Ojú oorun ni Aláàfin ti jí mi pé wọ́n ti yan òun ní ọba, n kò mọ pé ìdílé ọba ló ti wá ká tó ṣe ìgbéyàwó - Ayaba Alaafin

Oríṣun àwòrán, Instagram/Alaafin Oyo
Ayaba Abiwummi Olajumoke Owoade, iyawo Alaafin ti ilu Oyo ni iwo yii ọdun mẹrin sẹyin, ti wọn ba sọ fun oun pe ọkọ oun yoo di Alaafin ti ilu Oyo, oun yoo ni ki iru eeyan ba lọ tun yẹwo.
Ayaba Owoade tun ni oun fun gan ko mọ pe idile ọba ni ọkọ ni ọkọ oun ti wa ṣaaju igbeyawo ati ninu igbeyawo wọn.
O sọ yii lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori irinajo Alaafin Akeem Owoade si ipo Alaafin ti ilu Oyo.
"Ọdun 2006, ninu oṣu keje ni a ṣe igbeyawo, ti a si ṣe iranti ogun kan le ookan ayẹyẹ igbeyawo wa ni ọdun yii"
Ayaba ni o le ni ogun ọdun bayii ti oun ti mọ Alaafin Owoade, ti oun si mọ Alaafin nipa ọrẹ-ọrẹ oun kan.
"Ni ọdun 2006, ninu oṣu keje ni a ṣe igbeyawo, ti a si ṣe iranti ogun kan le ookan ayẹyẹ igbeyawo wa ni ọdun yii.
"Mo ma n sọ fun awọn eeyan pe ti wọn ba sọ fun mi ni iwo yii ọdun mẹrin sẹyin pe ọkọ mii yoo di ọba, ma sọ fun wọn pe boya ẹni to ba n sọrọ iru ọrọ bẹẹ, boya ki wọn lọ tun yẹ wo.
"Mi o mọ pe idile ọba ni Kabiyesi ti wa rara koto di pe a pade, koda ninu igbeyawo gan, mi o mọ pe ninu idile Ọba ni Kabiyesi ti wa."
Ayaba Owoade ni oju oorun ni oun wa nigba ti Kabiyesi kesi oun pe ilu ti yan oun gẹgẹ bii Alaafin Oyo, ti jinijini siba oun lẹsẹkẹsẹ.
"Nigba ti iroyin jade, emi n sun lọwọ ni Kabiyesi ji mi lati oju oorun, koda mo sọ fun wọn pe ko da bi pe 'prank' lori ayelujara ni.
"Nigba ti wọn sọ fun mi, esi mi ni pe ki ni a wa ma ṣe bayii, nitori mo kan n tẹwọ ni pe ki lo tun wa kan, ki Kabyesi to fesi pe ile ti ya niyẹn."
Tí ẹ kò bá súnmọ́ Alaafin, ẹ kò lè mọ irú èèyàn tí wọ́n jẹ́
Ayaba ni ti eeyan ko ba sumọ Alaafin, yoo nira diẹ lati mọ irufẹ eeyan bẹ, to si ṣapejuwe Alaafin Oyo gẹgẹ bii olori to nifẹẹ gbogbo eeyan lọkan, ti oun si mọ pe ọpọlọpọ ọmọ Oyo Alaafin le fọwọ sọya pe otitọ ni ọrọ yii.
"Gbogbo awọn to n wa ba Alaafin Oyo, ni wọn ma n sọ fun pe bi ilu Oyo yoo ṣe tẹsiwaju ni o jẹ awọn logun bayii.
"Koda ni igba miiran, ti a n ba n bọ ninu ọkọ, ti a jade, ti awọn eeyan n dọbalẹ, ni Kabiyesi ma gbadura si Ọlọrun pe ko ran oun lọwọ lati mu ilọsiwaju ba Ilu Oyo.
"Ti ẹ ba sunmọ Kabiyesi, ẹ mọ pe Olori to fẹ Ọlọrun, to fẹran eniyan, ebi ati gbogbo eeyan ni Alaafin Oyo."







