Ìtàn ayé àwọn àgbà méje tó léwájú ìgbòmìnira Nàìjíríà àti ìgbìnyànjú wọn

Oloogbe Ahmadu Bello, Oloogbe Obafemi Awolowo ati Oloogbe Nnamdi Azikiwe

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Àjèjé ọwọ kan ko gbe ẹru d’ori, igbiyanju, ifọwọsowọpọ ọpọ eeyan a si maa mu nnkan rọrun ju adaṣe ẹnikan ṣoṣo lọ.

Awọn eeyan pọ ti wọn kopa ninu gbigba ominira Naijiria lọwọ awọn oyinbo amunisin.

Àmọ́ BBC News Yorùbá ṣe àkójọpọ̀ àwọn èèyàn meje pataki ninu àwọn tó jà fún òmìnira Nàìjíríà àti atupalẹ igbiyanju wọn ninu iroyin yii.

1)Oloye Obafemi Awolowo (6 March 1909 - 9 May 1987)

Oloye Obafemi Jeremiah Oyeniyi Awolowo, jẹ olufẹ Naijiria ati olori to ko iko pataki ki orilẹede yii le bọ lọwọ iṣakoso oyinbo.

Ilu Ikenne, nipinle Ogun ni wọn ti bi i lọjọ kẹfa, oṣu kẹta ọdun 1909.

Oloogbe Obafemi Awolowo lo joye Olootu ijọba ilẹ Yoruba akọkọ, bẹẹ lo si tun jẹ kọmiṣanna eto iṣuna fun ijọba apapọ nigba kan .

Lasiko ogun abẹle ni Obafemi di Igbakeji aarẹ igbimọ apaṣẹ to n ri si bi ohun gbogbo ṣe n lọ.

Awolowo ni olori ẹgbẹ alatako ti i ṣe Action Group.

Loootọ ni ko ri ipo aarẹ Naijiria de ninu iṣejọba awarawa saa keji, ṣugbọn o gbajumọ kaakiri agbaye.

Ọjọ kẹsan-an, oṣu karun-un ọdun 1987 ni Oloye Obafemi Awolowo dagbere fun ile aye.

Aworan Awolowo ni wọn ya si ọgọrun-un kan naira (100 Naira) ilẹ wa.

Oloogbe Obafemi Awolowo

Oríṣun àwòrán, BETTMANN

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Obafemi Awolowo

(2) Funmilayo Ransome Kuti (25 October 1900 - 13 April 1978

Oloogbe Funmilayo Ransome-Kuti

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Funmilayo Ransome-Kuti

IFunmilayo Ransome Kuti nikan ni obinrin to wa lara awọn ajijagbara to ja fun ominira Naijiria.

Olukọ ni Funmilayo nileewe, oloṣelu ni nile, aja-fun-ẹtọ awọn obinrin ni, olórí si ni pẹlu nigba aye rẹ.

Funmilayo Ransom Kuti ni iya to bi gbajugbaja olorin Afro nni, Oloogbe Fela Anikulapo Kuti.

Funmilayo Kuti yii naa ni obinrin akọkọ to wa mọto ni Naijiria.

Wọn yan an si ipo olori nilana ibilẹ, nibi to ti jẹ aṣoju awujọ Yoruba.

Ilakaka Funmillayo Ransome Kuti ni ipa lori awọn ọmọ rẹ pẹlu, wọn jiya, paapaa lasiko ijọba ologun.

Ọjọ kẹtala, oṣu kẹrin ọdun 1978 ni Funmilayo Ransome Kuti jade laye.

Oloye Anthony Enahoro (22 July 1923 -15 December 2010)

Oloogbe Anthony Enahoro

Oríṣun àwòrán, Getty

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Anthony Enahoro

Ọkan lara awọn to lodi si ijọba amunisin pẹlu gbogbo ọkan wọn ni Oloye Anthony Eromosele Enahoro, nigba aye rẹ.

Baba naa nifẹẹ si ijọba awarawa to bẹẹ gẹẹ to fi jẹ pe oun ni ẹni akọkọ to kọkọ beere fun ominira Naijiria lọdun 1953.

Idi eyi ni wọn fi n pe e ni ‘Baba Naijiria.’

