Àwọn ọ̀daràn kan bẹ akọ̀ròyìn BBC lọ́wẹ̀ láti tọwọ́ bọ ojú òpó wa kò sì gbabẹ̀ di olówó tabua tí kò níí ṣiṣẹ́ mọ́ láyé

Joe Tidy
Àkọlé àwòrán, Akọroyin ori ayelujara fun BBC, Joe Tidy, ti wọn fi iṣẹ naa lọ lati tọwọ bọ oju opo BBC ree.
    • Author, Joe Tidy
    • Role, Cyber correspondent, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 11

Bi iku ile ko pani, tode o le pani. Oṣiṣẹ BBC kan ṣalaye ohun toju rẹ ri lọwọ awọn onijibiti ori ayelujara to bẹ ẹ lọwẹ lati tọwọ (hack) bọ oju opo ileeṣẹ wa ko si gbabẹ di olowo tabua.

Ọpọ nnkan lo maa n ṣẹlẹ lawujọ awọn amookunṣika ti wọn maa n kọwọ bọ oju opo awọn ẹlomi-in lati ṣe wọn ni ijamba, ja wọn lole, ba iṣẹ wọn jẹ,ṣugbọn ṣaṣa eeyan lo ti ni iriri nipa ki wọn lo ẹni to jẹ ara ileeṣẹ kan lati ṣe ijamba fun ileeṣẹ naa.

Eeyan diẹ paapaa ni awọn ti wọn maa n fẹ lati sọrọ nipa rẹ.

Ṣugbọn emi funra mi koju iru ẹ kan to da ọkan mi laaamu laipẹ yii, nigba ti awọn ọdaran ori ayelujara kan fi lọ mi.

"Ti o ba ṣetan lati ba wa ṣe ohun ti a fẹ, a le fun ọ ni ida mẹẹẹdogun ninu owo ti wọn ba san fun wa ti o ba le fun wa ni anfaani lati le ṣi kọmputa rẹ ."

Eyi ni atẹjiṣẹ ti mo gba lojiji lati ọwọ ẹnikan ti wọn n pe ni Syndicate, ẹni to fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si mi loṣu Keje, loju opo Signal.

Mi o mọ ẹni to jẹ, ṣugbọn ẹsẹkẹsẹ ni mo ti mọ ohun to n fẹ.

Owo nla ti awọn ọdaran naa yoo gba lọwọ BBC bi mo ba gba ki wọn gba ibi kọmputa temi wọle si ileeṣẹ naa lara lo n sọ fun mi, ti yoo si fun mi ni ipin temi nibẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wọn yoo ji awọn aṣiri kan, tabi ki wọn fi awọn nnkan to le bani lorukọjẹ si oju opo naa bi wọn ba raye wọle, wọn yoo waa ni ki awọn BBC to gba mi siṣẹ waa san owo nla lati tun wahala naa ṣe, wọn yoo si fun mi ni ipin temi nibẹ.

Koda, lẹyin ọjọ diẹ ti mo gba atẹjiṣẹ naa ni iroyin jade lati Brazil, pe wọn ti mu oṣiṣẹ ori ayelujara kan nibẹ fun pe o ta nọmba to fi n wọle si oju opo ayelujara rẹ fun awọn ọdaran , eyi ti ọlọpaa sọ pe o mu ki owo ti iye rẹ jẹ $100m (£74m) sọnu fun ileefowopamọ to fori ko o.

Mo pinnu lati ṣe bii pe mo maa ṣe ohun ti wọn fẹ lẹyin ti mo ti gba imọran lati ọdọ ọga oniroyin BBC kan. Mo fẹ tete mọ bawọn ọdaran ṣe maa n huwa okunkun wọn yii pẹlu awọn alabọde oṣiṣẹ ileeṣẹ, lasiko yii ti titọwọ bọ oju opo awọn eeyan ti wọpọ lagbaaye lori ayelujara.

Mo sọ fun Syn, to pa orukọ wọn da nigba ti a de aarin kan ninu ọrọ ti a n sọ, pe mo ṣetan lati ṣe ohun ti wọn n fẹ, ṣugbọn mo fẹ mọ bi gbogbo ẹ ṣe maa n lọ gan-an.

Wọn ṣalaye pe bi mo ba fun awọn ni nọmba ti mo fi n wọle soju opo BBC, ati nọmba idaboobo mi, awọn yoo le wọle soju opo BBC (hack), awọn yoo si fi wọ owo nla jade lara ileeṣẹ naa lati ipasẹ ọna idokowo ti a mọ si bitcoin. Wọn yoo si fun mi ni eyi to ba tọ si mi lara owo naa.

