Ìtàn tó rọ̀ mọ́ bí 'Coffee' mímu ṣe bẹ̀rẹ̀, àáfààní àti ipa rẹ̀ nínú àgọ́ ara
Aimọye biliọnu eeyan lo n mu ife Kọfi kan jakejado agbaye eyi ti yoo mu wọn ji pepe lati sisẹ oojọ.
Ife kọfi yii kan si ni ọkẹ aimọye ni agbaye fi maa n ta ọpọlọ wọn ji pepe ni owurọ.
Awọn eeyan yii ko ro ipa ti ife Kọfi kan le se fun agọ ara wọn.
Ninu iroyin yiic, BBC se iwadii nipa mimu ife kọfi kan, ohun ti eroja Kafiini to wa ninu Kọfi n se ninu agọ ara ẹda.
Bakan naa ni a tun wo ipa ti mimu ọpọ ife Kọfi to ni eroja Kafiini ninu le ni lori agọ ara ti a ba n mu Kfi ni amuju lojumọ.
Eroja inu kọfi ni 'cafffeine', ògùn tí wọ́n fi ń ta ọpọlọ jí, tí wọ́n ń mú jùlọ ní àgbáyé
'cafffeine' to wa ninu Kofi ni igbagbọ wá pé ohun ni oògùn tí wọ́n fi ń ta ọpọlọ jí, tí wọ́n ń mú jùlọ ní àgbáyé
Jakejado agbaye ni wọn ti n mu bii miliọnu mẹjọ ife Kọfi lojumọ, o si le ni ẹgbẹrun kan abọ ọdun ti wọn ti n mu eroja Kọfi yika agbaye.
Awọn kan sì máa ń sọ nípa ipa ń kó lórí imisi to ń máa ń fún wọn èyí tó mú ayé wa bó ṣe wà lónìí
Eroja gbogi ninu kọfi ni 'cafffeine', èyí tí igbabọ wá pé ohun ni oògùn tí wọ́n fi ń ta ọpọlọ jí tí wọ́n ń mú jùlọ ní àgbáyé
Ibo gan wa ni kọfi ti ṣe wa ati pe ki ni lọ máa ń ṣe fun wa ni igba ti a ba muu?

Itan wo lo rọ mọ sise Kọfi mimu ati bo se di gbajugbaja?
Láti ara èso ọgbin Coffea arabica tí orísun jẹ Ethiopia ni wọ́n ti yọ kọfi
Itan kan sọ pe darandaran kan ni to n jẹ Kaldi ni sẹnturiKọkàndínlógún rí pé awọn aguntan rẹ máa ń jí pepe lẹyin ti wọn ba jẹ eso coffee, loun naa wa jẹ diẹ ninu rẹ.
Akọsilẹ itan tọka sawọn Sufis tilẹ Yemen pe awọn ni sun eso kọfi to fi di nnkan ti a mọ si kọfi lonii.
Ni sẹnturi Kẹẹ̀dógún ni wọn bẹ̀rẹ̀ si ni kọ àwọn ile iṣẹ kọfi ni Ottoman ko to maa tan wọ ilẹ Yuroopu lawọn sẹnturi to tẹle
Awọn eeyan bẹrẹ si ni sọ awọŋ ile kọfi yii di ibi ti wọn ti n jiroro ọrọ nipa oko-owo, ọ̀rọ̀ òṣèlú ati ohun tuntun.
Onimo kan – Jurgen Habermas gan sọ pe lai si kọfi, o ṣeéṣe kó má sì í ìmọ̀ àti òye to bayii
Awọn ọjọgbọn bii Kant and Voltaire –tí wọ́n ní wọ́n máa ń tó ife kọfi to to mejilelaadọrin lójúmọ́ bẹrẹ yẹ bí ìjọ aguda ṣe ń tú ilé ayé si.
Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ si ni ṣàgbéyẹ̀wò ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé ilé ayé le ni ìtumọ̀ lọ́nà míì.
Aye ọlaju yii ti a n sọ mu ayipada ba agbaye gẹgẹ bii a ṣe mọ ọ si
O fa gbigba ijọba lọwọ awọn oriade, idagbasoke ìṣèjọba àwaarawa ati awọn ìwádìí nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì.
Kọfi naa kopa ninu karakata owo ẹru
Awọn eeyan Faranse lo ẹru lati ilẹ Afrika lati ṣíṣe oko ni Haiti, nígbà tó sì fi máa di ọdún 1800, Brazil ti n pese idà kan nínú ìdá mẹ́ta kọfi tí wọ́n ń mú ní àgbáyé nípasẹ̀ lilo àwọn ẹrú ilé Africa.
Awọn kan ti ẹ tún gbàgbọ́ pé o tún mú agbega bá ìlànà ìṣèjọba capitalism.

