Sunday Igboho fi ìdọ̀bálẹ̀ tọ̀rọ àforíjìn lọ́wọ́ Ooni, ó rí ìdáríjì gbà

Aworan Ooni Ile Ife ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, ooniadimulaife/Instagram

Àkọlé àwòrán, Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi, Ojaja Keji wọ aṣọ funfun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Yoruba bọ wọn ni ti ọmọde ba n ṣe bi ọmọde, agba a si maa ṣe bi agba, ohun lo difa fun Ooni Ile-Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi, Ojaja Keji to kede wi pe oun ti darijin ajijagbara fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Sunday Adeyemo, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho.

Ooni sọrọ yii lẹyin ti Igboho tọrọ aforijin lori awọn ọrọ kobakungbe to ti sọ sẹyin si Ooniriṣa nigba kan.

Kabiyesi sọ ninu atẹjade kan ti Ọgbẹni Moses Olafare to jẹ adari eto iroyin rẹ fi sita lorukọ Ooni pe, oun forijin Igboho nitori oun fẹ ki iṣọkan ati alaafia wa nilẹ Yoruba.

Lori idọbalẹ ni Igboho wa ni aafin Ooni lọjọ Satide ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹjọ lati tọrọ aforijin lọwọ ori ade naa.

Igboho ni iyalẹnu lo jẹ fun oun nigba ti oun gbọ wi pe Ooni ko ipa ribiribi lati ri pe oun gba ominira lọgba ẹwọn lorilẹede Benin Republic.

''Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun anfaani ti mo ni yii, mi o tiẹ mọ pe kabiyesi yoo gbami tọwọ tẹṣẹ bayii.

Mo ti ṣẹ Ooni, idi niyi ti mo fi wa sibi lati wa tọrọ aforijin, gbogbo ẹyin ti mo ba ti ṣẹ patapata ẹ forijin mi.

Eeyan le bu ọba lẹyin, amọ, ko si ẹni to le bu ọba alaye loju rẹ, kabiyesi, ẹ darijinmi,'' Igboho lo sọ bẹẹ

Igboho ko ṣai lo anfaani abẹwo rẹ si aafin Ooni lati bẹ kabiyesi lati ba a bẹ ijọba ki wọn le yọ orukọ rẹ kuro ninu awọn ọdaran tawọn ẹṣọ eleto abo n wa.

Bakan naa lo tun rọ Ooni wi pe ki ori ade naa ran oun lọwọ lati ri pe apo asunwọn owo rẹ ni banki di ṣiṣi pada.

Igboho ni ''nnkan to wu mi lati ṣe ni pe ki n daabo bo gbogbo ilẹ Yoruba.

Ni ṣe ni wọn n pa awọn eeyan wa, mo fẹ lo agbara ti Eledua fun mi lati kọju ija sawọn to n pa wa.

Amọ, mi nilo atilẹyin yin ki n to le ṣe bẹẹ.''

Akọni ọmọ Yoruba ni Sunday Igboho – Ooni

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọrọ rẹ, Ooni ṣapujewe Igboho gẹgẹ bi olori pipe eeyan ati akọni ọmọ ilẹ Yoruba.

''Kii ṣe fun ara rẹ ni Igboho n ja fun o, gbogbo ilẹ Yoruba lo n ja fun.

Ohun kan ti mo mọ ni pe iwapẹlẹ ati suuru dara ni gbogbo igba.

Ọpọ eeyan lo tabuku mi nigba ti ọrọ naa le, ṣugbọn ni ṣe ni mo n rẹrin-in nitori temi ye mi,'' Ooni ṣalaye.

Ooni fikun ọrọ rẹ pe oun lọ ba aarẹ ana to ti d'oloogbe, Muhammadu Buhari, sọrọ lori ọrọ Igboho.

Ooni sọ pe ''mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o si wa laaye

"Ọmọ mi ni o jẹ mi o le binu si ọ, ogo ilẹ Yoruba tun ni o jẹ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan sọ pe n ko gbọdọ gba ọ ni alejo ni aafin nile Ife, ṣugbọn mo ni rara wi pe gbogbo ilẹ Yoruba ni o n ja fun.

Gbogbo ọrọ to wa nilẹ lo maa ni iyanju, ẹ ṣa jẹ ka wa ni iṣọkan gẹgẹ bi ẹya Yoruba.''

Eyii kii ṣe igba akọkọ ti Igboho yoo tọrọ aforijin lọwọ Ooni latari awọn ọrọ kobakungbe to ti sọ sẹyin nipa kabiyesi Ooniriṣa.

Amọ, igba akọkọ ree ti yoo tọrọ aforijin ti awọn mejeeji yoo foju kan oju.

Loṣu Keji ọdun 2021, Igboho tọrọ aforijin lọwọ Ooni lẹyin to sọ pe ẹru Fulani ni ori ade naa.

Igboho tọrọ aforijin naa lẹyin bii ọjọ kan to ni Ooni ko sọ okodoro ọrọ nipa iya to n jẹ iran Yoruba fun Buhari nigba to ṣepade pẹlu rẹ niluu Abuja.

Ṣugbọn bayii, Igboho gba pe aṣiṣẹ ati aṣisọ ni gbogbo ọrọ toun sọ lati fi tabuku Ooni sẹyin.