Wọn ṣe afikun owo ti wọn fẹ fun mi.

"A o le sọ pato iye ti BBC n san fun ọ, ṣugbọn bawo ni yoo ṣe ri lara rẹ ti a ba fun ọ ni ida mẹẹẹdọgbọn ( 25% ) ninu owo ti a ba gba, ida kan naa la fẹ yọ ninu owo ti BBC n pa wọle. O ko tiẹ nii nilo lati ṣiṣẹ mọ laye rẹ."

Afojusun Syn ni pe ikọ ọdaran oun le beere fun ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu lọwọ BBC nigba ti ileeṣẹ naa ba ko si wọn lọwọ, bawọn ba fi le raye wọle soju opo wọn lori ayelujara.

Ni bayii, BBC ko ti i sọ igbesẹ ti yoo gbe nipa boya ki wọn sanwo fun awọn ọdaran naa to ba ṣe pe wọn ri ero wọn muṣẹ, ṣugbọn imọran ti awọn agbofinro gba wọn ni pe wọn ko gbọdọ sanwo kankan.

Ṣugbọn sibẹ naa, awọn ọdaran to fẹẹ wọ oju opo naa ko yee gbiyanju.

Awọn ọdaran ori ayelujara naa fi atẹjiṣẹ beere lọwọ akoroyin BBC yii, pe njẹ wọn tilẹ n sanwo gidi fun un bayii. Wọn ni awọn le jẹ ko fẹyinti lẹnu iṣẹ BBC, pẹlu obitibiti owo tawọn yoo san fun un to ba ṣe tawọn.
Àkọlé àwòrán, Ọrọ to wa loke yii jẹ eyi ti awọn amookunṣika naa sọ pẹlu akọroyin BBC ti wọn fẹ ko fun awọn ni nọmba aṣiri ti wọn yoo fi wọle soju opo ileeṣẹ BBC.

Syn sọ fun mi pe mo maa maa luwẹẹ ninu owo ni, o lawọn yoo pa gbogbo ọrọ ti a jọ sọ rẹ ti ẹnikẹni ko ni i le ri i mọ laye."

Wọn fi kun un pe awọn ko ṣẹṣẹ maa ṣe aṣeyọri lori iṣẹ awọn yii, owo nla lo si tibẹ jade.

Orukọ awọn ileeṣẹ meji ti wọn raye wọ oju opo wọn lọdun yii, fun apẹẹrẹ ni wọn fi ranṣẹ si mi nigba ti awọn ati ẹni ti wọn bẹ lọwẹ ti jọ fi ẹnu ko - ti wọn ki ọwọ bọ ile iwosan ilẹ UK kan ati ti awọn olupese itọju pajawiri kan ni US.

"Iye awọn oṣiṣẹ to maa fun ọ ni ohun to o fẹ ti a maa pese fun iwọ nikan gan-an maa ya ọ lẹnu."

Syn lo sọ bẹẹ.

Syn sọ pe alaboojuto to ṣee kan si ni oun, fun oju opo jibiti lilu kan ti a mọ si Medusa. O ni oun nikan loun wa lati apa Iwọ -Oorun ninu ẹgbẹ naa, oun nikan si ni oun le sọ ede oyinbo.

Medusa yii jẹ oju opo awọn onijibiti, gbogbo ẹka jibiti to ba wu lati ba wọn ṣe lo si le lọ soju opo naa, ki wọn si jọ gbá ileeṣẹ ti wọn ba fẹ fa lori ti wọn yoo tun fi ọda kun un.

Orukọ ti ẹgbẹ Medusa kọ jọ lati lu ni jibiti.
Àkọlé àwòrán, Ọkan lara oju opo awọn ọdaran ori ayelujara ree ti wọn n pe ni Medusa, wọn ti kọ orukọ ọpọ awọn ti wọn fẹ lu ni jibiti lori afẹfẹ jọ

Níbo ni Medusa ti ń ṣiṣẹ́ tirẹ̀?

Gẹgẹ bi iwadii kan ti ileeṣẹ eleto aabo ori ayelujara kan to n jẹ CheckPoint, ṣe lori Medusa, awọn alaṣẹ rẹ n pitu ọwọ wọn lati ita orilẹede Russia tabi lati ọkan lara awọn orileede to jẹ ọrẹ fun Russia.

