Bàbá tí kìí tọ́jú ọmọ ní Oluwo, gbogbo Yorùbá, ẹ kìlọ̀ fún kó yé tàbùkù ipò tó wà - Olori Oluwo tẹ́lẹ̀ Chanel sọ̀rọ̀

Aworan Oluwo ti ilẹ Iwo, Oba Akanbi ati Iyawo rẹ tẹlẹ, Olori Chanel

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Iyawo tẹlẹ fun Oluwo ti ilẹ Iwo, Olori Chanel Chin ti wọgile gbogbo ẹsun ti Oba Abdulrasheed Akanbi fi kan Ooni ti ilẹ Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi Ojaja II pe o n peto gbero lati gba ẹmi rẹ.

Ninu atẹjade ti Olori naa fi lede soju opo Instagram, Olori Chanel ṣapejuwe gbogbo ohun to jabọ lẹnu Oluwo gẹgẹ irọ lati si ọpọ lọna ati lati tabuku si ipo ladelade ni ilẹ Yoruba.

O tẹnumọ pe Ooni ti ile ife kọ lo mu oun mọ Oluwo tabi ni ọwọ ninu ajọsepọ wọn.

"Fun alaye ni kikun, Ọba alade kan ni ilu Eko fi mi mọ Ọgbẹni Akanbi, ki ṣe Ooni ile ife. Ti Ọba alade yii ko si mu mọ Ọgbẹni Akanbi lati ṣe ijamba kankan fun," o tan imọlẹ si.

"$500 ni owo akọkọ ti Oduduwa, ọmọ Oluwo, yoo gba lọwọ rẹ lati igba ti a ti kuro ni Aafin"

Olori Chanel se iranti awọn asiko rẹ ni aafin Oluwo gẹgẹ bii Olori,to si tun fẹsun kan Ọba Akanbi pe ko si ninu aye ọmọ wọn, fun o le ni ọdun marun un.

"Ọgbẹni Akanbi wa si ilu Canada ni Oṣu kẹjọ ọdun yii, to si kọ lati tọwọbọ iwe irinajo ṣugbọn o fi owo toto $500 silẹ, owo akọkọ ti ọmọ rẹ Oduduwa yoo gba lọwọ rẹ lati igba ti a ti kuro ni Aafin," o ṣalaye.

Olori Chanel ni oun nikan ni oun ṣe itọju ọmọ ti o bi fun Ọba Akanbi.

Ẹyin Ọba alade ilẹ Yoruba, ẹ ba Oluwo sọrọ ko ye tabuku ipo ọba to di mu

Olori Chanel tun kan si awọn igbimọ lọbalọba ni ilẹ Yoruba pe ki wọn kesi Oluwo ko ye tabuku si ipo to di mu.

"Mo n rọ gbogbo araalu pe ki wọgile irọ ti wọn n pa mọ Ooni ti ile ife, olori lọbalọba akọkọ," o fikun.

Olori Chanel ni eyi ni ọrọ ikẹyin ti oun yoo sọ nipa ọrọ yii, to fidi ifẹ ati ibọwọ rẹ han si ilẸ Yoruba,

Iwe ti Olori Chanel fi soju opo rẹ.

Oríṣun àwòrán, Instagram

Oluwo figbe bọnu pé Ooni dẹ aya òun àná láti pa òun, àwọn lọ́balọ́ba l‘Osun fún ní gbèdéke pé kó kó ẹ̀rí kalẹ̀ bíbẹ́ẹ̀kọ́...

Ooni Enitan Adeyeye Ogunwusi wọ aṣọ funfun pẹlu awọ ẹkun lara àti Oluwo ti Iwo, Oba Abdulrasheed Adewale Akanbi wọ aṣọ funfun pẹlu ilẹkẹ lọrun

Oríṣun àwòrán, BBC/Oba Abdulrasheed Adewale/Facebook

Àwọn lọ́balọ́ba kan ní ìpínlẹ̀ Osun ti fún Oluwo ti ìlú Iwo, Oba Abdulrasheed Adewale Akanbi ní gbèdéke ọjọ́ mọ́kànlélógún láti fìdí àwọn ẹ̀sùn tó fi kan Ooni ile Ife, Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi múlẹ̀ ní àgọ́ ọlọ́pàá.

Nígbà tó ń bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹta, oṣù Kẹwàá, ọdún 2025, Salu ti ilu Edunabon, Ọba Adesoji Kehinde sọ pé ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni Oluwo ti sọ sẹ́yìn tí àwọn kìí kà á kún rárá.

Àmọ́ tó ní ẹ̀sùn tí Oluwo ṣẹ̀ṣẹ̀ fi Ooni lásìkò yìí lágbára púpọ̀ ju nǹkan tí àwọn lè fọwọ́ lẹ́ràn láti máa wò lọ.

