Ìdí rèé tó fi ṣeéṣe kí ìbejì ní bàbá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Àkọlé fídíò, Fraternal Twins
Ìdí rèé tó fi ṣeéṣe kí ìbejì ní bàbá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Àìrìn jìnà ni àìrí abuké ọ̀kẹ́rẹ́, a ò sí rí irú eléyìí rí a fi máa ń dẹrù ba ọlọ́rọ̀ ni.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ló ń ṣẹlẹ̀ lókè eèpẹ̀ èyí tí ó máa ń ṣeni ní kàyééfì nígbà tí èèyàn bá gbọ́ wọn.

Lára rẹ̀ ni èyí tí ìwádìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ báyìí pé ó ṣeéṣe kí àwọn ìbejì tí a bí lọ́jọ́ kan náà ní bàbá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Èyí ni àwọn olóyìnbó ń pè ní "heteropaternal superfecundation".

Awọn ibeji jojolo ti wọn fi asọ ankara alawọ eweko we, wọn tẹ wọn si ori ibusun, awọn ibeji naa wọ asọ alawọ pupa, ti a si fi nnkan bo oju wọn tori ọmọ kekere ni wọn.

Ìwádìí fi hàn pé irú nǹkan báyìí kò wọ́pọ̀ àmọ́ ó máa ń wáyé nígbà tí obìnrin bá yé ẹyìn méjì lẹ́ẹ̀kan náà èyí tí wọ́n ń pè ní "hyperovulation" .

Ti iru obinrin bẹẹ si sunmọ ọkunrin meji ọtọọtọ ti atọ ara wọn ṣiṣẹ daadaa, laaarin wakati mejila si mẹrinlelogun sira wọn.

Loju opo ayelujara McGill University, wọn fidi rẹ mulẹ pe, ibeji mọkandinlogun pere kaakiri agbaye ni iroyin sọ pe baba ọtọọtọ lo bi wọn.

Sugbọn ṣa, iru awọn ibeji bayii kii ni afijọ rara, awọn ni oloyinbo n pe ni fraternal twins.

Lẹyin ti wọn ba bi iru ibeji bayii, ayẹwo DNA nikan lo le e fi han pe baba ọtọọtọ lo bi awọn ọmọ mejeeji.