"Ikọ naa maa n ri i pe awọn ko fọwọ kan awọn ileeṣẹ to wa ni Russia ati awọn ti Commonwealth ti wọn jẹ orilẹede olominira."

Pẹlu igara ni Syn fi fi ọna lati wo oju opo kan ranṣẹ si mi, eyi to n kilọ fun araalu nipa Medusa, ti wọn fi sita loṣu Kẹta.

Awọn alaṣẹ to n ri si aabo lori ayelujara ni US, ṣalaye pe lati ọdun kẹrin sẹyin ti ikọ onijibiti yii ti bẹrẹ iṣẹ, wọn ti tọwọ bọ oju opo to le ni ọọdunrun (300)".

Syn ṣaa n jẹ ki n mọ pe ikọ alagbara ni mo n ba to, nigba ti mo ni ko jẹ ki n mọ ohun to n sọ gan-an, nitori o le jẹ ọmọde lo n ba mi sọrọ tabi ko jẹ ẹnikan to fẹ dẹ pakutẹ silẹ fun mi.

Nigba naa lo fi oju opo ti maa gba wọle si Medusa ṣọwọ si mi lati apa ibi ti won ti maa n ba ara wọn sọrọ, eyi ti awọn ọdaran fẹran gidi.

Ara Syn ko balẹ ni gbogbo igba ta a n sọrọ, niṣe lo n kan mi loju pe ki n tete fesi si ibeere oun.

Wọn fi oju ọna igbani wọle si Medusa ṣọwọ si mi, wọn rọ mi lati bẹrẹ ohun ti yoo mu mi ri 0.5 owo bitcoin (eyi to $55,000) ti wọn yoo kọkọ san silẹ gẹgẹ bi adehun.

Ohun ti wọn ṣe yii ni wọn fi fidi ẹ mulẹ fun mi pe awọn yoo sanwo yii fun mi lẹẹkan ṣoṣo lọgan ti mo ba gba lati fun wọn ni nọmba iwọle BBC.

"Ki i ṣe ti igberaga, a ko si mu ọ ṣere- awa ki i ṣe oniroyin, ka ṣaa ti pawo wọle ni tiwa, ọkan lara awọn maneja wa lo fẹ ki n ba ọ sọrọ."

O foju han kedere pe wọn yan mi lati ran wọn lọwọ nitori wọn woye pe mo mọ nipa imọ ẹrọ, ti mo si tun ni anfaani to pọ lati wọle si oju opo BBC(Emi o si ni ). Titi di bayii, ko ti i fi gbogbo ara da mi loju pe Syn ti mo mọ jẹ oniroyin ayelujara tabi ọlọpaa ori ayelujara tabi oṣiṣẹ onimọ ẹrọ.

Wọn ni ilana bitcoin kan ni yoo fi gba a ni escrow
Àkọlé àwòrán, Awọn ọdaran naa ṣeleri ninu àyọkà oke yii lati san asansilẹ owo.

Wọn beere ọpọ ọrọ lọwọ mi nipa oju opo imọ ẹrọ BBC, to jẹ bi mo tiẹ mọ wọn gan-an mi o ni i dahun.

Wọn beere ọpọ ọrọ lọwọ mi nipa oju opo imọ ẹrọ BBC, to jẹ bi mo tiẹ mọ wọn gan-an mi o ni i dahun.

Lẹyin naa ni wọn fi ẹda awọn nọmba kọmputa kan to ruju ranṣẹ si mi, wọn ni ki n fi si oju ori ẹrọ kọmputa mi, ki n si ka ohun to ba sọ fawọn, kawọn gbọ. Wọn fẹ mọ bi mo ṣe ni agbara to lati wọle soju opo, ki n si tete bẹrẹ si i wa idahun si ibeere wọn bi mo ba ṣe wọle.

Ni gbogbo igba naa, emi ati Syn ti n sọrọ fun ọjọ mẹta, mo si woye pe mo ti n gbe ọrọ naa kọja ibi to yẹ, ati pe mo nilo imọran lati ọdọ awọn alaabo ori ayelujara ti BBC n lo.

Aarọ ọjọ Sannde kan ni, ero mi ni lati sọ ipinnu mi fun awọn ti a jọ n ṣiṣẹ lọjọ keji.

Fun idi eyi, mo kora ro, ṣugbọn Syn binu.

"Igba wo lo le ṣe eyi? Emi o ni suuru," Bẹẹ ni ọdaran ori ayelujara naa wi.

