Àwọn ǹnkan tó le tètè ba kíndìnrín rẹ jẹ́ àti bí o ṣe le mọ̀ tó bá ti bàjẹ́

Oríṣun àwòrán, Others
Ninu awọn ẹya ara eniyan, kindinrin jẹ eleyi to se pataki fun igbayegbadun ati ẹmi gigun ẹda.
Meji ni kindinrin to n bẹ ninu ara, bẹẹ si ni mejeeji ko to ikuuku eeyan, amọ wọn ṣe pataki pupọ. Nitori naa a ko gbọdo fi alaafia wọn ṣere rara.
Ninu awọn nnkan ti kindinrin maa n se ni pe wọn jẹ bi asẹ to n yọ awọn idọti to le se ipalara fun ara wa kuro ninu ẹjẹ wa.
Bi a ba jẹun tabi taa mu omi, eleyi ti ko ni wulo fun ara, kindinrin lo maa n se isẹ lati yọ wọn kuro ki omi ati ounjẹ si wa ni wọntunwọnsi ninu ara wa.
Ti kindinrin ko ba sisẹ daadaa, ara naa ko ni wa nipo alaafia.
Aisan tabi aarun to ba si mu ki kindinrin kọ isẹ, ayaafi keeyan fi itọju gbe e ro pada nipa 'dialysis' tabi paarọ kindinrin naa nipasẹ isẹ abẹ ti oloyinbo n pe ni 'kidney transplant'.
Bi eniyan ko ba fẹ ipalara fun kindinrin rẹ, ki ni awọn nnkan to le ṣe tabi yago fun ki kindinrin baa le wa ni alaafia.
Nkan meje ree to le fa ipalara fun kindinrin wa ti a ko ba sọra fun wọn:
- Jijẹ ẹran pupọ ju
Ẹran jẹ nnkan to maa n fun ara lokun sugbọn njẹ o mọ pe ẹran jijẹ lapọju a maa se akoba fun kindinrin rẹ?
Iwadii kan ti awọn onimọ nipa kindinrin gbe jade ni orile-ede America da lori ibasepọ to wa nibi ki eeyan maa jẹ ẹran pupọ ati ewu to n se fun kindinrin.
Wọn ri i ninu iwadii wọn pe awọn to n jẹ ẹran pupọ wa ninu ewu lati ni ailera nipasẹ kikọsẹ kidinrin wọn.
Ẹran jijẹ pupọju maa n fa inira fun kindinrin lati le se afọmọ awọn idọti kan taa n pe ni urea.
Bi 'urea' yii ba pọju, kindinrin ko ni le lagbara lati se isẹ rẹ bo se yẹ.
Lati dena eleyi, wọn gbawa lamọran peka maa fi ẹja kun ẹranwa ni jijẹ, wara tabi ẹran adiyẹ.
- Ọti mumu lapọju.
Lawujọ ode oni, awọn eeyan a maa fi ọti mimu se faaji lọpọ igba .
Ọti jẹ nkankan to maa mu ki ọpọlọ se rẹsi bakan naa o le se akoba fun kindinrin nipa bi wọn se n se isẹ wọn.
Ẹjẹ riru wa lara awọn akoba ti ọti mimu le mu ba ara. Bẹẹ ẹni to ba n mu ọti le wa ninu ewu aisan itọ suga.
Mimu ọti ni iwọntun wọnsi ko le sakoba fun ara sugbọn bi eeyan ba n mu ọti, paapa ẹni ti wahala ba sẹsẹ n deba kindinrin rẹ, eleyi le sakoba fun ẹni naa.
- Iyọ jijẹ
Iyọ se apataki fun ara wa. Lara ohun to n se ni pe a maa mu ki ẹju riru lọ silẹ lara wa.
Omi to ba wa lara naa, omi a maa jẹ ko se deede iye tara nilo.
Sugbọn ti oun ti bo se se patraki to, bi eeyan ba n jẹ iyọ pupọ ju, akoba leleyi a maa mu ba kindinrin ẹda.
Iyọ iru eleyi ti ọpọ maa n jẹ ni idile kọọkan le sakoba bi eeyan ba n jẹ lọjọ pipẹ.
Pupọ ninu awọn ounjẹ igbalode tawọn eeyan n jẹ lode oni a maa ni iyọ pupọ ninu, to si n ṣe akoba fun kindinrin wọn.
- Caffeine
Caffeine jẹ eroja a mara ji pepe to maa n wa ninu awọn ọti ẹlẹrindodo tabi coffee, tea,cocoa ati chocolate ta maa n mu.
Kaakiri agbaye ni iye awọn eeyan to n mu ohun mimu to ni caffeine ninu pọ si. Ni America nikan, miliọnu 587 ikemu coffee lawọn eeyan maa n mu lọdọọdun.
T'oun ti pe ọpọ lo nifẹ si coffee, ipalara to n ṣe fun ara kii se kekere, paapa kindinrin.
Apọju rẹ bi i gbogbo nnkan ni ko da fun ara.
Bi eeyan ba n mu coffee tabi ohun mimu miran to ni caffeine ninu, onitọun ni lati fi iwọntun wọnsi si ki o ma se ipalara fun kindinrin rẹ.

