Ìdí mẹ́rin tí sísùn láì wọ aṣọ fi dára fún ìlera rẹ

Ọkunrin to n sun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ eeyan lo ma n wọ aṣọ oriṣiriṣi bii kaba, ẹwu ati ṣokoto, awọtẹlẹ, ati awọn aṣọ mii nigba ti wọn ba fẹ sun ni alẹ.

Oriṣiriṣi nkan lo n mu awọn eeyan wọ aṣọ sun, boya nitori ooru, otutu, ẹfọn, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣugbọn njẹ o mọ pe sisun ni ihoho ni anfaani fun ọ?

Lootọ ni oorun sisun funra rẹ ni ọpọlọpọ anfaani fun ilera eniyan, amọ ipo ti eeyan sun naa ni nkan ṣe lara.

Bo tilẹ jẹ pe awọn dokita oniṣegun oyinbo ko tii ṣe iwadii ijinlẹ kankan to fihan pe sisun ni ihoho dara ju wiwọ aṣọ sun, awọn onimọ nipa bi agọ ara ṣe n ṣiṣẹ sọ pe o dara ki eeyan sun lai wọ aṣọ.

O ma n mu adinku ba ooru to le di oorun sisun lọwọ

Gbigba atẹgun si ara ni ọpọ iwulo, paapaa ni asiko ooru.

Onimọ ilera sọ pe ti atẹgun ba wọ ara, yoo sọ fun ara pe asiko isinmi ti to. Sisun ni ihoho yoo mu ki ara rẹ lelẹ, ko ni si ara gbigbona, o si tun le mu ki oorun tete kun ọ.

Bakan naa ni waa ni anfaani lati sun fun ọpọlọpọ wakati.

Obinrin to bọ ara silẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọ ara to ji pepe

Ti o ba n sun ni ihoho, yatọ si pe waa le sun daada, o tun ni anfaani to n ṣe fun bi awọ ara rẹ yoo ṣe ri.

Iwadii kan fihan pe sisun oorun aladun ma n fun awọ ara ni ilera to peye, ti yoo si mu ko jọ̀lọ̀, niwọn igba ti oorun sisun ni ihoho n ṣe anfaani , o tumọ si pe o n ko ipa ninu ẹwa ara.

O n gbani lọwọ aarẹ ara ati ipaya

Onimọ Kris sọ pe lara ibeere ti awọn ma n beere lọwọ awọn to n ṣe wahala pupọ, ni pe aṣọ melo ni wọn ma n wọ sun.

A si ma n gba wọn ni imọran pe ki wọn ma wọ aṣọ sun mọ, nitori pe yoo mu ki ara wọn balẹ daadaa lasiko oorun.

Ibaṣepọ to dara pẹlu ololufẹ rẹ

Ti tọkọtaya ba sun sori ibusun kan naa, ti ara wọn si n kan ara, eyi yoo mu ki ọkan wọn ko fa sira wọn.

Paapaa ti wọn ba sun ni ihoho, ere ifẹ yoo ya wọn lati ṣe.

Ni akotan, Onimọ Kris sọ pe o dara pupọ lati ṣi ara silẹ ni alẹ lasiko oorun fun afẹfẹ, nitori pe lati owurọ ni a ti n wọ aṣọ si ara naa.