Àyájọ́ ọjọ́ tó mọ́ jùlọ láyé fáwọn Jew di ọjọ́ ẹkún, ọkùnrin kan fi ọkọ kọlu ilé ìjọ̀sin wọn ní Manchester, fi ọ̀bẹ gún wọn, ẹ̀mí bọ́

Àkọlé fídíò, Àwọn agbófinró níbi ìkọlù Manchester
    • Author, Maia Davies
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Àwọn ọmọ Jew méjì kan ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní synagogue, Manchester nígbà tí ọkùnrin kan wa ọkọ̀ láti fi kọlu àwọn èèyàn tó sì tún ń fi ọ̀bẹ gún wọn.

Ní àyájọ́ Yom Kippur, tó jẹ́ ọjọ́ tí àwọn Jew gbà pé ó jẹ́ ọjọ́ tó mọ́ jùlọ láyé ni ìkọlù náà wáyé.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ń rí ìkọlù náà bíi ìgbéṣùmọ̀mí, tí wọ́n sì gbàgbọ́ pé ẹni tó wà nídìí ìkọlù ọ̀hún ni Jihad Al-Shamie.

Ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó sì ní orírun ilẹ̀ Syria.

Àwòrán afurasí kí ìkọlù náà tó wáyé ní agbègbè kan. Afurasí náà so nǹkan tó jọ àdó olóró mọ́ ìdí.

Báwo ni ìkọlù náà ṣe wáyé?

Èèyàn mẹ́ta ló farapa, tí wọ́n sì ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn lórí ìkọlù náà.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn gba ìpè láti Heaton Park Hebrew Congregation Synagogue ní nǹkan bíi mẹ́sàn-án àbọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́bọ̀ nípa ọkùnrin kan tó ń wa ọkọ̀ wọ àárín èrò, tó spì ń gún àwọn èèyàn lọ́bẹ.

Lẹ́yìn ìṣẹ̀jú méje ni àwọn ọlọ́pàá dé ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀ fún afurasí náà.

Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn olùjọ́sìn àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ni wọ́n wà ní synagogue lásìkò náà, tí wọ́n sì wà ní àhámọ́ títí tí ààbò tó péye wà ní agbègbè náà.

Shah, tó jẹ́ ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀, sọ pé òun ń wa ọkọ̀ kọjá lára synagogue nígbà tí òun rí ọkọ̀ kan sáré kọjá , tó sì lọ wa ọkọ̀ lọ bá àwọn èèyàn níbi tí wọ́n wà.

Àwòrán agbègbè Heaton Park Hebrew Congregation Synagogue ní àríwá Manchester.

Ó ní òun rí tí ọkùnrin náà sáré jáde nínú ọkọ̀, tó sì ń sáré ṣe ìkọlù sáwọn èèyàn pẹ̀lú ọ̀bẹ, bó se júwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà bí èyí tó burú púpọ̀.

Gareth Tonge tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ sọ fún BBC pé òun rí ọkùnrin kan tí ẹ̀jẹ̀ ń yọ lára rẹ̀ níbi tó wà nílẹ̀.

Tonge fi kun pé kò pẹ́ tí àwọn ọlọ́pàá dé ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọ́n ṣe ìkìlọ̀ fún afurasí náà àmọ́ tí kò dá wọn lóhùn èyí tó mú kí àwọn ọlọ́pàá yìnbọn bà á.

"Ó gbìyànjú láti dìde padà tí ọlọ́pàá sì tún yìnbọn fún-un ní ìgbà keì tí kò sì le dìde mọ́."

Mayor Manchester, Andy Burnham sọ pé àwọn ti paná ewu tó wáyé ní agbègbè náà ṣùgbọ́n tó rọ àwọn èèyàn láti jìnà sí àwọn ibi tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti fòfin dè.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn mẹ́ta ló farapa níbi ìkọlù náà – èèyàn kan tí wọ́n gún ní ọ̀bẹ, ẹnìkan tí afurasí fi ọkọ̀ kọlù àti ẹnìkan tó farapa nígbà tí àwọn ọlọ́pàá fẹ́ mú afurasí náà balẹ̀.

