Àwọn ọ̀dọ́ Gen-Z fọnmú ní Madagascar pẹ̀lú ìwọ́de, agbófinró pa olùwọ́de 18, 100 farapa, ààrẹ tú ìjọba rẹ̀ kà

Oríṣun àwòrán, EPA/Shutterstock
- Author, Natasha Booty
- Author, Jessica Rawnsley
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Aarẹ orilẹede Madagascar ni oun ti tu ile ka ninu ijọba rẹ lẹyin ti awọn ọdọ gunle iwọde tako bi ko ṣe si omi ati ina ni orilẹede naa.
"A mọ eyi, ti a si n tọrọ aforijin ti awọn igbimọ ijọba ba kuna lati ṣe iṣẹ ti a gbe fun wọn," Andry Rajoelina sọ lasiko to n ba awọn araalu sọ lọjọ Aje.
Iwọde awọn Gen-Z ni ọpọ awọn ọdọ kopa ninu rẹ, ti wọn si gba gbogbo titi kaakiri awọn ilu lorilẹede Madagascar lati ọjọbọ ọsẹ to kọja, ti wọn si n kọrin, "A fẹ wa gbe aye, ki se ka kan wa laye".
Oloye ajọ iṣokan agbaye bu ẹnu atẹlu bi awọn agbofinro ṣe kọlu awọn olufẹhonuhan, ti mejilelogun si padanu ẹmi, ti ọgọrun un mii si farapa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn eeyan ti awọn agbofinro ṣekupa, ni wọn ko ni nnkan ṣe pẹlu awọn oluwọde - UN
Minisita to n risi ọrọ oke okun ni Madagascar ti wọgile iye eeyan ti UN gbe sita pe o ba iṣẹlẹ naa lọ, ti wọn si fẹsun kan wọn pe wọn n gbe iroyin ofege kiri.
Iwọde naa kọkọ bẹrẹ ni olu ilu Antananarivo ṣaaju ko to tan si awọn ilu mẹjọ kaakiri orilẹede naa.
Ijọba kede ofin koni ile gbe ile ni Antananarivo lẹyin ti ọpọ rogbodiyan bẹ silẹ, ti awọn ọlọpaa si n yin tajutaju lati le tu awọn oluwọde ka.
Olori UNCHR, Volker Türk ni ohun iyalẹnu lo jẹ fun oun pẹlu nii awọn ọlọpaa ṣe kọlu araalu ati bi wọn ṣe na ọpọ oluwọde ati yinyin ibọn.
"Mo rọ awọn ọlọpaa pe ki wọn ya go fun nilo ohun ija fun awọn oluwọde, ki wọn si tu gbogbo awọn ti wọn fi si ahamọ silẹ ni kiakia," Turk sọ ninu atẹjade lọjọ Aje
Gẹgẹ bii UN ṣalaye, awọn eeyan to ba iṣẹlẹ naa ti awọn agbofinro ṣekupa ni wọn ko ni nnkan ṣe pẹlu awọn oluwọde.
Ni ọsẹ to kọja, Aarẹ Madagascar kede pe oun ti gba iṣẹ lọwọ minisita fun eto agbara lori ẹsun pe ko ṣe iṣẹ to yẹ ko ṣe daada ṣugbọn awọn oluwọde n beere pe ki awọn aarẹ ati awọn to n ba ṣe ijọba kọwe fipo silẹ.
Ọpọ awọn oluwọde yawọ titi lẹẹskansi lọjọ Aje.
"Ibinu araalu ye mi, ibanujẹ ati ohun ti wọn n la kọja lori bi ina ati omi se ge, eyi to fa wahala," Rajoelina sọ lasiko to n ba awọn araalu lori tẹlisfisan,Televiziona Malagasy.
O ni oun ti gba iṣẹ lọwọ Olootu ijọba, to si ni awọn to wa ni ipo ijọba bayii ni wọn kan wa nibi titi ijọba tuntun yoo wa fun araalu.
Rajoelina ni oun ṣetan lati ba awọn ọdọ ilu sọrọ
Orilẹede Madagascar ti n kọju ọpọ ipenija lati gba ti wọn ti gba ominira lọdun 1960, to fi mọ iwọde to bẹ silẹ lọdun 2009 to pe fun iyọkuro aarẹ nigba kan ri Marc Ravalomanana fi ipo silẹ Rajoelina lati bọ sipo.















