Àlàyé rèé lórí ohun tó mú ọmọ ọdún mẹ́fà borí nínú ìdíje Scrabble

Àkọlé fídíò, Àlàyé rèé lórí ohun tó mú ọmọ ọdún mẹ́fà borí nínú ìdíje Scrabble
Àlàyé rèé lórí ohun tó mú ọmọ ọdún mẹ́fà borí nínú ìdíje Scrabble

Yoruba ni ọmọ ti yoo ba jẹ Àṣàmú, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu ṣamuṣamu.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu ọdọmọde kan, Yusuff Abdulsalam, tii se ọmọ ọdun mẹfa, to bori idije Scrabble jake jado ilẹ wa.

Nigba ti BBC News Yoruba kan si Yusuff ati awọn obi rẹ, a gbọ pe ọmọ ọdun mẹta pere ni ọmọ naa ti bẹrẹ si kopa ninu ere ayo scrambble.

Amọ, ọmọ ti Ẹkun ba bi, Ẹkun ni yoo jọ ni ọrọ Yusuff, tori baba rẹ naa jẹ gbajumọ elere idaraya Scrabble nipinlẹ Kwara.

Yusuff Abdulsalam ọmọ ọdun mẹfa joko lori aga alawọ buluu, o wọ asọ alawọ ofeefe, ọpọn ayo Scrabble kan wa niwaju rẹ lori tabili alawọ buluu bakan naa, to si n n ta ayo naa.
Àkọlé àwòrán, Yusuff Abdulsalam, ọmọ ọdun mẹfa n ta ayo

Yusuff Abdulsalam sọ fun BBC News Yoruba pe ẹru kọkọ ba oun nipa idije naa amọ oun pada bori.

Olukọ rẹ ni awọn to ju Yusuff lọ wa nibi igbaradi fun awọn oludije ti yoo soju ipinlẹ Kwara nibi idije National Youths Game fun awọn ọdọ awọn ọmọ ọdun mẹfa naa lo fakọyọ julọ.

"Tori pe o fakọyọ ninu igbaradi naa lo mu ki wọn mu ko lọ soju ipinlẹ Kwara."

Bakan naa ni iya Yusuff ni ọmọ ọdun mẹta pere ni ọmọ naa ti n kọ nipa ayo Scrabble, to si nifẹ si ayo naa.

"Nigba ti mo gba iwe pe ọmọ mi yoo lọ kopa ninu idije National Youth Game ni Asaba, ẹnu ya mi pupọ."

Bakan naa, ijọba Kwara ni kayeefi lo jẹ pe Yusuff fakọyọ ninu idije naa ni Asaba.

Amọ wọn ni ati kekere ni ijọba ti maa n fa oju awọn ọdọ̀ naa si ere idaraya paapaa lasiko ti wọn ba wa lẹnu isinmi.

Yusuff Abdulsalam to wọ asọ alawọ ofeefe n bọ agbalagba ọkunrin kan lọwọ, ẹni to wọ aọ ankara alawọ eweko ati buluu.Awọn ọdọmọde to to mẹwa niye si lo rọgba yi wọn ka. Gbogbo wọn si lo gbe ami ẹyẹ sọrun gẹgẹ bii akopa ninu idije ere idaraya.