Oloye Enahoro di olootu iwe iroyin ti Oloogbe Nnamdi Azikiwe n ṣe nigba naa, iyẹn Southern Nigerian Defender Newspaper, oun si ni olootu to kere julọ ni Naijiria nigba naa.

Olufẹ Naijiria ni Oloye Enahoro,titi to fi ku ni 2010 lo ṣi n kede alaafia orilẹede yii.

4) Herbert Macaulay (14 November 1864 - 7 May 1946)

Oloogbe Herbert Macaulay

Oríṣun àwòrán, Getty

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Herbert Macaulay
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Orukọ rẹ gan-an ni Olayinka Herbert Samuel Heelas Badmus.

Olufẹ ati olufọkansin Naijiria ni, oloṣelu ni, onimọẹrọ ni pẹlu, o mọ nipa ile kikọ, bẹẹ ni Herbert Macaulay tun jẹ akọroyin ati akewi.

Ọpọ ọmọ Naijiria a maa ṣapejuwe Herbert Macaulay gẹgẹ bii olori awọn eeyan ti wọn nifẹẹ Naijiria.

Ọkunrin yii gbajumọ nipa bo ṣe maa n tako ijọba Gẹẹsi ti i ṣe amunisin.

Ni ọdun 1919, Herbert Macaulay kọju ija si awọn lọbalọba ni London, nigba ti wọn fi agbara jẹ oko oloko run.

Ija ti Macaulay ja fun awọn ti ọrọ naa kan lo jẹ ko didan fun ijọbba Gẹẹsi lati sanwo nla, owo itanran fun awọn ti wọn jẹ oko wọn run.

Eyi bi igbimọ ijọba Gẹẹsi ninu, to bẹẹ ti wọn ju Macaulay si ẹwọn lẹẹmeji ọtọọtọ .

Okiki Herbert Macaulay tun kan si i nigba to da ẹgbẹ oṣelu akọkọ silẹ lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa ọdun 1923, ni Naijiria, iyẹn Nigerian National Democratic Party (NNDP).

Herbert Macaulay ku lọjọ keje, oṣu Karun-un ọdun 1946, Naijiria si ṣe iranti rẹ nipa yiya a si ara owo ilẹ wa atijọ ti i ṣe Naira kan igba naa, ₦1.

5)Ọlọla Ahmadu Bello, Sardauna Sokoto (June 12, 1910 - January 15, 1966)

Oloogbe Ahmadu Bello

Oríṣun àwòrán, Getty image

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Ahmadu Bello

Ilu kan ti a mọ si Rabbah, nipinlẹ Sokoto, ni wọn ti bi Ọlọla Ahmadu Bello, o si jẹ ọkan lara awọn olori Naijiria ti wọn lokiki lagbaaye.

Ahmadu Bello jẹ oye Sardauna ilu Sokoto, bẹẹ lo jẹ adari ẹgbẹ Northern People's Congress, NPC.

Ahmadu Bello ni wọn ya sinu igba naira owo Naijiria (₦200).

Bakan naa ni wọn sọ yunifasiti lorukọ rẹ, iyẹn Ahmadu Bello Univeristy to wa ni Zaria.

6. Nnamdi Azikiwe (16 November 1904 - 11 May 1996)

Oloogbe Nnamdi Azikiwe

Oríṣun àwòrán, Britannica

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Nnamdi Azikiwe

Oloye Benjamin Nnamdi Azikiwe jẹ ọmọ Naiijiria tootọ to fi ifẹ rẹ han fun orilẹẹde yii.

Oun ni olootu iwe iroyin ‘African Morning Post’ laye ọjọun.

Nnamdi Azikiwe ni ọmọ Naijiria akọkọ to darapọ mọ ẹgbẹ awọn oyinbo, United States Congress.

Nigba ti Naijiria pada di ilẹ olominira, Ọmọwe Azikiwe sa ipa rẹ lati ri i pe orilẹede yii wa ni iṣokan.

Oun naa lo si pada di aarẹ akọkọ ni Naijiria.

7. Tafawa Balewa (December 1912 – 15 January 1966)

Oloogbe Tafawa Balewa

Oríṣun àwòrán, Getty image

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Tafawa Balewa