'Mi ò ní ₦30 lọ́wọ́ àmọ́ ajínigbé ní kí n mú 30m wáà fi gba ọmọ mi méjì tí wọ́n gbé'

Àkọlé fídíò,
'Mi ò ní ₦30 lọ́wọ́ àmọ́ ajínigbé ní kí n mú 30m wáà fi gba ọmọ mi méjì tí wọ́n gbé'

Laipẹ yii ni iroyin gba ori ayelujara kan, nipa ilu Babanla, to wa ni ijọba ibilẹ Ifelodun, ipinlẹ Kwara, lẹyin ti ilu naa di ahoro nitori ikọlu awọn agbebọn, ti wọn si lọ n fi awọn ilu miran ṣe ibugbe.

Eyi waye latari ikọlu ti awọn agbebọn ṣe si ilu ọhun, ti ẹmi awọn araalu kan si ba isẹlẹ naa lọ.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2025 ni iroyin sọ pe awọn agbebọn to le ni igba (200), ya bo ilu Babanla.

O kere tan, iroyin sọ pe wọn pa eeyan marun-un, to fi mọ ọlọpaa kan, awọn ọmọ ikọ Miyetti Allah meji ati araalu meji.

Iwadii BBC Yoruba fi han pe awọn to kọlu ilu Babanla tun ya bo ọja, wọn si ji oriṣiriṣi ounjẹ lapolapo lọ.

'Wọn ni ki n mu 30m wa a fi gba ọmọ mi mejeeji'

Imaamu Agba ilu Babanla, Alhaji Aweda, joko o to si fi ibanujẹ sọ iriri rẹ lọwọ awọn agbebọn
Àkọlé àwòrán, Ọsẹ diẹ sẹyin ni iroyin ti kọkọ jade pe awọn araalu Babanla ti sa kuro niluu nitori ikọlu awọn agbebọn

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa kan, to tun jẹ Imaamu agba ilu Babanla, Alhaji Aweda, sọ fun BBC News Yoruba pe, ọmọ oun meji ni awọn agbebọn naa gbe lọ, ti wọn si tun n beere fun ọgbọn miliọnu Naira fun itusilẹ wọn.

Ninu alaye to ṣe lori bi iṣẹlẹ ọhun ṣe waye, Alhaji Aweda sọ pe ni nnkan bi aago mọkanla alẹ ọjọ naa ni awọn agbebọn yabo ilu, ti wọn si ji awọn gende ọkunrin naa gbe lọ.

"Yatọ si awọn ọmọ mejeeji, wọn tun gbe iya ọkan ninu wọn.

"Ilu Babanla ni wọn bi mi si, ti mo dagba si, t imo si ti lo gbogbo igbesi aye mi."

Baba naa sọ pe pẹlu omije ni oun fi de ilu Ilorin nibi ti wọn sa lọ.

Arabinrin Aweda to jẹ mọlẹbi baba naa, sọ pe ile onile ni oun lọ ọ sun ni alẹ ọjọ ti iṣẹlẹ ọhun waye nitori ibẹru awọn agbebọn to ti n yọ wọn lẹnu.

Amọ si iyalẹnu rẹ, wọn yabo ile to lọ ọ fi ara pamọ si, ti wọn si tun ji ẹni to gba a lalejo gbe lọ nibẹ.

" Pẹlu ibọn ni wọn gba apo owo ọja mi, wọ̀n ko kaadi ipe t imo n ta, koda, wọn ko awọn nnkan mimu ẹlẹrindodo t imo n ta."

Alhaji Aweda ni iranlọwọ bi oun yoo ṣe ri awọn ọmọ oun gba jade ni oun n fẹ nitori pe oun o ni owo kankan lati doola awọn ọmọ naa.

Awọn eeyan naa fi kun ọrọ wọn pe, ojoojumọ ni ebi n pa awọn nibi ti wọn salọ, nitori pe wọn ko ni ẹbi tabi ara nibẹ.

Ọmọ ìlú kò sá lọ, àwọn àlejò ló n fìlú sílẹ̀ - Kabiyesi Ìlú Babanla

Kabiesi ilu Babanla, Ọba Aliyu Alabi Yusuf

Oríṣun àwòrán, babanla palace

Àkọlé àwòrán, Ọba Yusuf sọ pe o ti pẹ diẹ ti ijinigbe ti bẹrẹ ni agbegbe Babanla, ati pe awọn agbebọn to wa yii pọ niye, wọn si ṣoro lati koju nitori ibọn ti wọn gbe lọwọ.

Lodi si ọrọ awọn ọmọ ilu Babanla ti BBC ba sọrọ, Kabiyesi ilu naa, Ọba Aliyu Alabi Yusuf, sọ pe awọn to n filu naa silẹ ki i ṣe ọmọ bibi ilu Babanla, o ni awọn ajeji lo n sa lọ.

Ninu ọrọ ti Kabiyesi Yusuf ba BBC sọ lori aago lo ti ni oriṣiiriṣii ẹya lo wa ni ilu Babanla.

Ọba ni oun ko le sọ boya agbodegba fun awọn ajinigbe wa ninu wọn tabi ko si, ṣugbọn ohun to da oun loju ni pe ọmọ ilu kan ko le jẹ agbodegba.

Kabiyesi Babanla rọ gbogbo awọn to sa lọ lati pada sile, o ni nitori eto aabo ti wa.

O ni o ṣe diẹ ti ijinigbe ti bẹrẹ ni agbegbe Babanla, ati pe awọn agbebọn to wa yii pọ niye, wọn si ṣoro lati koju nitori ibọn ti wọn gbe lọwọ.

Ọba naa sọ pe gbogbo ile itaja ilu naa ni wọn fẹrẹ wọ tan, ti wọn ko ounjẹ loriṣiiriṣii lọ.

Kabiyesi Aliyu Alabi ṣalaye pe ọjọ naa jẹ ọjọ ọja, o ni gbogbo awọn olọja ti wọn ka owo mọ lọwọ ni wọn gba owo naa lọ lọwọ wọn.

Ọba ilu Babanla rọ ijọba lati fi awọn igbo nla nla to wa ni ilu naa kọ agọ awọn ṣọja, ileesẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.