N kò mọ ohunkohun nípa oyè ti wọn fí Auxillary jẹ - Olubadan

Aworan Olubadan ati Auxillary

Olubadan ti ilẹ Ibadan, Oba Lekan Balogun, ti tako iroyin to gbode pe oun lo fi alaga igbimọ to n mojuto ibudokọ n'ipinlẹ Ọyọ, 'Park Management System (PMS)', Alhaji Lamidi Mukaila, ti ọpọ eeyan mọ si ‘Auxillary' jẹ oye.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi ṣọwọ si awọn oniroyin lati aafin Olubadan, Ọba alade naa ṣe apejuwe irufẹ iroyin bẹẹ gẹgẹ bii nnkan to ni ọwọ satani ninu.

L'ọjọ Iṣẹgun ni Auxillary jẹ oye Aare Ajagunla Kiriji ti ilẹ Yoruba nibi ayẹyẹ kan ti o waye ni gbọngan nla Mapo nilu Ibadan.

Atẹjade ti oluranlọwọ pataki fun Olubadan lori eto igbohunsafẹfẹ, Oladele Ogunsola buwọlu ṣe alaye wi pe yatọ si bi iroyin naa ṣe jẹ nnkan to bani lorukọjẹ, o ni, "o jẹ nnkan iyalẹnu ati idẹyẹsini gbaa, bẹẹ sini o jẹ nnkan ti o n kọnilominu lori bi ẹnikan yoo ṣe dede bẹrẹ sini gbe iroyin ofege ti o ti ọrun apaadi jade wa kiri".

Atẹjade naa ṣe alaye wi pe bi awọn ara ilu ṣe gbọ iroyin ifinijoye naa ni awọn to n bẹ laafin ṣe gbọọ,

O fi ibeere kun wi pe bawo ni ariwo orukọ Olubadan yoo ṣe wa di nnkan ti awọn eeyan n mu bọ ẹnu lori ohun ti ko bojumu ti Olubadan ko mọ ohunkohun nipa rẹ?

Botilẹ jẹ wi pe iroyin kan ti n ja ranyinranyin tẹlẹri wi pe alaga PMS naa ni ibatan pẹlu idile Aliwo nibi ti Olubadan ti jade wa, atẹjade naa ni ko si ohunkohun ti o da oun ati aafin Olubadan pọ de ibi ti yoo ti jẹ oye.

Atẹjade naa ṣe alaye siwaju sii wi pe ẹẹkan ṣoṣo ti Olubadan ri Auxillary laarin ọdun kan sẹyin naa ni lori tẹlifisan.

"Njẹ o wa ṣeeṣe ki o di oloye labẹ Olubadan lai ba Ọba alade naa sọrọ laarin ọdun kan tabi ju bẹẹ lọ?".