Oríṣun àwòrán, others
- Ọti ẹlẹrindodo
Awọn ọti ẹlẹrindodo kan wa, to ni eroja kan taa n pe ni carbon dioxide.
Bi ọti ẹlẹrindodo ṣe maa n ru ko sẹyin carbon dioxide ti wọn de mọ inu igo tabi agolo rẹ.
Awọn ọti ẹlẹrindodo yi a maa dun lẹnu sugbọn akoba ti wọn n se fun ara pọ.
Wọn a maa mu alekun ba ẹjẹ riru wọn a si maa se idiwọ fun isẹ ti kidinrin le se.
Iwadii kan sọ pe ibasepọ wa laarin kiko aisan jẹjẹrẹ ẹdọ nitori suga to pọju ninu wọn.
Bi eeyan ba fẹ yago fun eleyi, ohun to le se ni pe ko fi awọn nnkan miran rọpo ọti ẹlẹrindodo yii.
Eeyan le maa mu awọn nnkan mimu taa fi ọsan, omi agbọn, ewe tea ati waini ṣe.
- Siga mimu
Iwadii kan ti ajọ to n mojuto kindinrin gbe jade sọ pe mimu siga a maa ṣokunfa iku eeyan kan laarin eeyan marun un to ba ku ni Amẹrika lọdọọdun.
Siga ẹyọkan pere ni kẹmika to fẹ ẹ to ẹgbẹrun marun un ti awọn mọkandinlaadọrin ninu rẹ si jẹ kẹmika to n se akoba fun ara.
Yatọ si pe awọn to n fa siga wa ninu ewu aisan jẹjẹrẹ ẹdọ fooro, ti aboonu,ati ẹnu, siga mimu a tun maa mu ki eeyan wa ninu ewu aisan kindinrin ati ti ọkan.
Bakan naa o le sakoba fun aboyun, ẹni to ni 'stroke' rọparọsẹ ati awọn to ni ailera kindinrin.
Awọn to n mu siga yi nikan kọ ni wọn wa ninu ewu, o lewu fun awọn to ba wa lẹgbẹ wọn ti wọn si n fa eefin sig simu.
Apọju oogun ara riro :
Ninu awọn nnkan to le se akoba fun kindinrin ni lilo oogun ara riro lapọju.
Bi awọn eeyan ṣe n lo oogun ara riro kan tabi omiran yi jẹ ohun to n kan awọn onimọ ilera lominu.
Aspirin, acetaminophen, ibuprofen atI naproxen sodium wọpọ ninu oogun ara riro ti awọn eeyan n lo.
Awọn oogun yii lakoba to n ṣe fun ara bi eeyan ko ba lo wọn niwọn. Koda bi eeyan ba lo wọn lalopẹ, akoba nla leleyi maa n jẹ fun kindinrin rẹ.
Awọn ti kindinrin ko ba ribi se afọmọ wọn, lo maa n pada wa di ailera fun kindinrin. Nitori naa, awọn oogun ara riro gbọdọ jẹ nnkan taa fi ẹsọ pẹlẹ lo.
Bawo lo ṣe le mọ ti kindinrin rẹ ba n ṣe aisan?
Gẹgẹ bi ajọ eto ilera ni orilẹede United Kingdom, NHS, ṣe sọ, o ṣoro lati mọ ti kindinrin ba bẹrẹ si ni i ṣe aisan ninu ara. Idi ni pe kii fi apẹẹrẹ kankan han to ba ṣẹṣẹ bẹrẹ, ayaafi ti eeyan ba lọ sileewosan fun ayẹwo.
NHS sọ pe o si ṣe e wosan pẹlu oogun ni ipele yii, amọ to ba ti di pe o ti ṣe aisan fun igba pipẹ, o le mu ki kindinrin naa pari iṣẹ patapata.
Ni ipele yii ni ẹni naa yoo ti nilo lati maa ṣe itọju ti wọn n pe ni dialysis tabi ipaarọ kindinrin naa.
Fun ẹni ti kindinrin rẹ ti bajẹ, awọn apẹẹrẹ yii ni yoo ma a ri:
- Ẹni naa yoo ma a ru, ko si ni le jẹun daadaa
- Ọrun ẹsẹ rẹ, ọwọ ati ẹsẹ yoo wu u – idi ni pe omi n darogun sinu kindinrin
- Eemi iru ẹni bẹẹ ko ni I ja geere
- Yoo ma a rẹ ẹni naa ni igba gbogbo
- Ẹjẹ le wa ninu ìtọ̀ rẹ
- Ẹni ti kindinrin rẹ n ṣe aisan yoo maa tọ̀ ju bo sẹ yẹ lọ, paapaa laarin our
- Ara yiyun, ori fifọ, ara riro, ati awọn nnkan mii.
Ṣugbọn o, ayẹwo nikan ni yoo sọ boya kindinrin lo n da ẹni naa laamu tabi bẹẹkọọ, nitori pe o le jẹ apẹẹrẹ irufẹ aisan tabi aarun miran.