N jẹ kọfi mu igbasoke ba iṣejọba bamubamu ni mo yo ti a mọ si capitalism?
Awọn ileeṣẹ bẹrẹ si ni ma fun awọn oṣiṣẹ wọn ni kọfi, ti wọn si tun gba isinmi láti lọ mu kọfi.
Eyi kii ṣe nitori ìfẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ bíkòṣe láti mu kí wọ́n le ṣiṣẹ́ dáadáa
Wọn n gbiyanju lati se moriya fun awọn oṣiṣẹ nidi iṣẹ wọn.
Lode oni, kò din ni bílíọ̀nù meji ife kọfi ti wọn n mulójúmọ́káàkiri àgbáyé
O to aadọrun bílíọ̀nù dọla ti ẹ̀ka náà ń pa ni ọdọọdún
Ati pe, ju bẹẹ lọ, o ti di nnǹkan bárakú fún ọ̀pọ̀ eeyan ni gbogbo ọjọ́ ayé won.
Kọfi mimu n kopa rere si agbelarugẹ ọrọ aje
Lode oni, kò din ni bílíọ̀nù meji ife kọfi ti wọn n mulójúmọ́káàkiri àgbáyé
O to aadọrun bílíọ̀nù dọla ti ẹ̀ka náà ń pa ni ọdọọdún
Ati pe, ju bẹẹ lọ, o ti di nnǹkan bárakú fún ọ̀pọ̀ eeyan ni gbogbo ọjọ́ ayé won.
Báwo ni ṣe ń nípa ni agọ ara?
Nigba ti kaffin ba wọ inu ẹya ara lo n lọ ounjẹ, inú ifun lo máa ń gba wọ inú ẹ̀jẹ̀.
Amọ eeyan kii ri ipa rẹ ayafi to ba ti n tọ awọn ẹya ara kan lọ.
Eyi ri bẹẹ nitori kafeinni awọn kẹmika kan ninu eyi to farajọ iru eyi ti ara eeyan maa n pese: adenosine
Kafein maa darapọ mọ awọn ẹya ara to maa n gba adenosine
O dabi kọkọrọ to n ṣi lẹkun ni.
Adenosine maa n mu adinku ba bi ọkan eeyan ṣe n ṣiṣẹ, o máa ń fa ki ara balẹ̀, tó sì lè mú kí ojú ẹni máa ṣù.

Eroja Kaffini to wa ninu Kọfi ma n fa ọpọ awọn ayipada ninu agọ ara
Iwadii ti fihan pe eroja kaffin ma n fa ọpọ awọn ayipada ninu agọ ara
Bi apẹẹrẹ, ifunpa eeyan le ga soke diẹ, paapaa ti mimu kọfi kii ba ṣe ohun ti eeyan maa n ṣe loorekoore.
Bakan naa lo ri fun iṣẹ ọpọlọ: kaffin maa n ṣe iranwọ fun ọpọlọ, bu adinku ba ebi, to si maa n jẹ ki eeyan ji pipe fun igba pipẹ.
Kafein le ni ipa rere lori bi ara eeyan ṣe maa n ya gaga si, kii jẹ ko rẹ eeyan, to si maa n mu ki ara ji pepe.
Ọpọ awọn elere idaraya maa n lo fun ijipepe. O le ṣiṣẹ laaarin iṣẹju mẹẹdogun si wakati meji.
Ago ara ma n yọ kaffin kuro lara laaarin wakati 5 si 10 lẹyin ti eeyan ba mu ṣugbọn ipa to maa n fi silẹ lara le pẹ ju bẹẹ lọ.
Ti o ba fẹ ki ipa ti kafiin siṣẹ to dara ni agọ ara rẹ daadaa, awọn onimọ sọ pe o dara ki o yago fun mimu kafein ni ọsan – ki ipa kọfi ti o ba maa mu ni owurọ ọjọ le ṣiṣẹ bo ṣe yẹ.
Kọfi mimu gba pẹlẹpẹlẹ ti eeyan ba fẹ mu-un
Fún awọn agbalagba, irinwo miligiraamu ni o pọ ju ti eeyan le mu – eyi to jẹ bii kọọpu mẹrin si marun-un
Mimu ju bẹẹ lọ le ṣokunfa awọn ailera bii airi oorun sun, ki inu maa dun eeyan, ori fifọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn ipa to lagbara bii giri le maa ṣe eeyan ti eeyan ba mu kọfi pupọ ju bi o ṣe yẹ lọ bii ki eeyan mu kọọpu mejila kọfi lojumọ.
Loootọ ni awọn iwọn yii yatọ lati eeyan kan si ẹlomiran: Bi ara ṣe le gba kafein yatọ sira.
Loootọ ni awọn iwọn yii yatọ lati eeyan kan si ẹlomiran: Bi ara ṣe le gba kafein yatọ sira
Awọn anfaani to wa ninu mimu Kọfi
Ṣugbọn ti eeyan ba mu ni iwọntunwọnsi, kọfi dara fun ilera rẹ
Bi apẹẹrẹ, o maa n mu adinku bi eeyan ṣe le ni aisan itọ suga, aisan ọkan, awọn aarun jẹjẹrẹ kan ati aisan Parkinson - gẹgẹ bi Dokita Mattias Henn, ti ile ẹkọ Harvard T.H.Chan school of Public Health ṣe sọ
Awọn anfani ilera ko so mọ kaffin nikan.
Kọfi ni awọn anfani mii to n pese bii chlorogenic acid, awọn eroja to le mu adinku ba nini awọn aisan kan.
Fun idi eyi, nigba mii ti o ba gba kọọpu kọfi mu, o ṣeeṣe ki o fi oju miiran wo o.






