Ìjọba Amẹ́ríkà dáwọ́ iṣẹ́ dúró - wo ipa rẹ̀ lórí ọmọ Nàíjíríà àti bí ó ṣe kàn ọ́

Àwòrán àsíá Amẹ́ríkà ní iwájú ilé ìjọba Amẹ́ríkà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti gbé ilẹ̀kùn rẹ̀ tì pa lẹ́yìn ọdún méje tí irúfẹ́ ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ ti wáyé.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn aṣòfin àti Ààrẹ Donald Trump kò fẹnukò lórí àbá ìsúná kan.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ètò ìṣèjọba ni kò ní jẹ́ ṣíṣe ní gbogbo oṣù Kẹwàá yìí, tó sì tún lè tẹ̀síwájú èyí tí yóò ṣe àkóbá fún ọ̀pọ̀ ọmọ Amẹ́ríkà.

Bákan náà bí ìjọba ṣe da iṣẹ́ sílẹ̀ náà tún le mú kí ìdá ogójì àwọn òṣìṣẹ́ – èyí tó tó bíi ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rin – le má rì í owó oṣù gbà.

Àwọn páàkì àti ibí ìnàjú ni ó ṣeéṣe kí wọ́n wà ní títìpa látàrí ìgbésẹ̀ yìí.

Bí ìjọba se gbé iṣẹ́ sílẹ̀ èyí tó ti wayé sẹ́yìn, ló ṣokùnfà kí àwọn ètò ìrìnnà òfurufú ní ìjákulẹ̀ nítorí àìsí àwọn òṣìṣẹ́ tó tó.

Kí ni ó jẹ́ kí ìjọba da iṣẹ́ sílẹ̀ ní Amẹ́ríkà?

Ìgbésẹ̀ ìjọba Amẹ́ríkà láti da iṣẹ́ sílẹ̀ bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn aṣòfin àti ààrẹ Donald Trump kọ̀ láti fẹnukò lórí àbá ìsúná lórí ètò ìlera kan èyí tó ti mú kí àwọn iléesẹ́ àti àjọ ìjọba kan wà ní títìpa.

Aáwọ̀ láàárín ààrẹ àti àtàwọn aṣòfin bẹ̀rẹ̀ látàrí bí àwọn aṣòfin ẹgbẹ́ òṣèlú Democrat ń bèèrè fún owó láti ṣètò ìlera èyí tí àwọn aṣòfin ẹgbẹ́ Republican kò fọwọ́ sí.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ìjọba máa ń dáwọ́ iṣẹ́ dúró ní Amẹ́ríkà nígbà tí àwọn aṣòfin àti ààrẹ kò bá fẹnukò órí ọ̀nà láti ná owó èyí tó máa ń mú kí àwọn iléeṣẹ́ àti àjọ tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀ wà ní títìpa títí tí wọ́n fi máa fẹnukò.

Ààrẹ Trump nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìgbésẹ̀ náà ní yóò ṣe ìrànwọ́ fún òun láti yọ àwọn ètò kan tó jẹ́ pé ẹgbẹ́ Democrat gbájúmọ́.

Gbígbé ètò ìjọba tì pa yìí kò ní kan àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ tó ṣe kókó bíi àwọn ológun, àwọn tó ń ṣètò àwùjọ, àwọn tó ń rí sí ọ̀rọ̀ oúnjẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Bákan náà ni àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ kan tí iye wọn fẹ́ ẹ̀ tó 800,000 yóò máa lọ sílé lójúmọ́ láì gba owó títí tí wọ́n máa fi parí aáwọ̀ náà.

Ìgbà àkọ́kọ́ nìyìí tí irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò wáyé lẹ́yìn tí irú rẹ̀ wáyé lásìkò ìṣèjọba Trump ní sáà àkọ́kọ́ rẹ̀.

Àwọn aṣòfin máa ń kojú ìfaǹfà lórí owó níná ṣùgbọ́n tí wọ́n máa ń yanjú rẹ̀ kó tó di pé ó máa ń di ohun tí yóò di ìfaǹfà.

Láàárín ọdún 1976 sí àsìkò yìí, ìgbà mọ́kànlélógún ni ìjọba àpapọ̀ ti dáwọ́ iṣẹ́ dúró nígbà tí ètò ìsúná ìgbàlódé yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

Ètò gbígba físà yóò tẹ̀síwájú ní Nàíjíríà

Iléeṣẹ́ ìjọba Amẹ́ríkà tó wà ní Nàìjíríà ti wá sọ àrídájú rẹ̀ pé ètò físà gbígbà àti ṣíṣètò ìwé ìrìnnà kò ní dáwọ́ dúró bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba Amẹ́ríkà kò ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ yìí.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ náà fi sójú òpó X rẹ̀ lọ́jọ́rú sọ pé àwọn kò ní máa fi ìròyìn sójú òpó náà déédéé bíi ti àtẹ̀yìnwá títí tí ìjọba Amẹ́ríkà fi máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà àyàfi ìròyìn tó bá nííṣe pẹ̀lú ààbò àbí ohun tó bá jẹ́ kíákíá.

Àmọ́ wọ́n ní èyí kò ní dáwọn dúró láti máa ṣe iṣẹ́ gbígba físà àti ìwé ìrìnnà tí àwọn ti ń ṣe tẹ́lẹ̀.

Ìkéde yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kọminú pé bóyá bí wọ́n ṣe da iṣẹ́ sílẹ̀ náà máa ṣe àkóbá fún ètò gbígba físà, ìrìnàjò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ sí Amẹ́ríkà àtàwọn nǹkan míì.