"Mi o ro pe o wu ọ lati maa gbe letikun alaafia to wa ni Bahamas?"

Oun lo n n da mi laaamu bẹẹ lati tete ṣe ohun to fẹ.

Koda, wọn fun mi ni gbedeke ọjọ ti mo maa fi ṣe e, oru ọjọ Aje ni wọn fun mi da. Lẹyin igba naa ni suuru wọn pin patapata.

Niṣe ni foonu mi ṣaa bẹrẹ si i dun, to n beere nọmba ti mo fi maa n ṣi i. Awọn ohun to n dun naa n wa lati ọdọ awọn alaabo BBC, wọn n sọ fun mi pe ki n fidi ẹ mulẹ pe emi gan-an ni mo fẹ wọle soju opo BBC mi.

Aworan foonu naa to n beere pe ṣe ojulowo oṣiṣẹ lo fẹ wọle soju opo.
Àkọlé àwòrán, Akọsilẹ ibugbamu ti wọn pe ni multifactor bomb

Bi mo ṣe mu foonu mi dani, iṣẹju-iṣẹju lo n tanna pe ki n fi nọmba mi-in si i.

Ohun ti eyi jẹ ye mi, - awọn onijibiti ori ayelujara yii ni wọn maa n lo ilana naa ta a mọ si MFA Bombing.

Wọn yoo ko idaamu ba ẹni ti wọn n ba sọrọ ki iyẹn le ṣe ohun ti wọn n fẹ.

To ba ya, ẹni ti wọn fẹ lu ni jibiti naa yoo tẹ ''mo fara mọ ọn'', (accept). O le jẹ aṣiṣe lo fi tẹ ẹ, o si le jẹ ki ohun ti foonu rẹ n gbe wa naa le parẹ kuro lojuu rẹ lo fi tẹ ẹ, ko le yee fa idaamu.

Eyi jẹ ọna kan to gbajumọ ti awọn eeyan yii n lo.

Awọn ọdaran naa ti gbe ohun ti a jọ n sọ wa si orii foonu mi kia, o si ya mi lẹnu bi wọn ṣe sare yi ọrọ pada, ṣugbọn mo n ṣọra pupọ ki n ma lọ tẹ ''mo fara mọ ọn.''

Bi mo ba ṣe eyi ni, ẹsẹkẹsẹ ni wọn ko ba ni anfaani lati wọ oju opo BBC.

Awọn to wa nidii rẹ ni BBC ko ni i mọ pe emi kọ, wọn yoo ṣe bi emi ni mo n beere nomba ni , wọn yoo ti bọ sọwọ tan ki won too mo pe awọn araabi ni.

Akọroyin ni, mi o ki n ṣe oṣiṣẹ to ni imọ ẹrọ lori ayelujara.

Mo pe ẹka iroyin BBC , ikọ alaabo, a si pinnu lati ge gbogbo ọna ti mo fi n wọ BBC kuro lori ayelujara. Ko ni i si lẹta emails, ko ni i si intanẹẹti, mi o si le lo nnkan to jọ bẹẹ, wọn ja mi kuro patapata ni.

Irọlẹ ọjọ naa ni awọn ọdaran yii fi atẹjiṣẹ ajeji ranṣẹ si mi.

"Ikọ yii tọro aforiji, a n gbiyanju lati yẹ nọmba iwọle si BBC rẹ wo, o si dun wa gan-an bi eyi ba ko inira kankan ba ọ."

Mo ṣalaye fun wọn pe wọn ti le mi danu loju opo BBC, ati pe inu n bi mi.

Syn ṣaa yari pe eto toun ṣe fun mi ṣi wa nibẹ ti mo ba fẹ. Ṣugbọn nigba ti mi o dahun lẹyin ọjọ diẹ, wọn pa oju opo Signal wọn naa de, wọn si poora raurau.

BBC da mi pada soju opo wọn, lẹyin aabo to nipọn ti wọn ṣe fun oju opo ayelujara mi.

Pẹlu iriri mi ti awọn ọdaran fi fẹ lo mi lati doju ija kọ ileeṣẹ mi.Emi funra mi ri ohun to maa n ṣẹlẹ si awọn ileeṣẹ, eyi ti mi o mọ tẹlẹ, to n sọ bawọn ọdaran ṣe n gba oju opo mọ eeyan lọwọ, nigba to kan mi ni mo mọ bo ṣe maa n waye gan-an.