ẹni to ti kopa ri ninu eto agbelewo Big Brother Naija, Patrick Fakoya, ti gbogbo eeyan mọ si Rico Swavey ti ku.

Owurọ Ọjọbọ ni akẹẹgbẹ rẹ to tun jẹ ọrẹ, Tobi Bakare, kede iku rẹ.

Ọjọ Iṣẹgun ni Rico Swavey kagbako ninu ijamba ọkọ kan nilu Eko, eyi to mu ko wa ni agbede meji aye ati ọrun.

Ipo ilera rẹ mu ki awọn ọmọ Naijiria gbohun adura soke fun, lẹyin ti ikede jade loju opo ayelujara Twitter rẹ to ṣafihan ijamba naa.

Koda, aworan bo ṣe wa lori ibusun aisan, ti wọn si to oriṣiriṣi ẹrọ mọ ọ lara gba ori ayelujara.

Awọn akẹgbẹ rẹ paapa naa da eto ikowojọ silẹ fun.

Akẹgbẹ rẹ mi, Alex, ti oun naa jẹ ọrẹ Rico, naa ti sọrọ nipa iku rẹ. Oun lo kọkọ kede ijamba to ni, to si beere fun adura lori ilera rẹ.

Ẹwẹ, wọn ti kede ni oju opo Twitter rẹ bakan naa bayii pe o ti ku.

Fidio ọkọ ayọkẹlẹ Rico Swavey lẹyin ijamba naa

Botilẹ jẹ pe a ko le sọ nkan to ṣokunfa ijamba naa, tabi asiko to ṣẹlẹ, fidio bi ọkọ gbajugbaja naa sẹ ri ree lẹyin iṣẹlẹ ọhun.

Nkan to yẹ ki o mọ nipa Rico Swavey

Ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ni Patrick Fakoya, ti ọpọ mọ si Rico Swavey.

Akọrin takasufe ni, o si tun ni awọn iṣẹ mii to n ṣe ni agbo amuludun.

Bo tilẹ jẹ pe o ti wa ni agbo amuludun, o di ilumọọka lẹyin to kopa ninu eto agbelewo Big Brother Naija lọdun 2018.

O kẹkọọ jade ni fasiti Babcock, nibi to ti gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu imọ ofin.