Àwọn èèyàn tí wọ́n ń wo ibi tí ọlọ́pàá ti gbégi dí

Oríṣun àwòrán, AFP

Àwòrán Heaton Park Hebrew Congregation Synagogue ní Middleton Road

Ta ni afurasí náà?

Ṣíṣe àyọ̀wò bóyá àdó olóró wà lára afurasí tí àwọn ọlọ́pàá yìnbọn pa.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn gbàgbọ́ pé afurasí náà ni Jihad Al-Shamie, ẹni ọdún márùndínlógójì, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ UK pẹ̀lú orírun Syria.

Ó wà ní ọmọdé ló wọ UK, tí wọ́n sì fún ni ìwé ọmọ ìlú orílẹ̀ èdè UK lọ́dún 2006 gẹ́gẹ́ bí ọmọdé.

Ọ̀gá àgbà GMP, Sir Stephen Watson sọ pé afurasí náà wọ aṣọ tó jọ bí ẹni pé ó ní àdó olóró lára àmọ́ tí wọ́n padà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé kò ní ipa kankan.

Ìwádìí ti ń lọ láti mọ̀ bóyá afurasí náà ti ní ìwà ọ̀daràn kan tẹ́lẹ̀.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn afurasí mẹ́ta míì ni ọwọ́ tún ti tẹ̀ lórí ìkọlù náà.

Àwọn òṣìṣẹ́ pàjáwìrì ń kó àwọn èèyàn tó wà ní synagogue kúrò

Oríṣun àwòrán, AFP

Kí ni Yom Kippur?

Àwọn èèyàn tó kó ara wọn ní ibi tí ìkọlù ti wáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn Jew tó wà ní agbègbè tí ìkọlù náà ti wáyé

Yom Kippur ni ọjọ́ tó mọ́ jùlọ níní kajọ́kaṣù àwọn Jew.

Ó jẹ́ àsìkò tí wọ́n máa ń gba ààwẹ̀ àti ṣe ìrúbọ sí Ọlọ́hun gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gbàgbọ́ pé àsìkò náà ló jẹ́ ìgbà tí Ọlọ́hun máa ń ṣe àṣẹ sí kàdárà àwọn èèyàn fún ọdún tó ń bọ̀.

Kìí sí iṣẹ́ lọ́jọ́ yìí, tó sì jẹ́ pe àdúrà nìkan ló wà fún.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí kìí lọ synagogue ni wọ́n máa ń lọ lọ́jọ́ yìí, tí ètò ààbò sì máa ń le si.

Olóòtú ìjọba UK, Sir Keir Starmer sọ pé wọ́n máa fi kún ètò ààbò tó wà káàkiri synagogue ní orílẹ̀ èdè náà lẹ́yìn ìkọlù yìí.

Ó ní àwọn máa ṣe ohun gbogbo tó yẹ láti mú kí àwọn èèyàn Jew wà lábẹ́ ààbò tó péye.

Rabbi Daniel Walker, wọ aṣọ funfun dúró láàárín àwọn ọlọ́pàá ní ìta synagogue

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dárúkọ àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti forúkọ àwọn èèyàn méjì tó bá ìkọlù náà léde.

Adrian Daulby, ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́ta àti Melvin Cravitz, ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin ni wọ́n ní ó pàdánù ẹ̀mí nínú ìkọlù náà.

Iléeṣẹ́ ní àwọn ti ń ṣe àtìlẹyìn fún àwọn ẹbi tí wọ́n pàdánù àwọn èèyàn wọn náà.

Ọ̀gá ọlọ́pàá Manchester, Det Ch Supt Lewis Hughes bá ẹbí Daulby àti Cravitz kẹ́dùn, tó sì ní àwọn òṣìṣẹ́ àwọn yóò máa kà sí wọn títí bí ìwádìí ṣe ń lọ lọ́wọ́.

Ó ní bí ó ṣe jẹ́ pé wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ́lẹ̀ ìlànà òfin, ọ̀gá ọlọ́pàá náà sọ pé àwọn yóò bọ̀wọ̀ fún àṣà láti ri pé àwọn tẹ̀lé ìfẹ́ àwọn èèyàn náà lórí àwọn òkú wọn.

Ní ọjọ́ ni wọ́n máa ṣàyẹ̀wò àwọn òkú náà gẹ́gẹ́ bí Home Office ṣ sọ.