Ọba Adesoji ní èyí ló mú àwọn Oba Origbo méje fi ẹnu kò láti fún Oluwo ní gbèdéke ọjọ́ mọ́kànlélógún láti kọ̀wé ẹ̀sùn ránṣẹ́ sí ọ̀gá ọlọ́pàá Nàìjíríà láti lọ fi ẹjọ́ Ooni sùn ní ìlànà tó tọ́ dípò bí ó ṣe gbe wá sórí ayélujára.

"Kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Oluwo ń fa wàhálà pẹ̀lú àwọn Ọba alayé bíi tirẹ̀"

Ó ní tí Oluwo kò bá ṣe nǹkan tí àwọn sọ yìí tí gbèdéke ọjọ́ náà bá fi pé àwọn máa pè é lẹ́jọ́ fẹ́sùn bíba orúkọ Ooni jẹ́.

"Tí Oluwo kò bá fi ẹ̀sùn rẹ̀ ránṣẹ́ sí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tí gbèdéke ọjọ́ mọ́kànlélógún fi pé, a máa pe Oluwo lẹ́jọ́ fún ẹ̀sùn ìbánilórúkọjẹ́ àti títàbùkù oyè Ooni."

Nígbà tó ń dáhùn sí ìbéèrè lórí àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n ti gbé láti parí aáwọ̀ tó ń wáyé láàárín Ooni àti Oluwo, Oba Adesoji sọ pé kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Oluwo ti máa ń fa wàhálà pẹ̀lú àwọn Ọba alayé bíi tirẹ̀.

Ó fi kun pé ṣáájú ni Ooni ti fòfin de Oluwo láti má kópa níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ Osun fún oṣù mẹ́fà nítorí àwọn ìwà àìtọ́ kan tó hù sáwọn Ọba kan.

Ó ní èyí ni kò jẹ́ kí àwọn gbé ìgbìmọ̀ kankan dìde láti parí aáwọ̀ náà, tí àwọn sì rò pé ọwọ́ òfin ni àwọn fi máa tò ó.

Kí ni Oluwo sọ tí wọ́n fi fún ní gbèdéke ọjọ mọkanlelokun?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọgbọ́n ọjọ́ oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2025 ni Oluwo ti Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi gbé fídíò kan jáde lórí ìkànnì ayélujára Facebook àti Instagram rẹ̀.

Nínú fídíò náà ni Oluwo ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan, tó sì fẹ̀sùn kan Ooni pé ó gbìyànjú láti dá ẹ̀mí òun légbodò.

Oluwo ní òun gbé fídíò náà jáde láti jẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà mọ ìdí tí òun fi máa ń sọ̀rọ̀ nípa Ooni ní gbogbo ìgbà.

Ó ní Ooni ń wá ìṣubú òun, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni òun ṣe ìrànwọ́ bí ó ṣe di Ooni Ilé Ife nígbà tó fẹ́ jọba.

Ó fẹ́sùn kàn pé Ooni mọ̀ọ́mọ̀ gbé obìnrin fún òun láti fẹ́ lójúnà àti lè máa mọ gbogbo nǹkan tó ń lọ nípa òun.

"Nígbà tó wà ní ilé mi, wọ́n máa ń bá a sọ̀rọ̀ nípa mi, tí wọ́n sì fi dẹ pàkúté fún mi pẹ̀lú fídíò àtàwọn nǹkan míì. Ó máa ma bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi láti lọ sọ fún wọn.

"Ọdún mẹ́ta ló lò nílé mi, tó sì bí ọmọ kan fún mi tí mi ò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé bóyá èmi gan ni m oni ọmọ náà. Mo máa nílò láti ṣe àyẹ̀wò DNA láti mọ̀ bóyá èmi ni m oni ọmọ náà.

"Ẹ̀ẹmèjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló fún mi ní májèlé jẹ. wọ́n gbìyànjú láti ran àwọn agbanipa sí mi, wọ́n gbìyànjú láti fi àwọn òrìṣà pa mí àmọ́ wọn kò ṣe àṣeyọrí."

Oluwo ní lẹ́yìn tí àwọn àṣìrí náà tú sí òun lọ́wọ́ ni òun lé ìyàwó náà jáde, tó si jẹ́ pé Ooni ló gbà á sílé lẹ́yìn tí òun le kúró tán.

Bákan náà ló tún fẹ̀sùn kàn pé Ooni ló gba ilé fún ìyàwó òun tẹ́lẹ̀ rí náà àti pé òun rí wọn papọ̀ ní ilé ìtura tí òun kò ní dárúkọ.

Ó tẹ̀síwájú pé àwọn èèyàn máa ń bú òun pé òun ń sọ̀rọ̀ jù ṣùgbọ́n "tó bá jẹ́ pé ìwọ ni wọ́n gbé obìnrin sí ilé rẹ láti pa ọ́ ṣé o ò ní sọ̀rọ̀?

Ó wòye pé ìjà tó ń wáyé láàárín òun àti Ooni kò lè parí nítorí nǹkan tó wà láàárín àwọn ju ohun tí àwọn èèyàn ń rí lọ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post