"Mo kẹ́kọ̀ọ́ jáde, n kò rí iṣẹ́ ni mo ṣe ń darí ọkọ̀ lójú pópó lọ́fẹ̀ẹ́ àmọ́ lọ́jọ́ tí àwọn òbí mi rí mi lójú pópó, inú wọn bàjẹ́ púpọ̀"

Àkọlé fídíò, Lọ́jọ́ tí àwọn òbí mi rí mi níbi tí mo ti ń darí ọkọ̀ lójúu pópó, inú wọn bàjẹ́ púpọ̀
"Mo kẹ́kọ̀ọ́ jáde, n kò rí iṣẹ́ ni mo ṣe ń darí ọkọ̀ lójú pópó lọ́fẹ̀ẹ́ àmọ́ lọ́jọ́ tí àwọn òbí mi rí mi lójú pópó, inú wọn bàjẹ́ púpọ̀"

Yoruba ni ori lo mọ iṣẹ aṣela fun onikaluku ninu irinajo igbesi aye, to si jẹ gbogbo eni to ba wa ni oke agba lonii ni o jẹ pe o bẹrẹ lati ibi kekere.

Isẹ adari ọkọ loju popo jẹ ohun ti Opeyemi Taiwo nifẹẹ si pupọ, to si ṣe iṣẹ yii lai nani owo ṣugbọn nitori ifẹ ọkan rẹ.

Taiwo, nigba to n BBC News Yoruba sọrọ ṣalaye pe lọfẹ ni oun dari ọkọ tẹlẹ ki Gomina ana nipinlẹ Kwara, AbdulFatah Ahmed to gba siṣẹ labẹ ijọba ipinlẹ naa.

O tẹnumọ pe ibanujẹ ọkan lo jẹ fun awọn obi oun nigba ti wọn ri oun nibi ti oun ti dari ọkọ ni loju popo.

"Igba ti mo pari ile ẹkọ ti n ko ri iṣẹ, ni mo bẹrẹ pe ki n kuku ma a dari ọkọ."

"Mo n lọ ni agbegbe Maraba niluu Ilorin, mo ri pe sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ wa n bẹ, mo ni lati bọ silẹ ti mo si bẹrẹ si ni dari ọkọ."

Taiwo ni nnkan ti oun le sọ ni iṣẹ ma n wu oun ṣe pupọ nitori oun ma fi n ran awọn eeyan lọwọ

"Igba ti mo pari ile ẹkọ ti n ko ri iṣẹ, ni mo bẹrẹ pe ki n kuku ma a dari ọkọ."

Aworan Opeyemi Taiwo to n dara ọkọ loju popo

"Lati ọdun 2010, iṣẹ ọfẹ ni mo n ṣe"

Taiwo tẹsiwaju ninu alaye rẹ pe lati ọdun 2010, iṣẹ ọfẹ ni oun ṣe, ti ko si si ẹnikẹni to n sanwo oṣu fun.

O ni awọn eeyan kọọkan ti wọn ba ri lasiko ti wọn n kọja, ti wọn si ri igbiyanju rẹ ni wọn ma n fun ni owo kekere.

"Ijọ ti awọn obi mi ri ti mo ṣe iṣẹ yii, inu wọn bajẹ, agaga iya mi ṣugbọn wọn pada ṣe adura fun mi, ni mo ṣa fi tẹsiwaju lati ma a se e lọ bayẹn."

Bawo lo se pada Gomina Abdulfatah Ahmed?

Taiwo ni lẹyin ọdun mẹrin ti oun ti n ṣe iṣẹ naa ni gomina to wa ni ijoko lasiko naa nipinlẹ Kwara, Abdulfatah Ahmed ri oun nigba to n kọja lọ

Oun ni Gomina fun ara rẹ lo ni ki wọn lọ pe oun wa, ti Gomina si ni oun ti ma ri gbogbo akitiyan rẹ, pe ko si lọ bẹrẹ iṣẹ pẹlu ileeṣẹ ijọba KWATMA.

"Gomina ni ki n lọ bẹrẹ iṣẹ pẹlu ileeṣẹ KWATMA, ti Gomina si tun fun ni owo to jọju, to jẹ pe mi o ti ẹ ti gba ieu owo yẹn gan ri ki n to bẹrẹ iṣẹ."