Ọkùnrin ẹni ọdún 23 jí ara rẹ̀ gbé ní ìpínlẹ̀ Ogun lọ́nà àti gba ₦10m lọ́wọ́ òbí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Abimbola Oyeyemi
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi ṣikun ofin mu ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Edward Okache, lori ẹsun pe o ji ara rẹ gbe, lọna ati dibọn gba miliọnu mẹwaa naira lọwọ awọn obi rẹ.
Ọkunrin naa atawọn mẹrin mii; Asamoah Ernest, Isiah Uti, Ephraim Anyijor ati Charity Lukpata, ni ọwọ ọlọpaa tẹ.
Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi fi lede, o ni obinrin kan Comfort Okache lo fi ọrọ naa lọ ni agọ ọlọpaa kan to wa ni Mowe ki ọwọ to tẹ awọn afurasi naa.
Bi akara ṣe tu sepo
Gẹgẹ bii ohun to sọ, Comfort sọ fun awọn ọlọpaa pe aburo oun n rinrinajo bọ lati ilu Calabar siluu Eko, amọ wọn jii gbe nigba to de Mowe, ti awọn ajinigbe naa si n bere miliọnu mẹwaa naira owo itusilẹ lọwọ awọn ẹbi.
Oyeyemi ni kete ti ọrọ naa to awọn leti ni awọn akọṣẹmọṣẹ agbofinro tẹkọ leti lọ sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye lati doola ọdọkunrin ọhun.
O ni asiko ti wọn n wa inu igbo to yi agbegbe naa ka ni wọn ri ọdọkunrin naa ninu ile kan ti wọn ko tii kọ tan ti wọn de ọwọ ati ẹsẹ rẹ.
Oyeyemi tẹsiwaju pe wọn ri ọkunrin naa pẹlu Asamoah Ernest, to jẹ ọmọ orilẹ-ede Ghana, ati Isiah Uti, nibi ti wọn de apa ati ẹsẹ rẹ mọ.
Wọn fi ṣikun ofin mu awọn afurasi ti wọn ba pẹlu rẹ, wọn si doola rẹ.
Oyeyemi ni “Amọ nigba ti wọn yoo fi de agọ ọlọpaa, awọn afurasi mejeji ti a mu sọ pe ọkunrin naa funra rẹ lo ki ni awọn ji oun gbe lọna ati gba owo lọwọ awọn obi rẹ, eyii ti yoo fi ṣowo lori ayelujara.”
Wọn tun jẹwọ pe ọkunrin ọhun lo mu awọn mọ Ephraim Anyijor ati Charity Lukpata ti wọn ji gbe, Ephraim ati Charity si ti jẹwọ pe lootọ ni.
Oyeyemi pari ọrọ rẹ pe awọn yoo dari awọn afurasi naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣe iwadii iwa ijinigbe fun iwadii nin kikun.














