Ìjọba àtàwọn ọlọ́pàá yarí bí agbébọn ṣe pa èèyàn méjìlá lásìkò ìkọlù sí abúlé kan ní Kwara

Awọn Ọdẹ aṣọgbo wọ asọ dudu, wọn to mejila, ti wọn si n rin lọ loju popo pẹlu ibọn lọwọ ẹni kọọkan wn.

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, Awọn Ọdẹ aṣọgbo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Bi iroyin ikọlu awọn agbebọn ṣe n wa lati ipinlẹ Kwara lẹnu ọjọ mẹta yii naa lo tun jẹ jade lọjọ Aiku, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025.

Ilu kan ti a mọ si Oke -Ode, nijọba ibilẹ Ifelodun ni iroyin sọ pe awọn agbebọn kọlu laaarọ ọjọ Aiku naa, ti wọn si pa eeyan mẹwaa ti wọn jẹ fijilante.

Bakan naa ni iroyin kan sọ pe mẹẹdogun ni awọn fijilante to pade iku ojiji naa, awọn kan si farapa yanna-yanna.

O ṣoju mi koro kan ti ko darukọ ara rẹ, ṣalaye pe niṣe ni awọn agbebọn naa ṣina ibọn bolẹ, ti wọn si n pa awọn eeyan lọ.

O ni awọn fijilante to doloogbe naa gbiyanju pupọ lati koju awọn agbebọn ọhun, ṣugbọn ipa wọn ko ka awọn to kọlu wọn naa.

Bakan naa la gbọ pe wọn tun ji eeyan marun-un gbe sa lọ.

Ọkan lara ọmọ ẹgbẹ fijilante naa to pe orukọ rẹ ni Ajetunmobi, ṣalaye ninu ifọrọwanilẹnuwo kan, pe lati alẹ Satide ni awọn ti n gbọ pe awọn agbebọn wa lagbegbe awọn.

O ni awọn ranṣẹ si awọn ikọ yoku lati dira ogun silẹ ko too ṣẹlẹ.

Lara awọn to ni wọn ba iṣẹlẹ naa lọ ni : Oji, Saheed Metubi, Baale Ogba Ayo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Tesan ọlọpaa ni Ajetunmobi sọ pe wọn kọkọ gbe awọn oku naa lọ, wọn si gbe awọn to farapa lọ si ile iwosan ijọba apapọ niluu Saare

Ẹ má jẹ ka doju ija kọ ara wa- Gómìnà Abdulrahman Abdulrazaq

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n kẹdun iṣẹlẹ yii, Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq rọ awọn araalu lati ma ṣe da oju ija kọ ara wọn.

Gẹgẹ bi Gomina Kwara naa ṣe wi ninu atẹjade ti Akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye fi sita lọjọ Aiku naa:

"Mo ba awọn ẹbi ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ si kẹdun lati inu ọkan mi. Ko si alaye ti mo le ṣe to le tu ọkan awọn eeyan to gbọgbẹ naa lara.

"Pẹlu gbogbo bi a ṣe n sapa to, ti a n nawo to lati ro awọn ọlọdẹ to n ṣo igbo wa lagbara, awọn eeyan wa naa si n gbiyanju lori ọrọ yii.

" A mọ riri awọn ikọ alaabo ati igbiyanju wọn, ṣugbọn o di dandan lati fi kun ipa wa.

" Lakootan, mo rọ awọn akikanju araalu Oke-Ode lati ma ṣe ko aarẹ ọkan, ki wọn si ma ṣe kọju ija sira wọn.

"Bẹẹ ni mo ki awọn fijilante ti wọn padanu eeyan marun-un ninu ikọ wọn, ti wọn si tun ṣe awọn alatako naa leṣe, titi laye la o maa dupẹ lọwọ gbogbo wọn gẹgẹ bii akọni wa."

Gomina Abdulrazak pe fun afikun ọmọ ogun ni Kwara lati koju iṣoro aabo naa.

Lori ipe naa si ni olu ileeṣẹ ologun ilẹ wa ṣe paṣẹ, pe ki ọga ologun to wa n'Ibadan, ẹkun keji (2 Division), dari awọn ọmọ ogun rẹ lọ si Kwara lati kun wọn lọwọ.

Ẹ o ranti pe lọsẹ to kọja yii ni awon agbebọn kan naa ya wọ ilu Motokun ni ijọba ibilẹ Patigi, ipinlẹ Kwara.

Wọn pa obinrin alaboyun kan, awọn marun-un mii farapa yana-yana, wọn si tun gbe eeyan mejidinlogun lọ.

Aworan yii ṣafihan ikọ to wọsọ ologun ninu ọkọ, awọn kan jokoo, awọn kan si duro, ọkọ ologun meji miran n lọ niwaju wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn ikọ to wọṣọ ologun, wọn wa ninu ọkọ ogun pẹlu ibọn lọwọ

Ọlọpaa Kwara fidi iku kọlu naa mulẹ, ṣeleri pe awọn yoo mu awọn to wa nidii rẹ

Ninu alaye ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara lori ikọlu yii, wọn fidi rẹ mulẹ pe o ṣẹlẹ ni nnkan bii aago meje aarọ ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025 yii.

Atẹjade ti SP Adetoun Ejire-Adeyemi, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara, fi sita lọjọ naa, ṣalaye pe awọn agbebọn ya wọ agbegbe Ogbayo, l'Oke-Ode, nijọba ibilẹ Ifelodun, ipinlẹ Kwara.

O ni wọn bẹrẹ si i yinbọn lakọlakọ, apapọ ọlọpaa ati awọn ikọ aṣọgbo (National Forest Security Service) si dide lati koju wọn.

Adetoun sọ pe nibẹ ni awọn ti ri oku fijilante mejila, titi to fi mọ ti Baale of Ogbayo.

"Awọn to ku fara gba ọta ibọn, eeyan mẹrin to farapa ni a sare gbe lọ si ileewosan fun itọju, nigba ti a gbe awọn oku kuro.

"Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ati awọn ologun ati awọn NFSS ti fi kun ipa wọn lati mu awọn to wa nidii iṣẹlẹ yii.

"A n wa wọn lọwọ, ileeṣẹ ọlọpaa Kwara si fi da awọn eeyan agbegbe naa loju pe a maa mu awọn to lọwọ ninu ikọlu naa."

O fi kun un pe Kọmiṣanna ọlọpaa Kwara, Adekimi Ojo, ba ẹbi awọn eeyan to padanu ẹmi wọn kẹdun gidi, ati pe ileeṣẹ ọlọpaa Kwara yoo maa tẹsiwaju ninu ipese aabo fun awọn eeyan ibẹ.